Àwọn ọmogun Naijiria ṣekúpa àwọn jàndùkú agbébọn méjì l'Ondo

Oku awọn agbebọn ti awọn ọmogun ṣekupa ni ipinlẹ Ondo.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni ti oloun, bẹẹ lọrọ ri bi awọn ikọ ọmọ ogun orilẹede Naijiria ṣe sekupa awọn agbebọn meji nipinlẹ Ondo.

Awọn ikọ ọmogun 32 Artillery Brigade ti wọn ko lọ si agbegbe Auga nipinlẹ Ondo lo ṣe isẹ naa lasiko ti wọn wa loju isẹ ni opopona Akunu si Auga ni ọjọ kẹrinla oṣu yii.

Aseyori yii ti mu ki awọn olugbe agbegbe naa fo fayọ nitori agbegbe naa jẹ ọkan lara ibi ti awọn ajinigbe atawọn janduku agbebọn ti n sọsẹ nipinlẹ Ondo.

Igbakeji Alukoro ẹka ọmogun 32 Artillery Brigade nipinlẹ Ondo, Irabor Njoka, lo fidi ọrọ naa mulẹ.

Ọgagun Njoka salaye pe awọn olugbe agbegbe naa lo sin awọn ikọ naa ni igbere ipakọ ti wọn fi ṣe aṣeyọri naa.

O salaye pe ni kete ti wọn ri awọn agbebọn naa, wọn kọ oju ibọn sira wọn, sugbọn awọn ikọ naa fi ọwọ ajulọ han wọn ti wọn si yinbọn pa meji ninu awọn agbebọn ọhun.

Irabor sọ pe awọn to ku ninu awọn agbebọn naa salọ ọgbẹ ọta ibọn lara wọn.

Ọgagun Njoka ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe pe awọn ọmọ ogun Naijiria ṣe aseyọri naa pẹlu ajọsepọ ẹṣọ Amọtẹkun ati awọn fijilante.

Awọn ohun ti wọn ri gba lọwọ wọn lẹyin iṣẹlẹ naa ni; ibọn AK-47 kan, pẹlu ọpọlọpọ ọta ibọn, ẹrọ ilewọ meji, ọbẹ, oogun oloro ati ₦39,000.

Irabor salaye pe aseyọri yii waye latari isẹ takuntakun ti ileeṣẹ ologun n se nipinlẹ Ondo.

O seleri pe wọn ileeṣẹ ologun yoo ri daju pe ko si kọlọrọsi ẹda kankan ti yoo farapamọ nipinlẹ Ondo mọ.

Ọgagun Njoka wa rọ awọn ara ilu lati tubọ maa sin awọn ileeṣẹ ologun nigbẹrẹ ipakọ loorekoore nitori wọn nilo ifọwọsowọpọ wọn lati le fopin si isẹ awọn eniyan ibi ni ipinlẹ Ondo.