Kí làtunbọ̀tán àwọn orílẹ̀èdè méje tí Amẹ́ríkà ti kọ́mọ́ogun wọ̀ rí ní Áfíríkà?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Donald Trump sọ fawọn ọmogun Amẹrika lopin ọsẹ to kọja wi pe ki wọn wa lojufo tori oun le ran wọn lọ kọju ija sawọn ẹgbẹ agbesunmọmi ''ti wọn n fẹmi awọn kristẹni ṣofo loririlẹede Naijiria.''
Trump ni iṣekupani awọn kristẹni jẹ nnkan to n kọ ọpọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican lorilẹede Amẹrika lominu.
Ẹwẹ, ajọ kan to n ṣe itọpinpin ija to n bẹ silẹ kaakiri ti sọ pe ko si ẹri to le fidi rẹ mulẹ pe awọn agbesunmọmi n pa kristeni ju awọn musulumi lọ.
Ijọba apapọ Naijiria naa si ti sọ pe ko si nnkan to jọ ipanirun awọn kristẹni gẹgẹ bi Trump ṣe sọ.
Ijọba ni ko ba dara ti Amẹrika ba le ṣeranwọ lati dẹkun iṣẹ laabi tawọn agbesunmọmi n ṣe ni Naijiria.
BBC Yoruba ṣe atupalẹ orilẹede Afirika meje ti Amẹrika ti kogun ja ẹgbẹ agbesunmọmi nibẹ.
Somalia (1992–1994)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọdun 1992 si 1994 ni awọn ọmogun Amẹrika lọ si lorilẹede Somalia nibi ti wọn ti koju ẹgbẹ agbesunmọmi.
Lasiko ti ogun abẹle n lọ lọwọ ni Somalia ti iyan si mu, Amẹrika ko ọmogun lọ sibẹ lati ṣeranwọ.
Bakan naa ni Amẹrika tun ko oniruuru nnkan lọ sibẹ lati ran araalu lọwọ.
Eyi lo lo ṣokunfa ''ija Mogadishu ọdun 1993'' ti ọpọ eeyan fi mọ ipenija awọn ọmogun to n pẹtu sija nilẹ okeere.
Amẹrika ju ado oloro si ẹgbẹ agbesunmọmi al-Shabab lati ṣeranwọ fun ijọba Somalia.
Iroyin fidi rẹ mulẹ pe loṣu Kinni ọdun 2024 ni Amẹrika ṣeku pa olori ẹgbẹ al-Shabab mẹta lai ṣekọlu si araalu.
Liberia (2014–2015)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amẹrika ko ọmogun ati oniruuru nnkan elo lọ si Liberia lasiko ajakalẹ arun Ebola lati dekun itankalẹ arun naa.
Lara nnkan ti Amẹrika ṣe ni Liberia ni kikọ ibudo tawọn eeyan ti n gba itọju, ipese oogun ati idanilẹkọọ fawọn oṣiṣẹ eleto ilera.
Ṣaaju ominira ati lẹyin ominira Liberia ni Amẹrika ti ko ọmogun rẹ lọ si orilẹede naa lati pana ogun abẹle to ṣẹlẹ nibẹ fun ọpọlọpọ ọdun.
Senegal (2014–2015)
Amẹrika lọ si orilẹede Senegal lasiko ajakalẹ arun Ebola nibẹ.
Awọn ọmogun Amẹrika lọ si Senegal lati ṣeranwọ nipa pipese eto ilera fawọn eeyan nibẹ.
Eyi ni ko si jẹ ki arun Ebola tan kalẹ ju bo ti yẹ lorilẹede Senegal atawọn orilẹede to wa ni ayika rẹ.
Kenya (1998)
Amẹrika ko ọmogun rẹ lọ si Kenya lọdun 1998 lẹyin ti ẹgbẹ agbesunmọmi ṣe ikọlu si olu ileeṣẹ Amẹrika niluu Nairobi nibi ti eeyan 224 ti ku ti ọmọ Amẹrika mejila si wa ninu wọn.
Awọn ọmogun Amẹrika lọ si Kenya lati ṣeranwọ fawọn eeyan to farapa ti wọn le ni ẹgbẹrun kan.
Tanzania (1998)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikọlu agbesummọmi to ṣẹlẹ ni Kenya lọdun 1998 de orilẹede Tanzania naa.
Amẹrika ran ọmogun rẹ lọ si Tanzania lati ṣe itọju awọn to fara kaasa nibi ikọlu ọhun.
Awọn ọmogun Amẹrika tun dẹkun rukerudo to le ṣẹlẹ lẹyin ikọlu awọn agbesunmọmi.
Bakan naa ni ileeṣẹ ologun Amẹrika tun ṣe iwadii ohun to ṣokunfa ikọlu naa.
Libya
Loriṣii ọna ni Amẹrika ti ṣiṣẹ lorilẹede Libya, awọn ọmogun Amẹrika ti figba kan ṣiṣẹ lati koju ẹgbẹ agbesunmọmi ISIS ki idasilẹ ijọba fun gbogbo araalu le waye.
Ileeṣẹ ologun Amẹrika tun ti kogun wọ Libya ri lọdun 1986 ati lọdun 2011 eyi to fopin si ijọba Muhammar Gaddafi.
Bakan naa ni Amẹrika tun ju ado oloro si Libya laarin ọdun 2015 si 2019 lasiko ogun abẹle nibẹ.
Niger

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amẹrika ko awọn ọmogun rẹ lọ si orilẹede Niger lati koju ẹgbẹ agbesunmọmi to n ṣọṣẹ nibẹ.
Ọpọ eeyan ni ko mọ bi ọmogun Amẹrika ṣe pọ to ni Niger tẹlẹ, ikọlu Tongo lọdun 2017 nibi ti ISGS ti pa ọmogun Amẹrika mẹrin ati ọmogun Niger mẹrin lo jẹ kawọn eeyan mọ.
Ọmogun Amẹrika ni Niger lasiko naa le ni ẹgbẹrin, eyi to jẹ iyalẹnu fun ọpọlọpọ.
Ni ọdun 2024 ni Amẹrika kede pe oun yoo ko awọn ọmogun oun kuro ni Niger lẹyin tawọn ologun ditẹ gbajọba orilẹede naa.
Loṣu Keje ọdun 2024 ni Amẹrika ko awọn ọmogun rẹ to wa ni ''Camp 101'' kuro tan, nigba tawọn to ku ni ''Camp 201'' kuro ni Niger lọjọ karun un oṣu Kẹjọ ọdun 2024.















