Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN bu ẹnu àtẹ́ lu Amẹ́ríkà lórí ìkọlù sí Ààrẹ Venezuela

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akọ̀wé àgbà àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, United Nations, UN, António Guterres ti kọminú lórí ìgbésẹ̀ Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump lórí ìkọlù tó ṣe sí orílẹ̀ èdè Venezuela.
António Guterres nínú àtẹ̀jáde kan tó kà níbi ìpàdé pàjáwìrì tí àjọ náà pè lórí ìkọlù Amẹ́ríkà sí Venezuela sọ pé Trump kò tẹ̀lé òfin tó de àjọ àgbáyé lórí ìkọlù náà.
Ó ní bí Amẹ́ríkà kò ṣe bọ̀wọ̀ fún òfin àgbáyé ní Venezuela jẹ́ ohun tó ń kan òun lóminú.
Ó wòye pé ìgbésẹ̀ náà le da ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè náà rú, tó sì lè ṣokùnfà ìdààmú ní ẹkùn náà.
Bákan náà ló ní ó le fa àyípadà ńlá lórí báwọn orílẹ̀ èdè ṣe ń bára sẹ àti àjọṣepọ̀ tó máa ń wà láàárín àwọn orílẹ̀ èdè méjì.
Níbi ìpàdé náà ni èròńgbà wà pé wọ́n ti máa jíròrò lórí ìdúnkokò tó wà fún àwọn orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé àti ìpèsè ààbò.
Àìsọ̀rọ̀ ìjọba Tinubu lórí bí Amẹrika ṣe mú Ààrẹ Maduro Venezuela àti ìyàwó rẹ̀ mú ìfura dání - Atiku

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/X/Atiku Abubakar/X
Eekan oṣele ADC, Atiku Abubakar, ti koro oju si bi Aarẹ Bola Tinubu ko ṣe tii sọrọ lori bi ijọba Amẹrika ṣe mu Aarẹ Nicolas Maduro orilẹede Venezuela.
Ninu ọrọ ti o fo soju opo Facebook nipasẹ Paul Ibe to jẹ oludamọran rẹ lori eto iroyin, Atiku sọ pe o jẹ iyanlẹnu wi pe ijọba apapọ ko tii sọ nkankan lori nnkan to ṣẹlẹ ni Venezuela, papaa julọ pẹlu ipa ti eleyii ni lori oṣelu orilẹede si orilẹede agbaye
Atiku ni ''ki lo de ti ijọba apapọ Naijiria ko sọ nkankan lori bi Amẹrika ṣe mu Aarẹ Maduro, ti wọn si ju u si ahamọ?..
Igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ ni o ṣee ṣe ki ijọba apapọ mọọmọ dakẹ lori ọrọ naa.
Atiku sọ pe aisọrọ ijọba apapọ Naijiria le jẹ wi pe tori ẹru n ba wọn ni.
Eekan ẹgbẹ oṣelu ADC tun sọ ninu atẹjade to fi sita naa pe o yẹ ki minisita ọrọ ilẹ okeere, Yusuf Tuggar tabi agbẹnusọ aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, ti sọ ero ijọba apapọ lori nnkan to ṣẹlẹ ni Venezuela.
Igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ sọrọ yii lẹyin ti ọpọ eeyan ati oniruuru ẹgbẹ lagbaaye ti n sọrọ lori bi Amẹrika sẹ mu Maduro ti wọn si ju u sahamọ.
Ọpọ lo ti n sọ pe igbesẹ Aarẹ Donald Trump lati mu Aarẹ Maduro tako ofin agbaye.
Ààrẹ Maduro Venezuela tí Amẹrika mú yóò fojú ba ilé ẹjọ́ lónìí
Lonii ọjọ Aje ọjọ karun un oṣu Kinni ni Aarẹ Nicolas Maduro yoo foju ba ile ẹjọ lorilẹede Amẹrika.
Oun ati iyawo rẹ Cilia Flores ti Amẹrika mu ni wọn yoo jọ farahan nile ẹjọ niluu New York lonii.
Minisita eto aabo ni Venezuela, Vladimir Padrino, sọ pe ọpọ ọmogun atawọn araalu lo padanu ẹmi wọn nigba ti Amẹrika yin ado oloro si Venezuela ki wọn to mu Aarẹ Maduro.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ileeṣẹ ologun Venezuela ti kede atilẹyin rẹ fun aarẹ fidihẹ orilẹede naa, Delcy Rodrguez.
Ọpọ alẹnulọrọ lo sọ pe atilẹyin ileeṣẹ ọmogun Venezuela ṣe pataki fun aarẹ fidihẹ naa tori awọn to ba Aarẹ Maduro ṣiṣẹ pọ naa lo si wa ni oniruuru ipo.
Ṣaaju ni Aarẹ Donald Trump ni Amẹrika ni yoo maa ṣejọba Venezuela bayii fun igba kan lẹyin to ti mu Maduro tan.
Ẹwẹ, Aarẹ Trump ti kilọ fun olori orilẹede Venezuela tuntun, Delcy Rodriguez, pe nnkan ti yoo ṣẹlẹ si i yoo buru ju ti Maduro lọ ti o ba kọ lati ṣe nnkan to yẹ.
Trump sọrọ yii tori ifarahan Maduro ati iyawo rẹ ti yoo waye nile ẹjọ lonii ọjọ Aje niluu New York.
Amerika fẹsun kan Maduro pe o n gbe oogun oloro, ati pe o n huwa ọdaran pẹlu nnkan ija oloro.
Ẹsun miran ti wọn fi kan an ni pe o n ṣejọba orilẹede Venezuela gẹgẹ bi awọn agbesunmọmi.
Gbogbo awọn ẹsun ti wọn fi kan Maduro yii lo sọ pe oun o mọ nkankan nipa rẹ.
Rodrihuez to jẹ igbakeji Maduro ti sọ pe o ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu orilẹede Amẹrika lasiko ipade igbimọ alaṣẹ ijọba rẹ, tii ṣe akọkọ iru rẹ lanaa ọjọ Aiku.
Ki nidi ti Amẹrika fi n kọlu Venezuela?
Awọn iroyin kan tilẹ tun sọ pe ọpọlọpọ awọn ilu to yi ilu Caracas ka ni ko ni ina bayii, bẹẹni awọn iroyin ti a ko le fidi rẹ mulẹ pẹlu n sọ pe awọn baluu n fo kaakiri ofurufu ilu naa bayii.
Igbesẹ yii n waye lasiko ti aawọ laarin Amẹrika ati Venezuela n ba ara wọn wọ ṣokoto kan naa, ti Amẹrika si n kọlu awọn ọkọ ojuomi ti wọn n ko ogun oloro ni agbami Caribbean.
Orilẹede Amẹrika n sọ pe makaruru ni ibo to gbe aarẹ orilẹede Venezuela, Nicolas Maduro de ipo, ati wi pe o ṣe agbodegba fun okoowo ogun oloro kaakiri orilẹede naa.
Orilẹede Venezuela n sọ pe, awọn igbesẹ ti Amẹrika n gbe lẹnu ọjọ mẹta yii, titi kan gbigbẹsẹ le awọn ọkọ akepo loju omi lati orilẹede naa, kun ara igbesẹ ti wọn n gbe lati fi ipa yọ Aarẹ Maduro nipo, ki wọn si le maa ṣe akoso ọgbun epo rọbi orilẹede Venezuela.















