Atiku, Bashir Ahmad korò ojú sí oṣù Kejì ọdún 2027 tí INEC kéde fún ìbò ààrẹ torí Ramadan, INEC ṣàlàyé ìdí abájọ

Atiku Abubakar wọ agbada buluu pẹlu fila, Ọjọgbọn Joash Amupitan ati Bashir Ahmad naa wọ agbada pẹlu fila lori

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/X/INEC/Bashir Ahmad/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, ti ṣalaye wi pe oun kede ogunjọ oṣu Keji ọdun 2027 gẹgẹ bi ọjọ ti ibo aarẹ yoo waye nitori alakalẹ to wa ninu iwe ofin orilẹede Naijiria lori eto idibo.

INEC ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita eyi ti ọkan lara awọn ọga agba ajọ naa, Muhammed Kudu Haruna, buwọlu wi pe asiko to wa ninu iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999 ni awọn fi ṣe agbekalẹ ọjọ idibo ọhun.

Bakan naa tun ni Ọgbẹni Haruna fikun ọrọ rẹ pe ajọ INEC tun lo ofin eto idibo Naijiria ọdun 2022 fun ikede ogunjọ oṣu Keji ọdun 2027 gẹgẹ bi ọjọ ti ibo aarẹ yoo waye.

''Alakalẹ to wa ninu iwe ofin Naijiria sọ pe eto idibo aarẹ ati igbakeji aarẹ ati tawọn ọmọ ile aṣofin agba l'Abuja gbọdọ waye ni Satide kẹta oṣu Keji ọdun ibo.

Eto idibo awọn gomina pẹlu igbakeji wọn ati ti ile igbimọ aṣofin awọn ipinlẹ naa gbọdọ waye lẹyin ọsẹ meji ti ibo aarẹ ati tawọn ile aṣofin agba ba ti waye.

Ogunjọ oṣu Keji ọdun 2027 ti INEC kede fun eto idibo aarẹ ati ti ile aṣofin agba l'Abuja ati ọjọ kẹfa oṣu Kẹta fun eto idibo gomina ati ti ile aṣofin ipinlẹ wa ni ibamu pẹlu awọn alakalẹ yii.

Amọ, INEC ti ṣe akiyesi oun to n kọ awọn eeyan kan lominu wi pe ọjọ ati oṣu idibo ti ajọ naa kede jẹ asiko kan naa pẹlu oṣu awẹ Ramadan awọn musulumi.

Ajọ eleto idibo Naijiria ti bẹrẹ si ni maa bawọn tọrọ kan sọrọ lori akiyesi awọn eeyan lori ọjọ idibo ti INEC kede,'' ajọ INEC lo ṣalaye bẹẹ.

INEC ni awọn ti n wa ọna ti ile aṣofin agba fi le ṣeranwọ lati ṣatunṣe lori akiyesi awọn eeyan kan lori ọjọ eto idibo ti ajọ naa kede, lọna ti ko fi ni tapa si iwe ofin Naijiria.

Ajọ naa ni oun ko ni beṣu bẹgba lati ṣagbatẹru eto idibo ti yoo lọ ni irọwọ rọsẹ lai figba kan bọkan ninu.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Atiku, Bashir Ahmad kegbare lori ọjọ idibo ti INEC kede tori oṣu Ramadan ni

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni oludamọran aarẹ Muhammadu Buhari tẹlẹ, Bashir Ahmad, ti rọ ajọ INEC pe ko tun ero rẹ pa lori ogunjọ oṣu Keji ọdun 2027 ti o kede gẹgẹ bi ọjọ ti eto idibo aarẹ Naijiria yoo waye tori o jẹ asiko kan naa ti awọn musulumi yoo maa gbaawẹ lọwọ.

Ahmad ni ọpọ musulumi to ba n gba awẹ le ma ni okun lati lọ dibo tori wọn maa wa ninu awẹ nigba naa.

Ninu ọrọ to fi lede loju opo X rẹ, Ahmad sọ pe ko le rọrun fun ọpọ musulumi lati kopa daadaa ninu eto idibon naa ti ajọ INEC ba tẹsiwaju lati ri pe eto idibo naa waye loṣu Keji ọdun to n bọ gẹgẹ bi o ti kede.

Oludamọran aarẹ tẹlẹ ri sọ pe adinku maa n ba awọn nnkan ti ọpọ awọn musulumi maa n ṣe lasiko awẹ ki wọn le fi ara wọn jin fun iṣẹ isin lasiko awẹ Ramadan.

O ni eyi le ma jẹ ki ọpọ musulumi kopa ninu eto idibo eyi to tako erongba INEC pe ki gbogbo eeyan to ba ti to ibo di jade dibo

Ninu ọrọ tiẹ, igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Atiku Abubakar, naa rọ ajọ INEC wi pe ki o ṣatunṣe lori ọjọ eto idibo to kede ni kia kia.

Atiku sọ ninu ọrọ to fi lede loju opo X rẹ pe awẹ Ramadan yoo bẹrẹ lati ọjọ keje oṣu Keji ọdun 2027, yoo si pari lọjọ kẹjọ oṣu Kẹta.

Eyi tumọ si pe laarin awẹ Ramadan lawọn musulumi yoo wa ni ogunjọ ti INEC kede pe eto idibo aarẹ yoo waye.

Atiku ni ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ Naijiria to jẹ musulumi ni wọn yoo fi ara wọn jin ni asiko naa fun iṣẹ isin.

Atiku ni kikede ọjọ idibo ni aarin oṣu Ramadan fi han pe awọn to ṣe ikede naa ko ṣe agbeyẹwo igbesẹ wọn daadaa ki wọn to kede rẹ sita.

Eekan ẹgbẹ oṣelu ADC naa ni bawo ni INEC ṣe fẹ ṣeto idibo ti yoo lọ ni irọwọ rọsẹ lai ṣegbe lẹyin ẹnikan, ti ajọ naa ko ba le ṣeto to mọyan lori nipa asiko ti eto idibo ọdun 2027 yoo waye.