Ìyàwó mi di àwátì nílùú Abuja, kò lè sọ̀rọ̀ mọ́ nígbà tí mo padà rí i nípìńlẹ̀ Sokoto

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Mallam Jibrin Rabiu, ẹni ti iyawo rẹ, Khadijat Ado, di awati ni Ọjọbọ to kọja, Ọgbọn oṣu Kẹwaa ọdun 2025, ni Life Camp niluu Abuja ti ṣalaye bi wọn se ri iyawo rẹ nipinlẹ Sokoto ni ọjọ keji.
Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Daily Trust lọjọ Aiku, ọjọ keji oṣu kọkanla, Rabiu ṣalaye pe nigba ti oun de si ile oun ni Ọjọbọ ni oun ri pe wọn ti ji iyawo oun gbe.
O ni kete ni oun kesi ọrẹ oun kan to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa, to si kesi awọn ọlọpaa Life Camp, Gwarinpa ati awọn ẹsọ alabo mii lati bẹrẹ iwadii.
O ni imọ ẹrọ CCTV ni ile wọn ka asiko ti iyawo oun jade kuro ni ile titi to fi kuro nibi ti CCTV ko ti le ri mọ.
Gẹgẹ bii o ṣe sọ, gbogbo igbiyanju lati ri iyawo rẹ jasi pabo lọjọbọ.
Mallam Jibrin ni oun gba ipe kan ni ọjọ Ẹti pe wọn ti ri iyawo oun ni ipinlẹ Sokoto, ṣugbọn ko le sọrọ mọ.
O fikun pe iyawo oun ko le sọrọ mọ titi di asiko yii ṣugbọn oye rẹ ti pada. O ni awọn n fi ọrọ ranṣẹ si ara awọn olri ayelujara.
O ni iyawo oun sọ fun pe ni ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, oun kan ṣadede gbọ ti eeyan kan pe orukọ oun, ti oun si jade lati lọ ba eeyan. O ni nnkan ti oun ranti mọ niyẹn ko to di pe o ri ara rẹ nipinlẹ Sokoto.
"O ni nigba to de si Sokoto, o pada eeyan kan to bẹrẹ pe ki o fun oun ni iwe ati bairo, nibẹ lo ṣalaye gbogbo ohun to ṣẹlẹ si nigba ti ko le sọrọ mọ."
Mallam Jibrin tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe ẹni ti iyawo oun ba sọrọ lo pe oun, ti oun si ni ko gbe iyawo oun lọ ba awọn mọlẹbi kan nipinlẹ Sokoto.
O ni iyawo si wa nipinlẹ Sokoto ṣugbọn ko ti le sọrọ, to si fẹ lọ si ipinlẹ Sokoto lati mu pada wa si ile.
Gbogbo akitiyan awọn akọroyin lati jẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lo jasi pabo, ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ilu Abuja, Josephine Adeh ko sig be ipe rẹ.















