Kí ló lé obìnrin yìí àtọmọ rẹ̀ tí wọ́n fi lọ ń gbé abẹ́ àpáta?

Oríṣun àwòrán, Nina Kutina
- Author, Various correspondents
- Role, BBC News Russian
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9
Ninu igbo kan nitosi Gokarna, iyẹn ilu kan to gbajumọ lorilẹede India fun bawọn arinrinajo ṣe maa n wọ lọ sibẹ, ti awọn eeyan to n gbe nibẹ fi diẹ le lẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn (25,000) a ri ọmọde kan to ni irun pupa lori, o n fẹsẹ rin kiri lai wọ bata.
Agbegbe àpáta naa jẹ ibi kan ti awọn arinrinajo maa n lọ nitori awọn aaye mimọ to wa nibẹ.
Nigba ti awọn ọlọpaa wadii ọrọ ọmọde to n rin ni bebe igbo yii, ohun ti wọn ko ro tẹlẹ ni wọn ri. :
Wọn ri obinrin ọmọ orilẹede Russia kan torukọ rẹ n jẹ Nina Kutina, pẹlu awọn ọmọ rẹ obinrin méjì.
Ọjọ́ ori wọn jẹ marun-un ati mẹfa, wọn n gbe ninu iho kan ti wọn fi ọwọ hun awọn nnkan ti wọn n lo ninu rẹ, ti iyoku si jẹ eweko.
"Awa naa ko gbe ninu iho bayii ri." Kutina, ẹni ogoji ọdun lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
Bawo lo ṣe wa di ẹni to n gbenu igbo bii ẹranko?
Arabinrin Kutina ṣalaye pe oṣu mẹsan-an ni oun pẹlu awọn ọmọ oun fi gbe ninu iho.
O ni lasiko naa, ọmọ oun ọkunrin torukọ rẹ n jẹ Luchezar, n gbe pẹlu ọrẹ rẹ kan ni Arambol, ilu kan ti ko fi bẹẹ jinna, nibẹ lo ti n lọ sileewe.
Inu igbo ni iho ti wọn n gbe yii wa bi Kutina, ṣugbọn o sunmọ Gokarna ti wọn ti le ri eso ra.
Wọn ki i jẹ ẹran. Irufẹ awọn eeyan ti a mọ si vegetarian lo pe awọn ọmọ rẹ obinrin mejeeji, wọn ki i jẹ ẹran rara latigba ti wọn ti dele aye.
O ni Iṣẹda si ba wọn ṣe e, ohun gbogbo ti wọn n jẹ bii eweko lo n ba wọn lara mu, wọn ki i dubulẹ aisan bi iya wọn ṣalaye fun BBC.
"Ọpọ eeyan lo maa n lọ sibẹ fun iṣẹ isin, ibi to wuyi ni. Awa naa wa sibi lati mọ bo ṣe ri ni .
A fẹran nnkan to ba ti jẹ ti Iṣẹda (Nature), a si ti gbe ọpọ aaye lorilẹ aye yii — Inu igbo ni o, aginju ni o ati bẹẹ bẹẹ lọ. Inu iho ti a wa gbe yii nikan lo jẹ iriri tuntun fun wa."
Kutina lo sọ bẹẹ.
O ṣalaye fun BBC pe o tun wu oun lati maa gbe ninu iho yii koun le fi daro iku ọmọ oun ọkunrin to dagba ju, ti ọmọ naa si ṣe alabapade iku ojiji ninu ijamba ọkọ loṣu Kẹsan-an ọdun 2024.
Dmitry, lo pe orukọ ọmọ to ku yii, o ni asiko ibanujẹ gan-an lo jẹ foun nigba naa.
Nipa bi wọn ṣe n sun ninu iho yii, Kutina kan ibusun onigi, o tẹ ẹni silẹẹlẹ, o si fi awọn iṣẹ ọna afọwọṣe to jẹ ti ẹbi rẹ kọ sibẹ lati mu ko rẹwa bi aworan lara ogiri.
Koda, awọn ọlọpaa to ṣewadii wọn gan-an fidi ẹ mulẹ, pe o jọ pe awọn ẹbi yii n gbe igbe alaafia ninu iho, ṣugbọn wọn gbiyanju lati jẹ ko ye Kutina pe inu igbo to n gbe pẹlu awọn ọmọde yii ki i ṣe aaye ire.
Wọn jẹ ko mọ pe aabo ko si nibẹ, nitori ejo ati awọn ẹranko buburu kun inu igbo, o si ṣee ṣe ki ilẹ tun ri lasiko ojo. Wọn ni ewu loko Longe nibi to fi n ṣe ibuba.
"Ejo ko ge wa jẹ ri. Ẹranko kankan ko si kọlu wa ri. Fun ọpọ ọdun, eeyan nikan la bẹru." Bẹẹ ni Kutina ṣe kọ ọ si oju opo Telegram rẹ.
Ṣugbọn awọn ọlọpaa sọ pe iwe irinna Kutina ti lejọ, o ti yẹ ko ṣe atunṣe rẹ, awọn si ko wọn si aaye kan fun awọn arinrinajo.
Ninu alaye rẹ, Arabinrin Kutina sọ fun BBC pe lẹyin iku ọmọ oun ọkunrin yẹn, oun ko ni agbara lati maa ṣe iwe irinna kankan kiri.
Loṣu Kẹsan-an to kọja yii, wọn da wọn pada si Russia -Nibi igbesi aye alajọṣe to ti mọ tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Nina Kutina
Àràmàndà obìnrin tó ń fi ejò ṣe alábàágbé
Arabinri Kutina tẹsiwaju ninu alaye rẹ, o ni Leningrad ti a mọ so St Petersburg bayii ni wọn ti bi oun. O kawe niluu Siberia, Krasnoyarsk, fun bii ọdun mẹjọ. Lẹyin naa lo rin irinajo kọja okun Russia, o si gbe ni Ukraine, Thailand, Malaysia, Indonesia, Sri Lanka, Costa Rica, Nepal ati India lawọn asiko kan.
O gboye ninu ẹkọ, ṣugbọn iṣẹ awọn to n mu inu ile rẹwa (interior designer) lo n ṣe ni Moscow, o kuro ni Russia lọdun mẹẹẹdogun sẹyin pẹlu ọmọ rẹ ọkunrin to dagba ju, Dmitry.
"Ko wu mi ki n gbe ile gidi ni Moscow. Eti okun lo wu mi ki n maa gbe, kawọn ọmọ mi le maa sara kiri lorii yẹpẹ okun, ki wọn le ri gbogbo aye. Ki aye wọn le kun fun ayọ ati ilera pipe."
Kutina lo sọ bẹẹ.
Ẹyin odi naa lo wa to ti bi Luchezar, lẹyin naa lo bi awọn ọmọ rẹ obinrin mejeeji — Ama ati Prema. O sọ fun BBC pe ile loun bi wọn si, lai si iranlọwọ agbẹbi oyinbo kankan, o ni ẹbi oun si wa niṣọkan digbi ni, to ba di ti iṣọkan tootọ.
"Gbogbo wakati mẹrinlelogun to wa ninu ọjọ ni mo fi maa n wa pẹlu awọn ọmọ mi. Mo gboye nimu imọ ẹkọ (Degree in Education), mo mọ nipa iṣẹ ọnà, olorin si tun ni mi."
Kutina sọ pe abẹ ọrun to funfun balai lai si aabo loun gbe fun ọpọ ọdun pẹlu alaafia.
Loju opo Telegram rẹ, PecheRNaYa ZhizN (ti itumọ rẹ jẹ igbesi aye ninu iho), o polowo ẹkọ nipa bi wọn ṣe n fi owu hu nnkan sibẹ ( knitting lessons), o si loun tun n kọ awọn eeyan ni nnkan yiya ati gbigbẹ igi lere (sculpting) nigba toun wa ni ahamọ.
Ojugba rẹ ni India, Vasily Kondrashov, ṣapejuwe Kutina bii "Akọni lọna kan", o ni Kutina lo kọkọ gbe inu igbo Goan pẹlu awọn ọmọ rẹ ni nnkan bii ọdun mẹwaa sẹyin.
Ọgbẹni Kondrashov ṣabẹwo si i lapa Ariwa igbo Goan, o si wo igbesi aye Kutina: "Laaarin igi nla kan, Nina mu yara meji jade pẹlu aṣọ — o fi ẹyọkan ṣe yara igbalejo to ni pẹpẹ, o si fi ikeji ṣe yara ti yoo maa sun."
"Labẹlẹ, nibi ti igi wa, odo kekere kan wa nibẹ. Amọ̀ lo fi ṣe gbogbo agbegbe, ọwọ lo fi ṣe ijokoo to wa nibẹ, ati aaye kan to ti n dáná, o ko awọn nnkan idana rẹ sibi kan o si ko awọn nnkan iṣere ọmọde si apa mi-in.
'Ṣe ẹru ejo ko ba ọ ni? Mo beere lọwọ rẹ.
O da mi lohun pe, 'Ejo meji lo n gbe nitosi ile wa, a si mọ ara wa."
Ọgbẹni Kondrashov lo ṣalaye bẹẹ nipa Kutina, aramamda obinrin to n fi ejo ṣe alabaagbe.

Oríṣun àwòrán, Nina Kutina
Ìjọba gbẹ ìgbésẹ̀
Arabinrin Kutina sọ pe oun ni ki awọn agbofinro gba bẹẹli oun, ki wọn si jẹ koun lọọ gba ile, ṣugbọn wọn ko gba. Kaka bẹẹ, o ni atimọle awọn obinrin ni wọn fi oun si nitosi Bangalore, pẹlu awọn ọmọ oun obinrin. Wọn fi ọmọ rẹ ọkunrin si ibugbe kan ti ko jinna pupọ, Kutina sọ pe inira ni gbogbo eyi foun.
O sọ fun BBC pe igbesi aye inu ahamọ naa buru ju ti inu iho ilẹ ti oun n gbe tẹlẹ lọ.
Kutina ṣapejuwe ibugbe ọlọpaa bii eyi to kun fun idaamu. O ni awọn oṣiṣẹ ibẹ ji ounjẹ ati awọn nnkan ini oun, o ni wọn tun ji eeru oku ọmọ oun ọkunrin pẹlu, eeru toun tọju sinu iho — awọn ọlọpaa gbeṣẹ le gbogbo rẹ wọn ko si da a pada bo ṣe sọ.
"Awọn ọlọpaa sọ pe awọn n da aabo bo wa lọwọ ẹranko buburu, ṣugbọn ni tododo, nibi ti wọn fi wa si yẹn, awọn aayan nla-nla ni wọn fa wa le lọwọ, wọn maa n fo le awọn eeyan lori lalẹ bayii to jẹ pe ko sibi ti eeyan le sa si fun wọn."
"Wọn ro pe awọn ti da aabo bo awọn ọmọ mi lọwọ ebi ati otutu. Ṣugbọn ninu iho, mo maa n se ounjẹ aladun fun wọn. Ni ibudo agbofinro, ebi gidi lo n pa wọn, wọn ko si ni fitamin kankan lara."
BBC kan si awọn alaṣẹ India fun alaye "A ti n fi ọwọ gidi mu ọrọ ọmọ orilẹede Russia ti a gbọ awọn nnkan yii nipa rẹ. A ti ni ki Igbakeji Kọmiṣanna ati Amugbalẹgbẹẹ ẹkun-un Tumakuru ti won jẹ ọga agba wadii awọn ohun ti a gbọ yii, ki wọn si fun wa ni àbọ̀ rẹ. Bi awọn nnkan naa ba jẹ otitọ , a maa gbe igbesẹ ti yoo yi i pada lẹsẹkẹsẹ.''
Ọgbẹni P. Manivannan, Ọga agba ẹka to n ri si ọrọ araalu, ijọba Karnataka lo ṣalaye bẹẹ fun BBC Hindi.
Oṣiṣẹ mi-in to ni ka ma darukọ oun, sọ fun BBC pe "iwadii ti a ṣe ṣaaju fi han pe afikun ati asọdun pọ ninu nnkan ini rẹ to ni wọn ji naa. A o maa reti abọ iwadii awọn ọga."

Oríṣun àwòrán, Nina Kutina
Ọkùnrin kan yọjú, ó ní òun ni bàbá àwọn ọmọbìnrin Kutina
Gẹgẹ bi oṣiṣẹ kan to ba BBC sọrọ ni India ṣe sọ, Arabinrin Kutina kan si Ẹmbasi Russia lati ba a ṣe ọna ti yoo fi pada si Russia.
Ṣugbọn ọkunrin oniṣowo kan, Dror Shlomo Goldstein, ọmọ ilẹ Israeli to n gbe ni Goa, da igbesẹ naa duro nipa kikọwe si kootu, to si n beere pe ki wọn ko Ama ati Prema, ọmọ Kutina fun oun, nitori oun ni baba to bi wọn.
Ọkunrin naa ni ki wọn ma ṣe ko wọn lọ si Russia.
" Lẹnu ọdun diẹ si asiko yii, o ti ṣoro fun mi lati ri wọn [awọn ọmọbinrin naa]. Koda nigba ti mo ri wọn, wọn ko fẹ sun mọ mi, wọn ni mo ti kọ awọn ti kawọn too waye rara. Ṣugbọn emi o figba kan dawọ ifẹ wọn duro."
Ọgbẹni Goldstein lo kọ ọ bẹẹ si oju opo ayelujara.
O sọ fun BBC pe awọn ọmọ mejeeji loun fẹ gba, ṣugbọn kootu ni oun yoo kọkọ ṣe ayẹwo DNA na, eyi ti oun ko ṣe ki iya wọn too ko wọn lọ.
Ni tiẹ, Arabinrin Kutina kọ lati ba BBC sọ ohunkohun nipa Ọgbẹni Goldstein, o loun ko ni ajọsọ pẹlu ẹni yẹn.
Kutina ṣalaye fun BBC pe Moscow loun n gbe bayii pẹlu awọn ẹbi oun.
Arabinrin Kutina ko ṣeto lati ran awọn ọmọ rẹ lọ sileewe, kaka bẹẹ, o ni wọn yoo maa kawe nile ni.
O fi kun un pe oun maa n gbadun rinrin kiri ninu igbo pẹlu awọn ọmọbinrin oun, ṣugbọn oun tun n wo ọjọ iwaju pẹlu - ọjọ iwaju ti awọn yoo ti le ṣewe tuntun, ki oun atawọn ọmọ oun le maa rin irinajo kiri awọn aaye tuntun, ti awọn yoo ti maa ṣe faaji, wadi ohun tuntun.
Afikun iroyin lati ọwọọ Imran Qureshi















