Ìjọba Kwara bẹ̀rẹ̀ ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí rédíò fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ nítorí ìkọlù àwọn ajínigbé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara ti darí àwọn ilé ẹ̀kọ́ láti padà sẹ́nu ètò ẹ̀kọ́ bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2026 fún sáà kejì.
Àmọ́ ìjọba ní káwọn ilé ẹ̀kọ́ ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rin tí wọ́n ní abẹ́ àmójútó ètò ààbò ṣì dúró nílé fún ìgbà kan ná.
Ìdarí yìí ló wà nínú àtẹ̀jáde kan tí ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́ àti ìdàgbàsókè ọmọnìyàn ní ìpínlẹ̀ Kwara fi léde lọ́jọ́ Àìkú.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ náà, Peter Amogbonjaye, nínú àtẹ̀jáde náà tó fi léde lórúkọ Kọmíṣánnà ètò ẹ̀kọ́, Lawal Olohungbebe sọ pé ìjọba fẹnukò lórí ìdarí yìí lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àgbéyẹ̀wó ètò ààbò àtàwọn iṣẹ́ tó ń lọ lọ́wọ́ káàkiri ìpínlẹ̀ náà.
Àtẹ̀jáde náà ní kété tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ bá ti padà sẹ́nu iṣẹ́ lọ́jọ́ Ajé ni kí ètò ẹ̀kọ́ bẹ̀rẹ̀ lẹ́yẹ ò sọkà.
Olohungbebe ní dídá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dúró sílé láwọn agbègbè tí ètò ààbò ti nílò àmójútó níbẹ̀ gidi jẹ́ ọ̀nà láti fi dá ààbò bo àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ní agbègbè náà.
"Bí ìwọlé padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń wáyé ní ipele ipele yìí jẹ́ ojúná láti ri pé a kò fi àwọn ọmọ wa sínú ewu pẹ̀lú àkànṣe iṣẹ́ ààbò tó ń lọ lọ́wọ́ láwọn agbègbè náà.
"Ètò ẹ̀kọ́ máa tó padà sípò láwọn agbègbè náà láìpẹ́," Olohungbede sọ.
Iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ náà ní àwọn ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àjọ tó ń tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́ ní ìpele alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ìyẹn SUBEB àti TESCOM láti ri pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kẹ́sẹ járí níbi ètò ẹ̀kọ́ wọn.
Ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí rédíò
Ó fi kun pé láti lè ri dájú pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí kò lọ sílé ẹ̀kọ́ kò máa ṣe àfẹ́kù ohun tó yẹ kí wọ́n kọ́ púpọ̀, ó ní ìjọba ti gbé àwọn ètò kan kalẹ̀ lórí rédíò láti máa fi ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.
Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kìíní ni Kọmiṣánnà náà sọ pé ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí rédíò náà máa bẹ̀rẹ̀ èyí àjọ UNICEF àti Nigeria Learning Passport fọwọ́ sí.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ, orí ìkànnì Midland FM 99.1 ni ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà yóò ti máa wáyé ní aago mọ́kànlá òwúrọ̀ ní gbogbo ọjọ́ Ajé, aago kan ọ̀sán ní gbogbo ọjọ́rú àti aago méjì àbọ̀ ọ̀sán ní gbogbo ọjọ́ Ẹtì títí tí ètò ẹ̀kọ́ fi máa padà sípò láwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà.
Ó fi kun pé wọ́n ṣi máa fi àwọn ilé rédíò kun tó bá yá.
Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara kéde títí àwọn ilé ẹ̀kọ́ pa ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Irepodun, Ifelodun, Isin àti Ekiti nítorí ìkọlù àwọn ajínigbé tó ń wáyé lemọ́lemọ́ láwọn agbègbè náà.
Ìjọba Kwara gbé àwọn ilé ẹ̀kọ́ tì pa níjọba ìbílẹ̀ márùn-ún lẹyìn ijínigbé àti ìpànìyàn tó wáyé ní ìjọ CAC ìlú Eruku
Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Kwara ti gbe gbogbo awọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama to wa ni ijọba ibilẹ marun-un ti pa lẹkun gusu ipinlẹ naa tori bi ọrọ eto abo se ri bayii nibẹ.
Awọn ijọba ibilẹ tọrọ naa kan ni, ìjọba ibilẹ Ekiti, Isin, Oke ẹrọ, Ifẹlodun ati Irẹpọdun ti gbogbo wọn wa ni lẹkun Gusu ipinlẹ Kwara.
Titi pa awọn ile ẹkọ naa ko sẹyin bọrọ eto abo ṣe n buru si i lẹkun naa.
Alaga ẹgbẹ awọn olukọ ipinlẹ Kwara (NUT), Kọmureedi Yusuf Agboọla, sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe ijọba ti awọn ile ẹkọ naa pa latari ipenija ọrọ eto abo.
O salaye pe ki awọn olukọ kiyesi atẹjade yii, ati pe bi nnkan ba se ri awọn yóò pada fi to wọn leti.
Ninu ọrọ rẹ, alakoso awọn olukọ nijọba ibilẹ Isin, Oloye Lere Balogun, naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.
Kọmisọna feto ẹkọ ni ipinlẹ Kwara, Dr Lawal Ọlọrungbẹbẹ naa sọ pe ijoba ipinlẹ gbe igbesẹ yii lati daabobo awọn akẹkọọ ni.
O fi kun un pe ijọba fẹ ki aabo to peye wa fun awọn akẹẹkọ to fi mọ awọn akẹẹkọ to n gbe lọgba ile ẹkọ.
Gbogbo ile ẹkọ ijọba ati aladani lọrọ naa kan bayii lawọn ijọba ibilẹ marun-un ọhun.
Ni irọlẹ ana ni ibẹrubojo gbalẹ pe, awọn ajinigbe fẹ kọlu ile ẹkọ Anglican Girls College Iludun Oro, ṣugbọn ti ijọba tete ko awọn ẹṣọ alabo sọwọ si ile ẹkọ naa.
Titi awọn ile ẹkọ pa yii waye lẹyin wakati merinlelogun tawọn agbebọn kọlu ile ìjọsìn CAC niluu Eruku nijọba ibilẹ Ekiti nibi ti wọn pawọn olujọsin, ti wọn si ji awọn ọmọ ijọ marundinlogoji gbe lọ.
Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazak naa sabẹwo si ilu Eruku l'Ọjọru lati bawọn kẹdun, to si bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ikọlu naa.















