INEC kéde ọjọ́ ìbò ààrẹ 2027 àtàwọn mí-ín

Alaga INEC, Ọjọgbọn Joash Amupitan

Oríṣun àwòrán, Professor Joash Amupitan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ ẹleto idibo ilẹ Naijiria; Independent National Electoral Commission, (INEC) ti gbe alakalẹ nipa bi eto idibo apapọ ọdun 2027 yoo ṣe lọ jade.

Alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Joash Amupitan lo fi alakalẹ eto idibo naa lede lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtala, oṣu Keji ọdun 2026, nibi ipade oniroyin kan l'Abuja.

Ṣaaju ni INEC ti ni oun ti pari iṣẹ lori awọn ọjọ ti idibo yoo waye, bo tilẹ jẹ pe awọn idiwọ diẹ wa.

"Mo fi n da awon ọmọ Naijiria loju pe bi a ṣe fẹ bẹrẹ eto pataki fun orilẹede wa yii, ajọ INEC ti ṣetan lati ṣeto idibo ti yoo fi ifẹ ọkan awọn eeyan han."

Ọjọgbọn Amupitan lo sọ bẹẹ.

Amupitan ṣalaye pe idibo yii yoo kan ọfiisi aarẹ, Igbakeji rẹ, awọn gomina ati igbakeji wọn, afi awọn ipinlẹ bii Anambra, Bayelsa, Edo, Ekiti, Imo, Kogi, Ondo ati Osun nikan ni ko kan.

Yoo kan awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin, ile igbimọ aṣoju ati awọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ.

Eyi ni awọn ọjọ ti idibo yoo waye ni 2027 bi INEC ṣe kede

  • Ogunjọ oṣu Keji, 2027: Ibo aarẹ ati ti ile igbimọ aṣofin agba yoo waye.
  • Ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta 2027: Ibo si ipo awọn gomina ipinlẹ ati tawọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ yoo waye kaakiri Naijiria.

Ikede yii lo jade laarin awuyewuye to n waye nile igbimọ aṣofin, nipa atunṣe ofin idibo lorilẹede yii.

Ajọ INEC sọ pe oun ti fi alakalẹ eto idibo naa ranṣẹ sawọn aṣofin tẹlẹ.

Wọn ni amọ awọn sọ fun wọn pe o ṣee ṣe ki awọn apa kan eto naa faragba abajade ijokoo igbimọ, nigba ti wọn ba pada gbe ofin ti wọn ṣe atunṣe rẹ jade.

Alaga INEC naa rọ awọn ileeṣẹ ijọba, awọn eleto aabo, awọn oniroyin,ẹgbẹ awujọ, awọn oludije atawọn oludibo lati ri i daju pe eto idibo to ni alaafia waye.

O ni ajọṣe gbogbo eeyan ni Naijiria ni idibo ọdun 2027.

O ni ajọṣe gbogbo eeyan ni Naijiria ni idibo ọdun 2027.