Ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Abuja: Mo máa ṣiṣẹ́ tako olùdíje tí kò bá ṣe tí Ààrẹ Bola Tinubu - Wike

Aworan Nysome Wike ati Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Minisita fun olu ilu orilẹede Naijiria, Nyesom Wike ti ni oun ṣetan lati ṣe atilẹyin fun oludije to ba jẹ pe ti Aarẹ Bola Tinubu ni o n ṣe lai bikita ẹgbẹ oṣelu saaju eto idibo ijọba ibilẹ to n bọ niluu Abuja ni ọjọ Kejileogun oṣu keji.

Wike sọ ọrọ yii niluu Abuja lasiko ọjọbi Sẹbetọ Sandy Onor, ẹni to pe ọgọta ọdun laye.

O tesiwaju pe oun ko ni tọrọ aforijin kankan nitori oun ṣe atilẹyin fun Aare Tinubu, to si ṣe ileri pe oun naa ṣetan lati ṣe atilẹyin fun oludije kankan to ba n ṣe ti Aarẹ Bola Tinubu.

"A ni eto idibo ibilẹ FCT to n bọ lọjọ Kejilelogun, ti mo si ṣetan se atileyin fun oludije to ba n ṣe ti Aare Tinubu lati bori.

"Ojuse mi lati ri pe oludije ti ko ba se ti Aarẹ Tinubu ko bori eto idibo, n ko si ni tọrọ aforijin kankan," Wike sọ.

Ki n ṣe igba akọkọ ree ti Wike yoo kede atilẹyin re fun Aarẹ Bola Tinubu, ti o si je ko di mimọ pe oun ko fi igba kankan ba abamọ pe oun ṣe atilẹyin fun Tinubu.

Lọdun to kọja ni ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party fi iwe ẹri, eyi to fọwọ osi juwe ile fun Minisita fun olu ilu Naijiria, Nyesome Wike, Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri, Ayodele Fayose ati awọn yooku ti wọn yọ kuro ninu ẹgbẹ lasiko ipade apero ẹgbẹ naa to waye niluu Ibadan nipinlẹ Oyo.

Gẹgẹ bii o ṣe wa ninu atẹjade kan ti PDP fi lede loju opo ayelujara X wọn, iwe ẹri naa ni wọn fi sita lọjọ keji oṣu kọkanla ọdun 2025 niluu Abuja, nibi ti adele alaga ẹgbẹ naa, Umar Damagum ti gbe agbara fun alaga tuntun, Sẹnetọ Kabiru Turaki.

Lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kọkanla lasiko ipade apero, fọwọ osi juwe ile fun Wike ati awọn yooku lori ẹsun pe wọn n ditẹ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Bakan naa ni Ile ẹjọ giga to n jokoo niluu Ibadan wọgile ipade apero ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party to waye niluu Ibadan, to si fọwọ si igun ti Wike.