Wá ojútùú sí ètò ààbò tó mẹ́hẹ kó o sì dáàbò bo ọmọ Naijiria, Alaafin àti Ooni gba Tunji Disu n'ímọ̀ràn

Alaafin Oyo, Oba Abimbola Owoade wọ agbada damaasiki ati fila, Tunji Disu wọ aṣọ ọlọpaa dudu pẹlu fila, Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi, wọ agbada funfun ati fila funfun

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/Ooni Ile Ife/Alaafin Oyo/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Alaafin Oyo, Ọba Abimbola Owoade, ti rọ adele ọga ọlọpaa Naijiria tuntun, Tunji Disu, wi pe ko lo ọfiisi rẹ lati daabo bo ọmọ Naijiria.

Alaafin sọrọ yii ninu iṣẹ ikini ku oriire ti o fi ranṣẹ si ọga ọlọpaa ti Aarẹ Bola Tinubu ṣẹṣẹ yan sipo naa.

Ọba Owoade ninu atẹjade to fi sita lati ọwọ adari eto iroyin rẹ, Bode Durojaye, ṣapejuwe Disu gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ ti ki i fi iṣẹ ṣere.

Amọ, Alaafin ni nnkan ti araalu yoo fi gbe Disu sori iwọn ni bi o ba ṣe le wa ojutuu si iṣoro to n koju ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria si, ati iṣoro eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.

Kabiyesi naa sọ pe oun ni igbagbọ wi pe Disu yoo ṣe daadaa gẹgẹ bii ọga ọlọpaa Naijiria.

''Mo rọ ọga ọlọpaa tuntun wi pe ko ṣiṣẹ gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ, ki o si ri pe awọn araalu ni igbagbọ ninu awọn ọlọpaa pada.

Mo mọ pe Disu ti wa ni igbaradi fun ipo yii, tori o ti ṣe iṣẹ ribi ribi loriṣii riṣii ẹka ni ileeṣẹ ọlọpaa.

Gbogbo orilẹede Naijiria lo n wo ọ bayii fun eto aabo to peye, mo si mọ pe awọn erongba rẹ yoo mu ilọsiwaju ba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria.'' Alaafin lo sọ bẹẹ.

Wa ọna ti iṣoro eto abo to mẹhẹ yoo fi dopin ni Naijiria, Ooni rọ Tunji Disu

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrọ tiẹ, Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi, Ojaja Keji, naa rọ adele ọga ọlọpaa tuntun lati wa ọna ti eto aabo to mẹhẹ yoo fi di ohun igbagbe.

Ninu atẹjade kan ti Ooni fi sita ni Kabiyesi naa ti fọrọ yii mulẹ.

Ooni ṣapujuwe iyansipo Disu gẹgẹ bi eyi to bọ si asiko pẹlu bi ọrọ eto aabo ṣe ri ni Naijiria lọwọ yii.

Oonirisa sọ pe iriri ti Disu ti ni ninu iṣẹ ọlọpaa yoo ṣeranwọ fun un lati ṣe aṣeyọri ninu isẹ ti Aarẹ Tinubu gbe le e lọwọ.

Kabiyesi naa wa rọ awọn ọlọpaa wi pe ki wọn fọwọ sowọ pọ pẹlu Disu ki gbogbo erongba rẹ ba le wa si imuṣẹ.

Ooni ko ṣai lu Aarẹ Tinubu lọgọ ẹnu lori bi o ṣe n dari orilẹede Naijiria ati lori iyansipo Disu gẹgẹ bii ọga ọlọpaa tuntun.

Kabiyesi naa wa fi da aarẹ loju pe awọn ori ade ni Naijiria yoo tẹsiwaju lati maa gbaruku ti gbogbo eto ti aarẹ ba n ṣe lati mu ilọsiwaju ba orilẹede Najiria.

Ni ibẹrẹ ọsẹ yii ni Aarẹ Tinubu kede iyansipo Disu gẹgẹ bii adele ọga ọlọpaa Naijiria tuntun, lẹyin ti Kayode Egbetokun to wa ni ipo naa tẹlẹ kọwe fipo silẹ.