Ìdí rèé tí a kò fi ní tẹ́wọ́ gba èsì ìdìbò tí INEC bá kéde - SCSN

Igbimọ agba to n risi ofin Sharia lorilẹede Naijiria, Supreme Council for Shari'ah in Nigeria (SCSN) ti pe fun iyọ kuro alaga fun ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC, iyun, Joash Amupitan ṣaaju eto idibo gbogbo ti ọdun 2027, ti wọn si ṣapejuwe gẹgẹ bii eeyan to le ṣakoba fun eti ijọba awarawa lorilẹede Naijiria.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, abẹnugan ile, Sheikh Bashir Aliyu Umar, ṣalaye iha to kọ si alaga ajọ eleto idibo, to si tun kilọ pe awọn musulumi lorilẹede Naijiria ko ni tẹwọgba esi idibo kankan labẹ iṣakoso Amupitan.
Sheikh Umar ni awọn n gbe igbesẹ yii nitori awọn iwa alaga naa tẹlẹ, paapa bi o ṣe kọ lẹta sita pe otitọ ni pe awọn Kristẹni n padanu ẹmi wọn lorilẹede Naijira, ọrọ to jẹ pe ijọba Naijiria gan sọ pe irọ to jina si otitọ ni.
"A si duro le ohun ti a n sọ ati alaga INEC ko ti jade lati sọ pe a n parọ mọ oun, o duro le ohun to gbagbọ, ko ri eyi gẹgẹ bii pe oun nilo lai jade wa sọrọ nipa rẹ," Sheikh Umar ṣalaye.
Gẹgẹ bii o ṣe ṣakaye, Sheikh Umar ni iha ti alaga INEC kọ si ọrọ ẹṣin le ṣe akoba fun ajọ eleto idibo.
"A gbagbọ pe ẹnikẹni to ba ma di irufẹ ipo yii mu gbọdọ jẹ eeyan ti ijọba ti ṣe iwadii rẹ pe ko ni fi si ibi kan ju ibi kan lọ.
"Ohun to tọna fun bayii ni pe ko kọwe fipo rẹ silẹ, ti ko ba ṣe bẹ, ki ijọba rọ loye nitori eto idibo to ba waye labẹ iṣejọba rẹ jẹ ohun ti awọn araalu ko ni igbagbọ ninu."
Ni oṣu Kẹwaa ọdun 2025, Igbimọ alaṣẹ orilẹede Naijiria, the National Council of State, ti buwọlu iyansipo Ọjọgbọn Joash Ojo Amupitan (SAN) gẹgẹ bii alaga ajọ eleto idibo INEC tuntun.
Aarẹ Bola Tinubu lo mu orukọ Ojọgbọn Amupitan lọ siwaju igbimọ alaṣẹ orilẹede Naijiria fun ibuwọlu, eyi ti gbogbo wọn si fẹnu ko le lori ti wọn si buwọlu u.
Tinubu sọ fun igbimọ naa wi pe Ọjọgbọn Amupitan ni ẹni akọkọ lati ẹkun aarin gbungbun Naijiria ti ijọba yoo yan sipo alaga INEC, ati pe ki i ṣe oloṣelu rara.
Ta ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Joash Amupitan?

Ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́ta (58) ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Joash Amupitan, tó sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Aiyetoro-Gbede, ìjọba ìbílẹ̀ Ijumu ní ìpínlẹ̀ Kogi.
Ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin, ọdún 1967 ni wọ́n bí i.
Onímọ̀ nípa òfin ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Amupitan.
Ọdún 2014 ló di agbẹjọ́rò àgbà, ìyẹn Senior Advocate of Nigeria, SAN.
Lẹ́yìn tó parí ilé ẹ̀kọ́ girama ló tẹ̀síwájú lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ìpínlẹ̀ Kwara ìyẹn Kwara State Polytechnic, Ilorin láàárín ọdún 1982 sí 1984 àti ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Jos láàárín ọdún 1984 sí 1987.
Ọdún 1988 ló di agbẹjọ́rò, tó sì gba oyè ọ̀mọ̀wé lọ́dún 2007.
Ṣáájú ìyànsípò rẹ̀, Amupitan ni igbákejì gíwá àgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Jos tó ń rí sí àkóso ilé ẹ̀kọ́ náà.
Ó ní ìyàwó pẹ̀lú ọmọ mẹ́rin.
Bákan náà ló tún jẹ́ alága alákòso ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ayo Babalola University tó wà ní ìpínlẹ̀ Osun.
Yàtọ̀ sí ètò ẹ̀kọ́, Amupitan ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìgbìmọ̀ àwọn lájọlájọ tó fi mọ́ Integrated Dairies Limited, Nigerian Institute of Advanced Legal Studies Governing Council, Council of Legal Education, Riss Oil Limited, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Alága tuntun fún INEC náà tún jẹ́ òǹkọ̀wé tó sì ti kọ ọ̀pọ̀ ìwé lórí òfin bíi Models and Principles (2008); Documentary Evidence in Nigeria (2008); Evidence Law: Theory and Practice in Nigeria (2013), Principles of Company Law (2013) àti Introduction to the Law of Trust in Nigeria (2014).
Iṣẹ́ àkọ́kọ́ tó máa ṣe gẹ́gẹ́ alága INEC ni láti ṣètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra tó máa wáyé lọ́jọ́ Kẹjọ, oṣù Kọkànlá, ọdún 2025.



























