Ṣé lóòótọ́ ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lu olùkọ́ pa ní ìlú Ogbomoso?

Ọ̀gbẹ́ni Adegoke Fatai nígbà tó wà lórí ibùsùn ní ilé ìwòsàn tí wọ́n fi aṣọ wé ní apá

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ní ọjọ́ méjì sẹ́yìn ni ìròyìn kan gba orí ayélujára pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan ní ilé ẹ̀kọ́ Soun High School tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Ogbomoso North, Ogbomoso, ìpínlẹ̀ lu ọ̀kan lára olùkọ́ wọn, Fatai Adegoke títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lára rẹ̀.

Àtẹ̀jáde kan tí ẹgbẹ́ olùkọ́, Nigeria Union of Teachers, NUT ẹ̀ka ìlú Ogbomoso fi sórí ayélujára sọ pé pẹ̀lú ọgbẹ́ ọkàn ni àwọn fi ń kẹ́dùn ikú ọ̀gbẹ́ni Adegoke tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn táwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan lù ú bí ejò àìjẹ.

"Pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn ni a fi kẹ́dùn ikú ọ̀gbẹ́ni Adegoke Fatai tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ lù ú nígbà tó ń báwọn wí láti yé ta tẹ́tẹ́ lásìkò ìkẹ́kọ̀ọ́."

Àtẹ̀jáde náà ni wọ́n fi ń képe àwọn àjọ tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́ àti gbogbo èèyàn lápapọ̀ láti dìde sí ọ̀rọ̀ náà, kí wọ́n sì ri dájú pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà fojú winá òfin.

Èyí ti ń fa onírúurú awuyewuye lórí ayélujára èèyàn sì ti ń pè fún ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an?

Ẹ̀wẹ̀, iléeṣẹ́ ìròyìn Ogbomoso Insight nínú ìròyìn kan tí wọ́n fi léde lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kọkànlá sọ pé àwọn bá olùkọ́ àgbà ilé ẹ̀kọ́ Soun High School, Adeyinka Ajayi láti fìdí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an múlẹ̀.

Ajayi ṣàlàyé pé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ni òun di olùkọ́ àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà tó sì jẹ́ pé láti ìgbà tí òun sì ti di ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ náà ni ọ̀gbẹ́ni Adegoke ti máa ń lọ sí ilé ìwòsàn ní ẹ̀ẹmèjì lọ́sẹ̀ láti lọ ṣàyẹ̀wò ara rẹ̀.

Ó ní wọ́n sọ fún òun pé Adegoke fi ìgbà kan rí ní ìjàmbá ọkọ̀ tó lágbára èyí tó jẹ́ pé gbogbo èèyàn tó wà nínú ọkọ̀ náà ló pàdánù ẹ̀mí wọn àyàfi òun nìkan.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Wọ́n ní láti ìgbà náà ló ti ní egbó lápá àti ẹsẹ̀ èyí tí mo rò pé kò jiná tán."

Lórí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé láìpẹ́ yìí, Ajayi sọ pé Adegoke ń rìn káàkiri ilé ẹ̀kọ́ lọ́jọ́ kan tó sì rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan níbi tí wọ́n ti ń ta káàdì nínú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọn kò lò mọ́.

"Bó ṣe rí wọn, ó pariwo mọ́ wọn, tó sì ní kí gbogbo wọn jáde wá bá òun.

"Adegoke kìí ṣe olùkọ́ tó sábà máa ń na akẹ́kọ̀ọ́ ṣùgbọ́n ó dàbí nǹkan tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe dùn-ún púpọ̀, tó sì gbìyànjú láti nà wọ́n.

"Níbi tó ti ń nà wọ́n ni ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gbé ọwọ́ sókè láti da dúró àmọ́ ó dàbí pé ibi ọwọ́ tó ń dùn-ún tẹ́lẹ̀ ni akẹ́kọ̀ọ́ náà kàn."

Ajayi kò pẹ́ rárá ni ọwọ́ Adegoke bẹ̀rẹ̀ sí ní wú, tó sì gba ilé ìwòsàn lọ lẹ́sẹ̀késẹ̀.

Ó ní òun gbọ́ pé ó tún lọ sí àwọn ilé ìwòsàn míì níbi tí wọ́n ti bá tún ọwọ́ náà tò, tí wọ́n sì tún da dúró síbẹ̀.

"Nígbà tí mo gbọ́, mo gbà á nímọ̀ràn pé kó padà sí ilé ìwòsàn Bowen University Teaching Hospital, BUTH ní Ogbomoso.

"Ní ilé ìwòsàn BUTH láti mọ̀ pé egungun rẹ̀ ti le tó sì ti ń kán káàkiri ara rẹ̀. Dókítà kan sọ fún mi pé Adegoke ti ní àìsàn jẹjẹrẹ inú egungun tó sì ti ń ṣàkóbá fáwọn sẹ́ẹ̀lì ara rẹ̀ kan.

"Wọ́n sọ wí pé ó ṣeéṣe kí ó má yè é kódà bí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ abẹ láti pààrọ̀ àwọn egungun ara rẹ̀."

Ó sọ pé nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà nìyẹn àti pé kìí ṣe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló lù ú tí ẹ̀mí fi bọ́ lára rẹ̀.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, alága ẹgbẹ́ olùkọ́ Ogbomoso, Binuyo Folashade Adedoyin sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà kìí ṣe pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló lu olùkọ́ náà tó fi jáde láyé.

Ó ní ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nígbà tó fẹ́ lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kàn jẹ́ sábàbí ni àti pé kò ní ohunkóhun ṣe nípa ikú rẹ̀.