Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Chukwuma Soludo tó di gómìnà Anambra lẹ́ẹ̀kejì

Oríṣun àwòrán, Governor Chukwuma Charles Soludo
Chukwuma Charles Soludo ti kuro ni ẹni ti a ṣẹṣẹ n juwe lagbo oṣelu Naijiria lasiko yii, bo tilẹ jẹ pe oṣelu kọ lo fi bẹrẹ irinajo idanimọ rẹ, to jẹ onimọ nipa ọrọ aje ni.
Idi ni pe Chukwuma Soludo ti wọn tun kede rẹ pe o jawe olubori ninu idibo sipo gomina Anambra bayii naa lo wa lori aleefa naa tẹlẹ.
Ni bayii ti ajọ INEC si ti kede rẹ bii gomina adiboyan kẹfa nipinlẹ naa, orukọ Chukwuma Soludo tun ti gbilẹ si i bo ṣe fi ẹyin awọn ẹgbẹ oṣelu bii APC, PDP, Labour ati bẹẹ bẹẹ lọ janlẹ.
Ọmọ ẹgbẹ oṣelu APGA ni Soludo n ṣe.
Oun nikan naa si ni ẹgbẹ APGA fa kalẹ bii oludije lasiko idibo abẹle ẹgbẹ naa.
Ta a ni Gómìnà Chukwuma Charles Soludo?

Oríṣun àwòrán, Governor Chukwuma Charles Soludo
Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keje ọdun 1960 ni wọn bi Chukwuma Charles Soludo, ni Isuofia, nijọba ibilẹ Aguata, ipinlẹ Anambra.
Ọmọwe to gba oye ipele akọkọ (first-class) ninu imọ nipa ọrọ aje ni University of Nigeria, Nsukka ni.
Yunifasiti yii kan naa lo ti gba ami ẹyẹ Ọmọwe, oun lo si gba ami ẹyẹ akẹkọọ to peregede julọ.
Ọjọgbọn ninu imọ nipa ọrọ aje ni Charles Soludo.
Ko too wọnu oṣelu, Chukwuma Soludo jẹ onimọ nipa ọrọ aje ati oṣiṣẹ banki, o si di gomina banki agba ilẹ wa (CBN) pẹlu.
Bakan naa lo ti di ipo Alaga igbimọ Banki apapọ ilẹ wa mu ri.
Charles Soludo ti figba kan ri jẹ oludamọran pataki fun aarẹ Olusegun Obasanjo lasiko iṣejọba rẹ ni 2003, bẹẹ naa lo tun jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ oludamọran fun aarẹ Muhammadu Buhari.
Ọjọgbọn ninu imọ nipa ọrọ aje ni Soludo ni awọn yunifasiti bii University of Nigeria Nsukka, University of Cambridge, Brookings Institution, University of Warwick ati University of Oxford.
Ọjọgbọn alabẹwo tun ni ni Swarthmore College (USA).
Gomina Charles Soludo ni iyawo, Nonye Soludo ni iyawo rẹ n jẹ, wọn si bi ọmọ mẹfa.
Ìrìnàjò Chukwuma Soludo sí ipò gómìnà Anambra fún ìgbà àkọ́kọ́ àti ìkejì

Ni ọdun 2009, Chukwuma Soludo kede pe oun fẹ di gomina ipinlẹ Anambra labẹ asia ẹgbẹ PDP.
Ṣugbọn ero rẹ igba naa ko wa si imuṣẹ, o si gba a to ọdun mejila ko too bọ si i fun un.
Ni 2010 to dije lo padanu sọwọ Peter Obi ti i ṣe gomina Anambra nigba naa.
Ni 2013 ni Soludo kuro ninu PDP, o si darapọ mọ All Progressives Grand Alliance, APGA, ṣugbọn igbimọ alayẹwo APGA ko tun gba a wọle lọdun naa, ko si le dije.
Nigba to di 2021 ni kadara ṣe e lore, Charles Soludo wọle ibo bii gomina Anambra labẹ APGA to n ba bọ, latigba naa lo si ti wa ninu ẹgbẹ ọhun.
Oṣu Kẹta ọdun 2022 ni saa akọkọ Charles Soludo bẹrẹ bii gomina ipinlẹ Anambra, nigba naa lo gba ipo ọhun lọwọ Willie Obiano to wa nibẹ tẹlẹ.
Ni bayii, Charles Soludo ni yoo maa tẹsiwaju bii gomina Anambra fun ọdun mẹrin miran, lẹyin to ti fi ẹyin oludije mẹẹẹdogun janlẹ ninu idibo ọjọ kẹjọ, oṣu Kọkanla ọdun 2025 yii.
Oun nikan naa si ni gomina to yege labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Grand Alliance, APGA.














