Àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ kí Tinubu gbé rèé kí Trump má ba à ṣe ìkọlù sí Nàìjíríà - Pásítọ̀ Adeboye

Pasítọ̀ Adeboye mú gbohùngbohùn dání níwájú pẹpẹ

Oríṣun àwòrán, Pastor E. A. Adeboye/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Pásítọ̀ àgbà ìjọ oníràpadà, Redeemed Christian Church of God, RCCG, Pásítọ̀ Enoch Adeboye ti rọ Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu láti fòpin sí ìpèníjà ètò ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra nípa pípa àwọn agbéṣùmọ̀mí rẹ́ láàárín àádọ́rùn-ún (90) ọjọ́.

Pásítọ̀ Adeboye ló sọ èyí lórí ìdúnkokò Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump láti ṣe ìkọlù sí Nàìjíríà, bó ṣe ní ìpèníjà ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra nílò àmójutó ní kíákíá.

Àgbà pásítọ̀ náà fi ìkọnilóminú yìí hàn lẹ́yìn ètò Holy Ghost Service tí ìjọ náà tó wà sópin lọ́jọ́ Ẹtì.

Ó sọ pé ẹ̀mí àwọn èèyàn ṣe pàtàkì gidi, tó sì pàrọwà sí ìjọba àpapọ̀ láti fáwọn olórí ẹ̀ṣọ́ ààbò Nàìjíríà ní gbèdéke oṣù mẹ́ta láti fi ri pé àwọn agbéṣùmọ̀mí di ohun ìgbàgbé tàbí kí wọ́n pàdánù iṣẹ́ wọn.

Àgbà pásítọ̀ náà ní gbogbo àwọn ààrẹ tó wà nípò láti ìgbà tí ìkọlù ti ń wáyé ni òun ti bá jíròrò láti wá ọ̀nà tí wọ́n fi máa fòpin sí ìpèníjà náà.

"Mo gbìyànjú gbogbo agbára mi lórí gbogbo nǹkan tí mo bá wọn sọ ní kọ̀rọ̀ àmọ́ ìmọ̀ràn lásán ni mo lè gbà olórí orílẹ̀ èdè, mi ò lè pàṣẹ fún wọn.

"Tí wọ́n bá ní kí n sọ èrò mi, mà á sọ fún ìjọba pé kí wọ́n tètè gbé ìgbésẹ̀, èyí tó máa mú ọgbọ́n wá. Ẹ wá ọ̀nà láti bá Ààrẹ Amẹ́ríkà sọ̀rọ̀, kí wọ́n dá ìkọlù tí wọ́n fẹ́ ṣe dúró fún ọgọ́rùn-ún ọjọ́.

"Lẹ́yìn náà, ẹ sọ fún àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ ààbò láti fòpin sí ìwà ìgbéṣùmọ̀mí láàárín àádọ́rùn-ún ọjọ́ tàbí kí wọ́n fi ipò wọn sílẹ̀."

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Adeboye ní òun fún ààrẹ àná, Muhammadu Buhari ní irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n tó kọminú pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbìyànjú ní ìbẹ̀rẹ̀, wọn kò gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti ri pé àwọn àṣeyọrí tí wọ́n rí ní ìbẹ̀rẹ̀ kẹ́sẹ járí.

"Ààrẹ Buhari pàṣẹ irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀. Kò sí níbí láti sọ ẹni tó fun ní ìmọ̀ràn náà. Ó mú ìmọ̀ràn náà lò àmọ́ kò tọ̀ ọ́ dé òpin. Lẹ́yìn tí oṣù mẹ́ta pé tí kò sí àbọ̀ kankan mo padà lọ ba láti bèèrè pé kí ló ṣẹlẹ̀ ṣùgbọ́n mi ò lè sọ gbogbo ohun tí a jọ sọ báyìí.

"Ìmọ̀ràn tí mà á gbà ààrẹ báyìí ni pé, tó bá pàṣẹ fáwọn olórí ẹ̀ṣọ́ ààbò, wọ́n gbọ́dọ̀ ri dájú pé kìí ṣe àwọn agbéṣùmọ̀mí nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ pa, wọ́n gbọ́dọ̀ ri dájú pé àwọn pa gbogbo àwọn tó ń ṣe onígbọ̀wọ́ fún wọn, bó bá ṣe lè wù kí wọ́n lágbára tó."

Ó ní ìdí tí òun fi sọ pé ìjọba Nàìjíríà gbọdọ̀ tètè gbé ìgbésẹ̀ láti fòpin sí ìpèníjà ààbò yìí ni pé tí Amẹ́ríkà bá ṣe ìkọlù sí Nàìjíríà, kò sí orílẹ̀ èdè kankan ní àgbáyé tó máa ṣe ìrànwọ́ fún wa.

"Tí Amẹ́ríkà bá ṣe ìkọlù sí wa, Russia, China àtàwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé kàn máa bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ náà ni nítorí nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe nìyẹn. Britain kò ní wá ràn wá lọ́wọ́, kò sí orílẹ̀ èdè àgbáyé kankan tó máa ṣe bẹ́ẹ̀," ó sọ.

Bákan náà ló rọ ìjọba láti ṣàwárí, kí wọ́n sì fojú àwọn tó ń ṣe àtìlẹyìn fáwọn agbéṣùmọ̀mí náà léde láì fi bí wọ́n bá ṣe lágbára tó ṣe.

Ó fi kun pé ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ báyìí kìí ṣe ọ̀rọ̀ Kristẹni tàbí mùsùlùmí nìkan nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àwọn aláìṣẹ̀ ló ń ṣòfò.