Ẹ̀sọ̀pẹ̀lẹ́ ló yẹ kóo fi dá sí ìpèníjà ààbò Nàìjíríà - Ìjọba àpapọ̀ rọ Trump

Ààrẹ Amẹ́ríkà wọ kóòtù dúdú ní apá òsì, Ààrẹ Bola Tinubu mú gbohùngbohùn dání ní apá òsì

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Bola Tinubu/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ìjọba Nàìjíríà ti képe ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump láti fọgbọ́n inú wo ìlànà rẹ̀ sí ìpèníjà ètò ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra.

Mínísítà fétò ìròyìn àti ìlanilọ́yẹ̀ Nàìjíríà, Mohammed Idris ló pe ìpè náà níbi ìpàdé pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn tó ṣe lọ́jọ́rú ní ìlú Abuja.

Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump dúnkokò láti ṣe ìkọlù sí Nàìjíríà lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ń ṣekúpa àwọn Kristẹni lọ́nà ìpanirun ní Nàìjíríà.

Mínísítà náà ní Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀ èdè tó kún fún onírúurú ẹ̀yà àti ẹ̀sìn, tó ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti mú ìgbòòrò bá ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀ àti ètò ààbò rẹ̀.

"A gbàgbọ́ pé níní ìjíròrò ni ọ̀nà kan tó dájú, tó sì dára jùlọ láti ri pé àlááfíà jọba káàkiri àgbáyé.

"Nàìjíríà ṣetán láti fààyè gba ìjíròrò, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti àtìlẹyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè àgbàyé tó fi mọ́ Amẹ́ríkà láti kojú ìpèníjà ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra."

Idris tẹmpẹlẹmọ pé ìṣèjọba tọ wà lóde ní ìfarajìn láti kojú ìgbéṣùmọ̀mí, àwọn agbébọn, ìjínigbé àtàwọn ìwà ọ̀daràn míì tó ń bá Nàìjíríà fínra.

Ó fi kun pé Nàìjíríà ń ṣe bẹbẹ, tí wọ́n sì ń gboríyìn nídìí gbígbé ogun ti ìwà ìgbéṣùmọ̀mí pẹ̀lú àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn àṣeyọrí ní ẹkùn ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó ní ìjábọ̀ àjọ Global Terrorism Index tí wọ́n gbé jáde nínú oṣù Kẹta ọdún yìí fi hàn pé ìkọlù àwọn agbéṣùmọ̀mí ti lọlẹ̀ gidigidi lòdì sí bó ṣe ń wáyé láti bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn.

"Kìí ṣe ìjọba Nàìjíríà ló sọ èyí, àjọ àgbáyé ló fi ìkéde yìí síta," ó sọ.

"Láti bíi oṣù mẹ́jọ sẹ́yìn ni iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà ti tú àwọn agbéṣùmọ̀mí ti iye wọn jẹ́ 592 ká ní ìpínlẹ̀ Borno nìkan, ọ̀pọ̀ wọn ni wọ́n ti rán sí ọ̀run àrèmabọ̀.

"Àwọn èèyàn tó lé ní 11,200 tó wà ní àhámọ́ ló ti gba ìtúsílẹ̀, tí èyí sì ń tẹ̀síwájú. Ní pàtàkì jùlọ, àwọn agbéṣùmsmí tó lé ní 124 ni wan ti juwọ́ sílẹ̀, wọ́n ti kó ohun ìjà ogun wọn tó lé ní 11,000 sílẹ̀ fáwọn iléeṣẹ́ ètò ààbò."

Gẹ́gẹ́ bí mínísítà náà ṣe sọ, ìṣèjọba tó wà lódé ti dókóowò nípa fífi ọ̀bítíbitì owó ra àwọn nǹkan ìjà ogun fáwọn iléeṣẹ́ ètò ààbò.

Mínísítà náà fi kun pé Ààrẹ Bola Tinubu ń ṣe àtìlẹyìn fáwọn iléeṣẹ́ ológun pẹ̀lú ṣíṣe àfikún àbá ìsúná àwọn iléeṣẹ́ ètò ààbò.

Ó ṣàlàyé pé Ààrẹ Tinubu ti ṣàfihàn ìfarajìn rẹ̀ láti fòpin sí ìgbéṣùmọ̀mí, àwọn agbébọn àtàwọn ọ̀daràn míì tó ń da omi àlááfíà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láàmú.

Bákan náà ló tún ṣàlàyé nípa àwọn iṣẹ́ ológun tó ń wáyé ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá Nàìjíríà èyí tó ní ó ti ṣokùnfà báwọn agbébọn kan ṣe ti juwọ́ sílẹ̀ ní ẹkùn náà.

Ẹ ó rántí pé ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump dúnkokò láti ṣe ìkọlù sí Nàìjíríà fẹ́sùn pé àwọn Kristẹni ń kojú ìpànìyàn tó lágbára.

Trump ní Amẹ́ríkà kò lè máa wòye kí ìpànìyàn bẹ́ẹ̀ máa tẹ̀síwájú, tó sì ní kí àwọn aṣòfin Riley Moore àti Tom Cole láti ṣe ìwádìí àwọn ìkọlù náà.

Ẹ lọ fọkàn balẹ̀, kò séwu lórí ọ̀rọ̀ tí Trump sọ nípa Naijiria - Tinubu

Aarẹ Bola Tinubu n woye lori ijokoo , o wọ aṣọ buba olomi aro pẹlu awo loju

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/X

Aarẹ Bola Tinubu ti kepe awọn ọmọ Naijiria lati fọkan balẹ lori ọrọ ti Donald Trump sọ pe o ṣee ṣe ki Amẹrika ko ọmoogun wọ Naijiria lati koju awọn agbesunmọmi to ni wọn ''n ṣeku pa awọn kristẹni.''

Tinubu sọ pe ijọba n gbe igbesẹ lati pese aabo to peye fun araalu ati dukia ọmọ Naijiria.

Minisita fun eto iroyin ati ilukoro, Mohammed Idris, lo fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin.

Lẹyin ti o ṣepade pọ tan pẹlu Tinubu, minisita ṣalaye pe aarẹ n gbiyanju agbara rẹ lati ri pe eto aabo gbe pẹẹli si i ni Naijiria.

Minisita fun eto iroyin ati ilukoro sọ pe ''a sọrọ pẹlu Aarẹ Tinubu lori idunkoko Trump mọ Naijiria.

Tinubu n ṣe agbeyẹwo awọn ọrọ ti Trump sọ lọwọ, o si n wa ọna lati sọ fun gbogbo agbaaye nnkan ti ijọba rẹ n ṣe lori eto aabo Naijiria.

''Ṣiṣe apejuwe Naijiria gẹgẹ bii orilẹede ti ko bọwọ fun ẹsin kii ṣe otitọ rara''

Ọgbẹni Idris sọ ninu fọnran ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ tẹlẹfisan NTA wi pe igbesẹ Tinubu eyi to fi yọ awọn ọga ileeṣẹ ologun Naijiria ni nnkan ọsẹ meji sẹyin ni ṣe pẹlu erongba aarẹ lati ṣatunṣe eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.

''Ṣiṣe apejuwe Naijiria gẹgẹ bii orilẹede ti ko bọwọ fun ẹsin kii ṣe otitọ rara.

Iwe ofin ilẹ wa la a kalẹ wi pe ẹnikẹni lominira lati ṣe ẹsin to ba wu u lai si idiwọ kankan.

Aarẹ n ṣe agbeyẹwo ọrọ ti Trump sọ nipa Naijiria lọwọ bayii, mo si gbagbọ pe oun to n ṣẹlẹ lọwọ n bọ wa di itan.

Iṣẹ n lọ lọwọ lori ọrọ yii, ijọba si tun ti ṣe agbekalẹ ọna ibaraẹnisọrọ tawọn orilẹede agbaaye yoo fi mọ nnkan ti Naijiria n ṣe lori ọrọ ti Trump sọ,'' Idris lo sọ bẹẹ.

Minisita fun eto iroyin fikun ọrọ rẹ pe Tinubu ti n ṣepade pọ pẹlu awọn olori ẹsin ni Naijiria.

O ni oniruuru ajọ ni ijọba apapọ n ba sọrọ lati ri pe awọn agbesunmọmi to n fẹmi araalu ṣofo dẹni igbagbe.