Agbésùnmọ̀mí kọlu ìlú mẹ́ta ní Niger, ṣekúpa èèyàn 30, dáná sun ilé àti àgọ́ ọlọ́pàá

Alupupu ti wọn danan sun lasiko ikọlu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn agbebọn ti wọn gun alupupu ti ṣekupa ọpọ eeyan lasiko ti wọn kọlu ilu mẹta ni apa Ariwa Naijiria.

A gbọ pe oniruru ohun ija oloro lawọn agbebọn naa ko lọwọ, bi wọn ṣe yinbọn pa awọn kan naa ni wọn fi ọbẹ rẹ ọrun awọn mii ti wọn si sọ ina si ọpọlọpọ ile ninu ikọlu ọhun.

Yatọ si awọn ti wọn ṣekupa, awọn agbesunmọmi naa tun ji ọpọ awọn mii ti a ko tii mọ iye wọn gbe lọ nipinlẹ Niger.

Ileeṣẹ iroyin AFP jabọ pe agbegbe ti ikọlu naa ti waye ko jina si ibi ti ikọlu kan ti waye ni ibẹrẹ oṣu yii, nibi ti wọn ti pa eeyan to le ni ọgọrun un.

Ikọlu lemọlemọ awọn agbesunmọmi ti di tọrọfọnkalẹ ni Naijiria amọ ikọlu naa ti n sunmọ iha iwọ oorun ati aringbungbun Naijiria lẹnu lọlọ yii.

Afẹmọju ni wọn kọlu Tunga-Makeri ti wọn si ṣọṣẹ nibẹ.

Wasiu Abiodun, to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger sọ pe eeyan mẹfa ni wọn pa ni Tunga-Makeri.

O ni "wọn sọ ina si awọn ile kan, bẹẹ ni wọn tun ji awọn eeyan ti a ko tii mọ iye wọn gbe lọ."

Awọn ti ikọlu naa ṣoju wọn sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe o fẹ jọ bii pe gbogbo ile to wa nibẹ ni wọn dana sun, wọn tun ji obinrin mẹrin gbe lọ.

Lẹyin ti wọn kọlu Konkoso, awọn agbesunmọmi naa tun tẹkọ leti lọ si Pissa, wọn dana sun agọ ọlọpaa, wọn tun ṣekupa ẹnikan.

Ileeṣẹ iroyin Reuters jabọ pe apapọ awọn ti wọn ṣekupa jẹ mejilelọgbọn, nigba ti ileeṣẹ iroyin AFP ni tirẹ ni eeyan mẹrindinlaadọta o kere tan ni wọn pa.

A ko tii le sọ nipa awọn ibomii ti wọn ṣakọlu si amọ iroyin ni ọpọ eeyan ni wọn gbẹmi wọn.

Iroyin kan ti AFP gbe jade sọ pe ori alupupu mọkanlelogoji ni awọn agbebsunmọ naa wa ti wọn ti n ṣọṣẹ, ti alupupu kọọkan si ko eeyan meji si mẹta.

Awọn ẹgbẹ to n woye bi ikọlu naa ṣe n lọ sọ pe pupọ ninu awọn ti ẹmi wọn n sọnu si awọn ikọlu naa ni wọn jẹ Musulumi.