Makinde gbé Adé àti Ọ̀pá Àṣẹ fún Ọba mẹ́ta tó wà lójú òpó Olubadan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ọba náà ò yọjú

Oríṣun àwòrán, Senator Sharafedeen Alli/X/Seyi Makinde/X
Gomina Ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ti Igbakeji Gomina Ipinlẹ Oyo, Amofin Abdul Raheem Adebayo Lawal, to ṣoju rẹ ti kede ifinijoye Ọba Akeem Mobolaji Adewoyin gẹgẹ bii Ẹkerin Balogun ti ilẹ Ibadan, Ọba Oyekola Babalola gẹgẹ bi Ẹkaarun-un Olubadan ti ilẹ Ibadan ati Ọba Sharafadeen Abiodun Alli gẹgẹ bi Ẹkaarun-un Balogun ti ilẹ Ibadan ni gbọngan Mapo niluu Ibadan.
Awọn oloye giga mẹtẹẹta naa ni ko yọju sibi eto ọhun, ti ẹ o ba gbagbe, Olubadan ti ilẹ Ibadan ninu atejade ti agbenusọ rẹ fi lede ti ṣalaye tẹlẹ wi pe awọn eeyan naa ti sọ fun oun pe awọn ko tii ri aye lasiko yii lati wa gba ade oju opo oye Olubadan.
Ọsẹ to kọja yii ni iroyin sọ pe wọn ṣẹṣẹ fi iwe to n kede ayẹyẹ igbega sipo ọba naa ranṣẹ si Olubadan Ladoja.
Gẹgẹ bi a sẹ gbọ, eyi naa si pẹlu ara idi ti awọn oloye giga naa ko ṣe fi gbogbo ara gba lati yọju sibi eto ọhun.
''Alakalẹ ofin ipinlẹ Oyo lori oye jijẹ ni a tẹle''
Igbakeji Gomina Ipinlẹ Oyo, Abdul-Raheem Adebayo Lawal, ṣalaye wi pe igbesẹ gbigba ọpa aṣẹ ati Ade Ọba wa ni ibamu pẹlu ofin ati ilana oye jijẹ nipinlẹ Oyo.
Lawal ni "eto ti a n se loni yii ṣe pataki ki akude ma ba ilana oye jijẹ nilu Ibadan.
Ọpọ eeyan le maa sọ pe a fi ọwọ oṣelu bọ ọ, amọ, ko ri bẹẹ rara , ofin Ipinlẹ Oyo la tele eyi to fun Gomina Ipinlẹ Oyo laṣẹ lati fi Ọba jẹ niluu Ibadan.
Ilana oye jijẹ ilu Ibadan ṣe pataki fun imugbooro alafia.
Ijọba Ipinlẹ Oyo yoo tun sise pọ pẹlu gbogbo awọn ori ade nipinlẹ Oyo ki idagbasoke le baa Ipinlẹ Oyo sii.''
Igbakeji Gomina ipinlẹ Oyo wa rọ awọn ori ade tuntun naa lati ni ẹmi ifọkansin, ki wọn si mojuto idagbasoke alaafia agbegbe wọn.
''Olubadan ko gbọdọ faye gba oloṣelu ninu igbimọ lọbalọba ilu Ibadan''
Asoju Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Tajudeen Ajibola, ni oun dupe lọwọ Gomina Ipinlẹ Oyo nitori gbogbo nnkan ti awọn awọn oloye ilu Ibadan n fẹ ni o n ṣe fun wọn.
Ọba Ajibola ṣalaye pe ipo ti awọn oloye ilu Ibadan wa tẹlẹ papaa julọ nigba ijọba oloogbe Obafemi Awolowo, awọn Gomina Ipinlẹ Oyo seyin yato si Gomina Abiola Ajimobi to mu atunto baa oye jijẹ nilẹ Ibadan.
Ọba Ajibola ni "Ọba Odugade lo sọ wi pe ẹniti o ba fẹ ṣe oṣelu ko fi ipo Ọba le, eniti o ba si fẹ ṣe oṣelu ko fi Ọba lẹ oun naa ni Ajimobi tẹle,Ọba wa to wa nibe nissininyi nigba yẹn ohun ati Odugade ko gba fun ara wọn.
Awon Ọba to de lẹyin igba yẹn mọ gba wọn ni moran ki wọn maa gba oṣelu laye laarin awọn lọbalọba ki wọn ma ba ilu jẹ.
Ọba ti gba gbogbo ilu, ki ba ṣe ẹgbẹ oṣelu APC, PDP,ADC, eniti wọn yan ko kan, ki Gomina to sọrọ ohun lo yẹ ko sọrọ, tabi ẹgbẹ miran.
Kabiyesi ko gbọdọ faye gba oṣelu laarin awọn oloye rẹ, isẹ Ọba ni lati ran Gomina lọwọ.''
Awọn Ọba bi Eleruwa ti ilu Eruwa, Ọba Samuel Adegbola, Okere ti ilu Saki, Oba Khalid Oyeniyi, Aseyin ti ilu Iseyin, Sefiu Olawale Oyebola ati awọn Oba miran nipinlẹ Oyo lọ peju sibi eto naa.
Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ọwọ́ òṣèlú wà nínú báwọn olóyè mẹ́ta tó yẹ kó gba adé Ojú Òpó Olubadan ṣe ní àwọn ‘Busy’, àmọ́ tí Makinde ní ayẹyẹ ìgbadé ń tẹ̀síwájú lónìí?

Oríṣun àwòrán, Gov.Seyi Makinde/Facebook/BBC/Sen. Sarafadeen Alli/ Facebook
Oni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹta oṣu Kẹrin ọdun 2026 ni Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, kede pe oun yoo gbe ade ọba ati ọpa aṣẹ fun awọn oloye giga ilu Ibadan mẹta, koda bawọn eeyan naa ko tilẹ yọju sibi ayẹyẹ naa rara.
Kọmiṣanna fun eto iroyin nipinlẹ Oyo, Dotun Oyelade, lo fidi eyi mulẹ ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọbọ.
Awọn ti Makinde fẹ fi jọba naa ni:
Sharafadeen Alli ti i ṣe sẹnetọ to n ṣoju Guusu ipinlẹ Oyo, ẹni ti wọn gbega si ipo Ẹẹkaarun Balogun.
Ẹnikeji ni Baolaji Adewoyin ti wọn sọ di Ẹẹkẹrin Olubadan, ati Kola Babalola ti wọn gbega sipo Ẹkaarun Olubadan.
Lẹyin igbega yii ni awọn oloye naa yoo di ọba ni agbegbe ti koowa wọn ti wa, ti wọn yoo si bọ sinu igbimọ agba oye oludamọran si olubadan.
Ṣugbọn iroyin sọ pe awọn ti Makinde fẹ gbega naa ko gbaradi, ko si irọkẹkẹ pe wọn tilẹ fẹ da si ọrọ agbega to sun wọn siwaju ninu ipo ọba naa.
Koda, a gbọ pe awọn ti wọn fẹ gbega sipo ọba naa ni awọn ko ni I yọju sibi ayẹyẹ naa rara.
Bẹẹ ni iroyin sọ pe Olubadan Rasidi Ladoja gan-an ko ni si nibi ayẹyẹ naa.
Wọn ni nitori ọba ti gbera wa siluu Eko ṣaaju ayẹyẹ to fẹ waye ni Gbọngan Mapo, niluu Ibadan, laaago mẹwaa owurọ oni.
Se lootọ ni ayẹyẹ igbade toni lọwọ oselu ninu?
Ọba mejila, Baalẹ ogoji ni Gomina Seyi Makinde ti fi jẹ lati 2019 to ti n ba a bọ, eyi ti Kọmiṣanna eto iroyin rẹ sọ pe ko ṣẹlẹ ri ninu itan oye jijẹ ipinlẹ Oyo.
Ṣugbọn eyi to fẹ waye loni ọjọ Ẹti yii ni ọpọ eeyan n sọ pe o lọwọ oṣelu ninu.
Eyi ri bẹẹ nitori Senetọ Sharafadeen Alli ti a gbọ pe o ṣee se ki wọn fa kalẹ bii oludije sipo gomina ipinlẹ Oyo ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni 2027.
Ṣadeede ni ijọba Seyi Makinde bẹrẹ si i kede pe Senetọ Alli yoo gba ade ti yoo sun siwaju de ipo Olubadan.
Ikede naa si n lọ pẹlu idaniloju pe ijọba ko ni I kede rẹ to ba jẹ pe ayẹye ọhun ko ni I waye.
Bẹẹ ni ijọba Oyo kede pe ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin ọdun 2026 ni ayẹyẹ igbega sipo ọba naa yoo waye niluu Ibadan.
Ibeere ti ọpọ eeyan bẹrẹ si I beere lẹyin eyi ni pe ṣe yoo ṣee ṣe fun Senetọ Alli lati tẹsiwaju ninu igbiyanju lati di gomina, nigba to ba ti gba ade oju opo sipo Olubadan, ti yoo si sun siwaju sipo Ọba?
Bẹẹ lọpọ eeyan n sọ pe Gomina Makinde mọ ọn mọ fẹ yi Senetọ naa lagbo da sina, ko ma baa le dupo gomina Oyo ni.
Ọba Ladoja atawọn oloye giga naa ko ni i yọju sibi ayẹyẹ igbade wọn
Awọn oloye giga mẹtẹẹta naa lo ti foju han pe wọn ko ni yọju sibi eto to kan wọn gbọngbọn yii, lati gba ade oju opo naa, ki wọn si de ipo ọba.
Iroyin kan ni Olubadan ilẹ Ibadan; Ọba Rasidi Ladoja, ti sọ l'Ọjọbọ pe loootọ loun lọ siluu Eko, ṣugbọn oun ti pada silẹ n'Ibadan.
"Mo kan lọ siluu Eko pẹlu ọmọ mi obinrin ni, irinajo to kan mi ni mo lọ l'Eko. Mo ti wa nile mi."
Nipa awọn tijọba fẹ gbega sipo ọba, Kabiyesi Ladoja ṣalaye pe awọn eeyan naa ti sọ fun oun pe awọn ko tii ri aye lasiko yii lati wa gba ade oju opo naa tori ọwọ awọn di.
"Awọn mẹta ti ijọba fẹ de lade sọ pe aaye ko si fawọn lati se ayẹyẹ naa lasiko yii.
"Ẹni akọkọ sọ pe oun wa ni Canada lati gba itọju, ikeji wa lẹnu iṣẹ ilu, ta a ni wọn wa fẹ fi jọba.?"
Ọsẹ to kọja yii ni iroyin sọ pe wọn ṣẹṣẹ fi iwe to n kede ayẹyẹ agbega sipo ọba naa ranṣẹ si Olubadan Ladoja, eyi to ko kere jọjọ.
Eyi naa si pẹlu ara idi ti awọn oloye giga naa ko ṣe fi gbogbo ara gba lati yọju sibi eto naa bi a sẹ gbọ.
'Ko si ija laaarin Makinde ati Olubadan'
Bi ọrọ yii ṣe n tan kalẹ, paapaa nigba ti iroyin jade pe Olubadan ti lọ siluu Eko ni ọpọ eeyan ti n sọ pe aarin ọba naa ti Gomina Makinde ko gún mọ.
Lati yanna-na eyi, Akọwe iroyin fun Ọba Ladoja, Adeola Oloko, fi atẹjade sita l'Ọjọbọ lati fidi ẹ mulẹ pe ko si ija kankan laaarin Gomina Makinde ati Olubadan.
"A fẹ ko ye wa daju pe ko si ija kankan laaarin Kabiyesi ati Olori Omo Oba ilu Ibadan.
"Lafikun, Olubadan ko lọ siluu Eko lati le ma yọju sibi ayẹyẹ ti yoo waye lonii ọjọ Ẹti.
"A fẹ ko ye wa daju pe alaafia ni Kabiyesi wa n'Ibadan, to n ṣiṣẹ ọba bii ipo Olubadan to wa."
Akọwe iroyin Olubadan naa tẹsiwaju pe awọn oloye giga to fẹ gbade naa ti sọ fun Olubadan pe awọn ko ni I wa, wọn si ti ni ki wọn sun ayẹyẹ naa siwaju.
"A ti fi eyi to ijọba ipinlẹ Oyo leti lati ọdọ ileeṣẹ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ."
Bẹẹ ni atẹjade to ti Aafin Olubadan wa naa wi.
BBC News Yoruba yoo wa nibi eto naa ni Mapo, a o maa mu bo ba ṣe lọ wa fun yin.

























