"A kò le ṣe káre sí Amupitan lórí ìbò Anambra, ìbò gómìnà ní Osun àti Ekiti ló máa sọ bó ṣe dáńtọ́ sí"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí ni ètò ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra wáyé níbi tí gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Chukwuma Charles Soludo ti rí ìyànsípò fún sáà kejì.
Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC, Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 kéde pé Soludo, ti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Grand Alliance, APGA, lo gbégbá orókè ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ mọ́kànlélógún tó wà ní ìpínlẹ̀ náà.
Edoba Omoregie, tó kéde èsì ìbò ọ̀hún sọ pé Soludo ní ìbò 422,664 nígbà tí Nicholas Ukachukwu ti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC tó gbé ipò kejì ní ìbò 99,445.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n ti ń sọ èrò wọn lórí ètò ìdìbò náà, bí àwọn kan ṣe ń kan sáárá sí àjọ INEC lórí etò ìdìbò Anambra, naa ni àwọn míì ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìbò rírà àtàwọn ìwà kò tọ́ míì tó wáyé lásìkò ètò ìdìbò ọ̀hún.
Àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú bu ẹnu àtẹ́ lu ètò ìdìbò
Ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Party, ADC nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú náà, Bolaji Abdullahi fi síta sọ pé níṣe ni ètò ìdìbò náà kún fún títà àti ríra ìbò.
Ó ní níṣe ni àwọn olóṣèlú kan sọ ibùdó ìdìbò náà di ilé ọjà tí wọ́n ti ń ta àti ra ìbò.
Abdullahi ní ìgbésẹ̀ jẹ́ ohun ìkọnilóminú lórí ìlànà ètò ìdìbò Nàìjíríà àti pé ìgbésẹ̀ náà jẹ́ ohun àbùkù sí ètò ìṣèjọba àwaarawa.
Ó fẹ̀sùn kàn pé gómìnà tó wà lórí ipò àti ẹgbẹ́ òṣèlú kò fi ìbò rírà wọn bò rárá, tí wọ́n sì ń fi owó ra ìbò lọ́wọ́ àwọn èèyàn èyí tí wọ́n ní ó lòdì sí òfin ètò ìdìbò.
Bákan náà ni olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Goerge Moghalu náà bu ẹnu àtẹ́ lu bí ètò ìdìbò náà ṣe wáyé, bó ṣe ní àwọn kùdìẹ̀kudiẹ pọ̀ níbi ètò ìdìbò ọ̀hún.
Moghalu sọ pé láti ìgbà tí òun ti díje dupò gómìnà, àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tó wáyé níbi ètò ìdìbò yìí ló pọ̀ jùlọ.
"Níṣe ni wọ́n ń fi ààyè gba àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò tó láti dìbò láàyè láti dìbò. Àwọn nǹkan yìí ló jẹ́ kí a máa bèèrè bí ètò ìdìbò náà ṣe kẹ́sẹ járí sí.
Awọn awuyewuye to n waye naa lo mu ki BBC News Yoruba ba onimọ nipa eto iselu kan sọrọ lati se agbeyẹwo ibo gomina to kọja ni ipinlẹ Anambra.
Bakan naa, onimọ naa jẹ ka mọ awọn agbọn ti INEC ti fọmọyọ ati ibi ti wọn ku si.
Àwọn agbọn ti INEC ti fakọyọ nínú ìbò Anambra rèé - Onímọ̀ nípa òṣèlú
Ẹ̀wẹ̀, onímọ̀ nípa ètò òṣèlú kan tó tún jẹ́ agbẹjọ́rò, Festus Adedayo wòye pé, ètò ìdìbò ìpínlẹ̀ Anambra ní àwọn àmúyẹ àtàwọn ohun tí a lè pè ní àléébù rẹ̀.
Ó ní ohun àkọ́kọ́ tó jẹ́ àmúyẹ ètò ìdìbò náà ni pé ó jẹ́ ohun ìwúrí láti rí àlékún sí iye àwọn tó jáde láti dìbò.
Adedayo ní iye àwọn èèyàn tó kópa níbi ètò ìdìbò yìí lé kún jọjọ sí iye àwọn tó máa ń kópa níbi ètò ìdìbò gómìnà èyí tí kó bá ti wáyé lásìkò ètò ìdìbò gbogbogbò.
Bákan náà ló wòye pé àdínkù bá àwọn ìwà jàgídíjàgan tó sábà máa ń wáyé lásìkò ètò ìdìbò.
Ó ṣe ìràntí pé láwọn ètò ìdìbò tó ti wáyé ní ìpínlẹ̀ náà sẹ́yìn, àawọn èèyàn agbègbè bíi Ihiala kìí sábà ríbi dìbò nítorí ìkọlù àwọn ẹgbẹ́ alájàngbilà ESN àti IPOB ṣùgbọ́n tí ètò ìdìbò wáyé láwọn agbègbè náà níbi ètò ìdìbò yìí.
Ó sọ pé àmúyẹ míì ni pé INEC ri dájú pé wọ́n fi ìdá mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún èsì ìbò náà sórí ayélujára pẹ̀lú ẹ̀rọ BVAS, èyí tó ń ṣàfihàn pé ìgbéga ti ń bá ètò ìdìbò Nàìjíríà.
Adedayo ní òun ní ìrètí pé èyí máa jẹ́ àmúlò nígbà tí ètò ìdìbò gbogbogbò máa wáyé lọ́dún 2027.
Níbi ètò ìdìbò gbogbogbò tó kọjá, INEC ṣèlérí láti lo ẹ̀rọ BVAS ṣùgbọ́n tí èyí kò wá sí ìmúṣẹ bí wọ́n ṣe ní ojú òpó ayélujára náà kò dára.
"Ètò ìdìbò ìpínlẹ̀ Osun àti ti Ekiti ló máa jẹ́ ìdánwò gangan fún àjọ INEC"
Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, Adedayo ní ìgbésẹ̀ rírà àti títa ìbò jẹ́ ohun tó ṣì ń fa ètò ìdìbò Nàìjíríà sẹ́yìn.
Ó wòye pé ọ̀pọ̀ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ni wọ́n gbé ẹ̀rọ POS lọ sí ibùdó ìdìbò láti fi ra ìbò lọ́wọ́ àwọn olùdìbò èyí tó ní ó tàbùkù ètò ìdìbò Nàìjíríà.
Adedayo sọ pé a kò lè fi ètò ìdìbò Anambra yìí ṣe ìgbéléwọ̀n alága àjọ INEC tuntun, Joash Amupitan nítorí Mahmood Yakubu tó gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ náà máa ń ṣe àṣeyọrí bẹ́ẹ̀ lásìkò tí kìí ṣe ètò ìdìbò gbogbogbò.
Ó ní èyí tó máa jẹ́ ìdánwò fún-un gangan ni ètò ìdìbò ìpínlẹ̀ Osun àti ti Ekiti.
Ó wá pè fún àtúntò òfin ètò ìdìbò èyí tó máa fìdí múlẹ̀ tí ètò ìdìbò Nàìjíríà bá máa gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀ bíi ti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ní àgbáyé.















