Olóṣèlú pín èédú àti ẹ̀rọ ìlọṣọ fáwọn ará ìlú rẹ̀ ni Zamfara láti fi rọgun sí wọn lápa

Oríṣun àwòrán, @others
Ọpọ iwe iroyin Naijiria lo gbe iroyin naa nibi ti kanselọ to n ṣoju wọọdu Mayana ni Gusau nipinlẹ Zamfara ti n pin eedu ati ẹro ilọṣọ fawọn eeyan wọọdu rẹ lati maa fi siṣẹ.
Abubakat Muhammadu Tahiri lo n pin ẹro ilọṣọ atọwọda naa lati fi rọgun sawọn eeyan rẹ lapa ki wọn le maa ṣiṣẹ lati ri owo na.
Iwe Iroyin Nasarawa Daily News lo kọkọ gbe e pe Tahiri n pin ohun ti awọn kan pe ni irinṣẹ yii ki ọwọ awọn to fun ma ba a dilẹ nitori pe ọwọ to ba dilẹ kii ṣe nkan rere lasiko.
O ni pe eyi jẹ ọkan lara awon ileri lati rọgun si awọn eeyan rẹ lapa.
Ṣé eyi jẹ tuntun laarirn awọn oloṣelu ni?
Irọgun sini lapa kii ṣe ohun tuntun laarin awọn oloṣelu kaakiri agbaye paapaa ni Naijiria ṣugbọn ọpọ lo ti n sọrọ lori awọn nakn ti awọn oloṣelu miran maa n lo lati fi pese iṣẹ fawọn eeyan wọọdu tabi agbegbe wọn.
Losu karun un, ọdun 2024 ni Senatọ Rufai Hanga to n ṣoju Aarin gbungbun Kano pin ẹgbẹrun marun un aṣọ funfun ati ọpọlọpọ ikoko amọ fawọn ara ilu rẹ to n ṣoju fun.
Bẹẹ naa ni Alex Mascot Ikwe to n ṣoju Aba North nipinlẹ Abia naa pin aramọnda nkan losu kẹta ọdun 2024.
O pin nkan idana fun awọn obinrin lati fi rọgun si wọn lapa.
Loṣu keji ọdun 2022 ni kanselo Sadada nipinlẹ Sokoto nijoba ibile Kebbi naa pin ẹni mejimeji fawọn eeyan ẹkun rẹ.
Lọdun 2020 ni Onorebu Abdullahi Mamadu to n ṣoju Rijau / Magama nipinlẹ Niger naa pin Wheel barrow ọmọlanke fawọn ọdọ ẹkun to n ṣoju fun nigba naa.
Ni Ilesa nipinlẹ Osun, lodun 2021 naa ni wọn sọ pe alaga Ila oorun Ilesa nigba naa pin ẹro iranṣọ ati erọ ti wọn fi n gbẹ irun fawon obinrin agbegbe naa.


























