Àwọn agbébọn yawọ ọjà, ṣekúpa èèyàn 30, jí ọ̀pọ̀ gbé lọ

Àwọn igi gbígbẹ tó jóná kù nínú ọjà ìlú

Oríṣun àwòrán, ZAKARI Kontagora

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Kò dín ní ọgbọ̀n èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn báwọn agbébọn ṣe yawọ ọjà kan ní ìlú Kasuwan-Daji, ìpínlẹ̀ Niger lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹta, oṣù Kìíní, ọdún 2026.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Niger sọ pé láti inú igbó ọba kan tó wà ní agbègbè náà làwọn agbébọn ọ̀hún ti tú jáde, tí wọ́n sì dáná sí apá ibìkan nínú ọjà náà.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Niger, Wasiu Abiodun fi léde lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kìíní fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé èèyàn tó lé ní ọgbọ̀n ni wọ́n ṣekúpa níbi ìkọlù náà.

Bákan náà ló sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn, táwọn kò ì tíì le fìdí iye wọn múlẹ̀ ni àwọn agbébọn náà tún jí gbé.

Abiodun fi kun pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti ṣe àrídájú rẹ̀ pé wọ́n rí àwọn tí wọ́n jí gbé náà gbà kalẹ̀ àti pé àwọn yóò máa fi bí gbogbo nǹkan bá ṣe ń lọ tó aráàlú létí.

Abdullahi Rofia, òṣìṣẹ́ àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Niger, Niger State Emergency Management Agency sọ fún BBC pé níṣe ni àwọn agbébọn náà so àwọn èèyàn lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀, tí wọ́n sì fi ọ̀bẹ ṣe ìkọlù sí wọn.

Rofia sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú ni kò lè jáde síta mọ́ báyìí látàrí ìbẹ̀rù tó gba ọkàn wọn, tí wọn kò sì le bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀.

"Wọ́n ń bẹ̀rù pé, tí àwọn bá bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀, wọ́n máa padà wá ṣe ìkọlù sí àwọn náà."

Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ti wà ní agbègbè náà láti ṣe ìtọ́jú àwọn tó farapa níbi ìkọlù náà àtàwọn tó ní ipa lé lórí.

Ìkọlù yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ St Mary's School, Papiri tó lé ní 250 ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní àkàtà àwọn agbébọn tó ji wọ́n gbé nínú oṣù Kọkànlá, ọdún 2026.

Ìlú Kasuwan-Daji súnmọ́ ìlú Papiri tí ìjínigbé náà ti wáyé. Àwọn aláṣẹ sọ pé gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé náà ló ti gba ìtúsílẹ̀.

Fún ọ̀pọ̀ ọdún bátyìí láwọn agbébọn ti ń ṣe ìkọlù káàkiri Nàìjíríà pàápàá lẹ́kùn àríwá Nàìjíríà.

Láìpẹ́ yìí ni ìjọba àpapọ̀ kéde àwọn agbébọn náà bí ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí.

"Wọ́n lé wa jáde kúrò nínú àwọn ilé wa, pa wá bíi adìyẹ"

Ọ̀kadà tí wọ́n jó níná wà nílẹ̀ pẹ̀lú

Oríṣun àwòrán, ZAKARI Kontagora

Ọ̀kan lára àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn sọ fún BBC pé nǹkan bíi aago márùn-ún sí mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ ni àwọn agbébọn náà yawọ ìlú náà tí wọ́n sì ṣekúpa ọ̀pọ̀ èèyàn.

Ó ní àwọn ti máa ń gbọ́ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù báyìí ni àwọn agbègbè míì ṣùgbọ́n tí àwọn kò mọ̀ pé ó máa padà kan àwọn náà lọ́jọ́ kan.

"A ò ní àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò kankan níbí. À ń késí ìjọba láti tètè ràn wá lọ́wọ́ nítorí a ò mọ ipò táwọn èèyàn wat í wọ́n jí gbé wà.

"Wọ́n lé wa jáde kúrò nínú àwọn ilé wa, níṣe ni wọ́n ń pa wá bíi adìyẹ. Ṣé ìjọba kò nání ẹ̀mí wa?

"Ìjọba ń rí, wọ́n sì ń gbọ́ nípa gbogbo àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ àmọ́ wọn ò ṣe nǹkankan si."

Ẹlòmíràn tó tún bá BBC sọ̀rọ̀ sọ pé láti ìlú Kari ni òun ti gbọ́ nípa ìkọlù náà, tí òun sì gbọ́ pé níṣe ni wọ́n ń dú àwọn èèyàn bíi adìyẹ àti ewúrẹ́.

Ó ní inú igbó ni àwọn ti ń ṣa òkú àwọn èèyàn tí wọ́n pa àti pé òkú méjìlélógójì ni àwọn ti ṣà báyìí.