Wo akọni obìnrin ọmọ Nàíjíríà tó balẹ̀ sí London pẹ̀lú ọmọ̀ kékeré mẹ́ta, báàgi kan àti owó díẹ̀ àmọ́ tó padà di ògbóǹtarigì onímọ̀ sáyẹ́ǹsì

Oríṣun àwòrán, photos du palace
- Author, Jo Fidgen et Andrea Kennedy
- Role, BBC World Service, serie Outlook
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8
Lọ́jọ́ kan lọ́dún 1990, Ijeoma Uchegbu pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́ta èyí tí ọmọ ọwọ́ wà nínú wọn, balẹ̀ sí ìlú London pẹ̀lú báàgì kan ṣoṣo àti owó díẹ̀ tí kò lè tó wọn ná láti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé tuntun.
Ijeoma padà sílùú London níbi tí wọ́n ti bi ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn.
Láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, ó bá ara rẹ̀ ní ilé ìjọba níbi tí ọ̀pọ̀ èrò ń gbé, tó sì ń tiraka láti jẹun àti ẹ ìtọ́jú àwọn ẹbí rẹ̀.
Báwo ló ṣe wá di ẹni tó ń léwájú nínú ìmọ̀ 'nanoparticles'?
Ìrìnàjò Ijeoma bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ gbé oyún rẹ̀ láti Nàìjíríà lọ sí UK lọ́dún 1960, tí wọ́n sì fun ní orúkọ tó rẹwà lẹ́yìn tí wọ́n bi tán.
"Wọ́n fún mi lórúkọ Ijeoma èyí tó túmọ̀ sí ìrìnàjò rere pẹ̀lú èròńgbà pé nǹkan máa lọ déédéé fún àwọn ní orílẹ̀ èdè tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kó dé.
Ìyá Ijeoma ń kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ London School of Economics, tí bàbá rẹ̀ sì ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná nígbà náà. Nítorí àti lè fojú sí ẹ̀kọ́ wọn, wọ́n gbé Ijeoma lọ sọ́dọ̀ ẹnìkan tí yóò máa tọ́jú rẹ̀ ní Kent.
Ọdún mẹ́rin ni Ijeoma lò lọ́dọ̀ àwọn tó ń tọ́jú rẹ̀ náà kí bàbá rẹ̀ tó wá gbe lọ́jọ́ kan.
"Mi ò mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, mo kàn rántí pé Aunt Pat, orúkọ ti mo máa ń pe ìyá tó gbà mí tọ́ nìyẹn kò sí pẹ̀lú mi mọ, tó sì jẹ́ pé bàbá mi ni mow à pẹ̀lú."
Bákan náà ni àwọn òbí Ijeoma kò sí papọ̀ mọ́, tó sì jẹ́ pé ìyàwó míì tí bàbá Ijeoma fẹ́ ló ń tọ́jú rẹ̀ láti ìgbà tí wọ́n ti lọ gbe kúrò lọ́dọ̀ alágbàtọ́ rẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni Ijeoma wà kó tó mọ̀ wí pé ìyá náà gan kọ́ ló bí òun.
"Ìgbà yẹn ni mo tó mọ̀ pé ìyá míì wà tó da ẹ̀jẹ̀ lémi lórí gangan."

Oríṣun àwòrán, Avec l'aimable autorisation d'Ijeoma Uchegbu
Ìyá míì
Nígbà tí Ijeoma pé ẹni ọdún mẹ́tàlá ló tó fi ojú kan ìyá rẹ̀ gangan.
Ó rántí pé níṣe ni inú ìyá òun dùn gan-an nígbà tí àwọn pàdé. "Níṣe ni ara rẹ̀ ń gbọ̀n nígbà tí a di mọ́ra wa. Sí mi àjòjì ló jẹ́ àmọ́ òpin ọ̀sẹ̀ yẹn dùn yùngbà fún àwa méjéèjì."
"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn ni ìyá mi rà fún mi. Tí mo bá ti wo nǹkankan báyìí ni ìyá máa bèèrè pé ṣé mo fẹ́ ni?"
Ohun kan tí wọn kò sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ìdí tí ìyá rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ kópa nínú ìgbé ayé rẹ̀.
"Mo rò ó pé ìdáhùn tí mà á gbọ́ máa ṣòro fún àwa méjéèjì tí mo bá bèèrè, ìdí nìyẹn tí mo ṣe dákẹ́, láti gbádùn àkókò tí a jọ ní papọ̀."
Ìgbà náà sì ni wọ́n ríra kẹ́yìn.
Lẹ́yìn ọdún kan tí wọ́n pàdé ni ìyá rẹ̀ kó lọ sí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà níbi tó kú sí lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tó kó débẹ̀ lẹ́ni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.
"Ó dùn mí gan nítorí mi ò rò ó pé a kò ní ríra mọ́."
Ó pàdánù ìyá tó gbà á tọ́, ìyàwó bàbá rẹ̀ àti ìyá tó bi lọ́mọ gangan àmọ́ bàbá rẹ̀ ṣì wà pẹ̀lú rẹ̀.
Ó sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ mọ́kànlá lápapọ̀ ni bàbá òun bí kó tó jáde láyé, ó máa ń fetí sílẹ̀ fún òun, tí àwọn sì jọ máa ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan papọ̀.
Ó ní bàbá òun máa ń fi gbogbo ìgbà sọ pé òun máa padà sí Nàìjíríà lọ́jọ́ kan àmọ́ ogun abẹ́lé tó ń wáyé lásìkò náà kò jẹ́ kó tètè rọrùn fún un.

Oríṣun àwòrán, Avec l'aimable autorisation d'Ijeoma Uchegbu
Ní àkókò kan...
Ijeoma dàgbà sí UK láàárín ọdún 1960 sí 1970, lásìkò náà bíbu ẹnu àtẹ́ lu ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà kò ì tíì pọ̀ báyìí.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àwọn olùkọ́ tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n sì máa ń sọ fun pé ó le di ohunkóhun tó bá fẹ́, ilé ìtajà ni Ijeoma ní èròńgbà láti ṣiṣẹ́.
"Mi ò ríra mi gẹ́gẹ́ bí ẹni tó le di ọ̀jọ̀gbọ́n nítorí kò sí ẹni tó dàbí mi nínú àwọn iṣẹ́ náà."
Àyípadà bá gbogbo èrò rẹ̀ yìí lẹ́yìn àlá bàbá rẹ̀ láti padà sí Nàìjíríà wá sí ìmúṣẹ ṣùgbọ́n tí ìrìnàjò náà mú àwọn ìnìra àti ìṣòro kan dání.
Ijeoma ṣe àárẹ̀ nígbà tí wọ́n dé Nàìjíríà fún ọ̀pọ̀ oṣù táwọn dókítà sì sọ pé òòrùn ti pọ̀ jù fún ni.
Àyípadà

Oríṣun àwòrán, Avec l'aimable autorisation d'Ijeoma Uchegbu
Nígbà tí ara rẹ̀ yá tán tó bẹ̀rẹ̀ sí ní lọ sílé ẹ̀kọ́, nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún-un. Tí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ síi yàtọ̀ sí nǹkan tó ń bá bọ̀ láti UK.
Ní orílẹ̀ èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ ogun abẹ́lé, kò sí iná àti omit í èyí sì yàtọ̀ sí bí ó ṣe rí ní orílẹ̀ èdè tó ti ń bọ̀ níbi tí omi àti iná mọ̀nàmọ́ná ti ya yẹ̀yẹ́.
Gbogbo nǹkan ló yàtọ̀, tó fi mọ́ ètò ẹ̀kọ́.
Ní UK, ó wà lára àwọn tó máa ń ṣe dada nínú ẹ̀kọ́ wọn ní kíláàsì rẹ̀. Ní Nàìjíríà, ó nílò láti yí ọkàn rẹ̀ padà nípa kíkọ́ nípa ìtàn Yúróòpù àti 'geography'.
"Nǹkan tó jọ ara wọn ni ìmọ̀ ìṣirò àti ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì, àwọn yẹn ni mo fara sí nítorí àwọn ló yé mi."
Lásìkò náà, ó ti yí ìpinnu rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nílé ìtajà padà. Ó sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kojú àwọn ìṣòro nígbà tí òun kọ́kọ́ padà sí Nàìjíríà, ó jẹ́ atọ́nà fún òun láti jí gìrì sí nǹkan tí òun padà jẹ́ láyé.
Láti ilé ọlọ́pọ̀ èrò sí rírí ìfẹ́
Ọdún mẹ́rìndínlógún ni Ijeoma wà nígbà tó rí ààyè sílé ẹ̀kọ́ gíga láti kọ́ nípa ìmọ̀ ìpoògùn. Lẹ́yìn náà ló tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè kejì, ṣe ìgbéyàwó, tó sì bí ọmọ mẹ́ta.
Àmọ́ nígbà tí ìgbéyàwó òun àti ọkọ rẹ̀ kò ló déédé, ó pinnu láti padà sí UK.
Láìní èròńgbà kan pàtó, owó díẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ́ẹ̀ta, Ijeoma balẹ̀ sí ìlú London, tó sì lọ ń gbé ilé tó wà fún àwọn tí kò bá rí ilé gbé ní UK.
"Láwọn àsìkò kan, àwa ẹbí mọ́kànlá là ń pín balùwẹ̀ kan lò, nígbà míì wọ́n máa ti ilẹ̀kùn ilé ìdáná tí a kò ní rí oúnjẹ sè.

Oríṣun àwòrán, Avec l'aimable autorisation d'Ijeoma Uchegbu
"Oṣù méje ni mol ò níbẹ̀, nígbà tí mo kúrò níbẹ̀, ó dàbí pé mo kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ni."
Ó ní pẹ̀lú ìṣòro tí òun kojú náà, òun kò gbèrò láti padà sí Nàìjíríà nítorí ohun tí òun là kọjá nínú ìgbéyàwó òun.
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ó wá ọ̀nà láti ṣiṣẹ́ ìwádìí láti tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ láti gba oyè ọ̀mọ̀wé, tó sì ṣiṣẹ́ lórí ìwádìí tí kò ní ìmọ̀ kankan lórí rẹ̀ tẹ́lẹ̀; 'tiny particles'.
Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta sígbà náà, ó lọ ibi àpérò kan tó mú àyípadà bá ìgbé ayé rẹ̀ lọ́nà àìrò.
Níbẹ̀ ló ti pàdé Andreas G. Schätzlein, ọmọ Germany tó jẹ́ onímọ̀ nípa sáyẹ́ǹsì, tí wọ́n sì jọ ní ọ̀rọ̀ àjọsọ fún ọjọ́ mẹ́rin èyí tó mú ìfẹ́ gabọkàn rẹ̀.
Ó ní lọ́jọ́ tí àpérò náà parí, òun fun ní àdírẹ́sì ilé òun bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun rò pé àwọn k]o ní ríra mọ́ nítorí ibi tí àwọn ń gbé jìnà síra.
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ ni Andreas G. Schätzlein kọ̀wé ránṣẹ́ sí Ijeoma, tó sì darapọ̀ láti máa gbé pẹ̀lú rẹ̀ ní United Kingdom pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta.
Yàtọ̀ sí pé Andreas jẹ́ ọkọ rẹ̀, wọ́n tún jọ ń ṣiṣẹ́ papọ̀ láti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìmọ̀ tuntun ní sáyẹ́ǹsì.
Wọ́n ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ nípa nanoparticle, ohun tó le mú oògùn dé àwọn ibi tó yẹ nínú ara láti jẹ́ kó ṣiṣẹ́ tó yẹ àti mímú àdínkù bá àwọn ìnira tó le kóbá ara.
"Tí a bá lo oògùn yálà oníkóró tàbí abẹ́rẹ́, ó máa kọ́kọ́ dé inú ẹ̀jẹ̀ kó tó lọ sí ẹ̀yà ara tó yẹ. nígbà míì èyí kò yẹ nítorí gbogbo ẹ̀yà tó yẹ kọ́ ni oògùn náà máa dé. Inú àwọn oògùn tó jẹ́ ti nanoparticles ni ìdáhùn wà," Uchegbu ṣàlàyé.
"Àwọn ẹ̀yà ara tí oògùn náà kàn ni àwọn nanoparticles máa lọ, tó sì máa mú àdínkù bá ìpalára tí wọ́n ń se fún ara."

Oríṣun àwòrán, Avec l'aimable autorisation d'Ijeoma Uchegbu
Ní àfikún, Ijeoma àti Andreas ṣe àwọn nanoparticles tó máa ma gbé oògùn dé àwọn ibi tó le lára tí oògùn kìí dé.
Pẹ̀lú ìwádìí tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí, wọ́n gbèrò láti ṣe ìtọ́jú ojú fífọ́ pẹ̀lú oògùn, mú àtúnṣe bá àwọn oògùn ara ríro àti wá àtúnṣe sí àwọn ìlàkàkà opioid.
Láàárín ẹ̀rín àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́
Uchegbu ti di akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó sì ti di ọ̀jọ̀gbọ́n lẹ́ka ìpoògùn nanoscience ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University College London, UCL àti ààrẹ ní Wolfson College ní University of Cambridge.
Ìmọ̀lára rẹ̀ sí sí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì jẹ́ kó tún máa lo àwàdà láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́.
"Mo ri pé bi mo ṣe máa ń ṣàwàdà ń jẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa tẹ́tí sí mi dáadáa. Nítorí náà ni mo ṣe lọ kẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́sẹ̀ mẹ́wàá nípa àwàdà.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà kún ṣíṣe àwàdà ní títà London.
Yàtọ̀ sí pé ó ń lo àwọn nǹkan tó kọ́, ó ní ó ti ṣe ìrànwọ́ fún òun láti fi bá ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀ níbi àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́pọ̀ èrò.

Oríṣun àwòrán, Phil Mynott
Ṣíṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nìkan kọ́ ló nífẹ̀ẹ́ sí, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní nífẹ̀ẹ́ sí jíjà fún àwọn èèyàn nígbà tó ló kópa níbi ìpàdé ètò àwùjọ kan ní UCL.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kò fẹ́ràn èrò náà nítorí kò yé òun àti pé òun kìí ṣe onímọ̀ nípa sáyẹ́ǹsì àwùjọ àmọ́ nígbà tó lọ síbi ìpàdé náà ó yí ọkàn rẹ̀ padà.
"Àwọn ìwádìí fi hàn pé àwọn ẹ̀yà kan kìí pegedé lórí ètò ẹ̀kọ́ wọn tàbí rí ìgbéga. Bẹ́ẹ̀ náà láwọn obìnrin kan láti ẹ̀yà kékeré kìí rí àwọn ẹ̀tọ́ tó yẹ."
Ijeoma darapọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìwádìí láti wá ojútùú sáwọn ìṣòro yìí.
Ó lo àwọn ìrírí rẹ̀ láti lọ sáwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ káàkiri láti rip é àwọn èèyàn tó wá láti ẹ̀yà tó kéré láti kópa nínú ẹ̀kọ́, sọ fún wọn láti sọ orúkọ wọn ní ọ̀pọ̀ ìgbà, kí wọ́n le ri pé àwọn náà ń rí ara wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan náà.
"Àwọn ìgbésẹ̀ náà ń ti ń ní ipa báyìí. A ti yọ gbogbo orúkọ àwọn eugenicists kúrò lára àwọn ilé, èyí tó jẹ́ ohun ìwúrí fún mi."
Bẹ́ẹ̀ náà ni èyí ti ń jẹ́ kí a gbọ́ ìròyìn rere.
"Obìnrin kan wá bá mi, ó sọ fún mi pẹ̀lú omijé lójú pé: 'Àkàndá èèyàn ni mí, mo kà fẹ́ dúpọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó ri dájú pé wọn yọ àwọn orúkọ (eugenicists) kúrò.'"
Ijeoma Uchegbu ni ó máa ṣòro láti fún èèyàn ní ìmọ̀ràn ṣùgbọ́n tó bá pọn dandan fún òun láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun máa ń sọ pé tí èèyàn bá fẹ́ yan iṣẹ́ kan láàyò, kó má ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí owó bíkòṣe òun tó bá wu èèyàn láti ṣe.
"Tí èèyàn bá ṣe ohun ó nífẹ̀ẹ́ sí gidigidi, gbogbo nǹkan máa di ìrọ̀rùn fún un."












