Èmi àti Makinde kìí ṣe ọ̀rẹ́, òṣèlú lásán ló pa wá pọ̀ – Wike

WIke ati Makinde lẹgbẹ ara wọn

Oríṣun àwòrán, Nyesom Wike/Seyi Makinde/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Minisita fun FCT, Nyesom Wike, ti sọ pe pe ko si ohun to pa oun ati gomina ipinlẹ Oyo, Makinde pọ lẹyin oṣelu, ati pe Makinde ko ni dije fun ipo Aarẹ lọdun 2027.

Wike lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels.

O ni ede aiyede to waye laarin oun ati Makinde ko ni nnkankan lati ṣe pẹlu orogun oṣelu amọ o waye ki ẹgbẹ oṣelu PDP maṣe kuna afojusun rẹ.

Nigba to n fesi lori boya ija oun ati Makinde da lori erongba Makinde lati du ipo Aarẹ lọdun 2027, niṣe ni Wike rẹrin keeke.

O ni "Ki lo n sọ yii kẹ? A n sọrọ lori bi a ṣe maa mi afẹfẹ alaafia o n sọ iranu.

"Ki lo n gbiyanju lati sọ pe inu mi ko dun pe o fẹ gbe igba ipo Aarẹ? Jọọ ma jẹ ki a fi ọrọ yii ṣere."

Wike fi kun pe ọrọ ipo adari kii ṣe ohun to yẹ ki eeyan maa fi ṣere, lẹyin naa lo kilọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ki wọn ṣọra fun fifi gọngọ fa ohun to ọwọ wọn ko to.

O tẹsiwaju pe "ma ṣi mi gbọ o, eyii kii ṣe ọrọ pe eeyan kawe gba oye PhD tabi pe o jẹ onimọ ẹrọ abi agbẹjọro.

"Iyẹn kọ la n sọ, kii ṣe ki eeyan kan dede ji laarọ ọjọ kan ko si sọ pe oun fẹ dije du ipo Aarẹ, rara o."

"Awọn kan fẹ sare wọ ẹgbẹ lọjọ kan ki wọn si di adari ẹgbẹ naa lojiji… Melo ninu wọn lo ti sin ẹgbẹ oṣelu PDP bii emi?"

"Emi ati Makinde kii ṣe ọrẹ"

Nigba ti wọn bere lọwọ rẹ boya ọrẹ aarin oun ati Makinde ti daru o ni awọn kii ṣe ọrẹ bi ko ṣe alabaṣiṣẹpọ.

O ni "Ki lo n gbiyanju lati sọ pe ọrẹ ni wa? Rara o, alabaṣiṣẹpọ lasan ni wa.

"Ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa ni awa mejeji, alabaṣiṣẹ inu oṣelu lasan ni wa, ko si si ofin kankan to sọ pe awọn alabaṣiṣẹ ninu oṣelu gbọdọ wa papọ titi lai."

Nigba to n sọrọ lori ohun to fa ede aiyede laari noun ati Makinde, Wike sọ pe ko ju ọrọ lori bi ẹgbẹ oṣelu PDP naa yoo ṣe tẹle ofin, ati bi yoo ṣe de ipo agba to yẹ ko de.

Gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ naa ni oun ko dalẹ Makinde tabi awọn gomina G-5 ẹgbẹ naa rara ati pe ni dalẹ ẹgbẹ naa lailai.

Minisita naa ni asiko ko tii to fun PDP lati maa sọrọ nipa eto idibo Aarẹ ọdun 2027 amọ ki wọn kọkọ lọ ṣe ipade gbogbogbo ẹgbẹ naa ki wọn to maa dabaa ọdun 2027.