Ìdí rèé tí Manchester United kò fi ra Osimhen mọ́ kó tó mórílé Galatasaray

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Isaac Fanin
- Role, Newsday
- Author, Rob Stevens
- Role, BBC Sport Africa
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Idije AFCON ni idi ti ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ko fi ra ẹlẹsẹ ayo Naijiria, Victor Osimhen, ko to darapọ mọ ikọ agbabọọlu Galatasaray lorilẹede Turkey.
Benni McCarthy to ti figba kan ri jẹ ọkan lara awọn akọnimọọgba ni ẹgbẹ agbabọọlu Man United tẹlẹ ri lo sọ bẹẹ.
Ọpọ ẹgbẹ agbabọọlu lo fẹ ra Osimhen ni Yuroopu lẹyin to gba goolu mẹrindinlọgbọn sawọn fun Napoli ni saa bọọlu 2022/2023, eyi ti wọn fi gba ife ẹyẹ Serie A fun igba akọkọ lẹyin ọdun mẹtalelọgbọn.
McCarthy to jẹ ọkan lara igbakeji akọnimọọgba Erik Ten Hag lasiko naa ni ẹgbẹ agbabọọlu Man U sọ pe oun gbagbọ wi pe Osimhen ko ba fakọyọ fun Man U ti wọn ba le ra a nigba naa.
Amọ, McCarthy ni nitori idije AFCON to maa n bọ si aarin idije liigi ni Yuroopu lo jẹ ki United wa ẹlẹsẹ ayo mi ra dipo Osimhen.
''Ti eeyan ba fi £100m ra agbabọọlu kan, o maa ṣoro lati fi iru agbabọọlu bẹẹ silẹ lọ fun idije AFCON.
O maa nira fun ẹgbẹ agbabọọlu naa lati ṣe daadaa lasiko to ba lọ fun idije AFCON.
Idi niyi ti Man United fi pinnu lati wa agbabọọlu mii ra,'' McCarthy lo sọ bẹẹ.
Lẹyin naa ni Man U ra Rasmus Hojlund lati ẹgbẹ agbabọọlu Atalanta fun £72m loṣu Kẹjọ ọdun 2023.
Hojlund pada gba goolu mẹrindinlọgbọn sawọn fun Man U ninu ifẹsẹwọnsẹ marindinlọgọrun un to gba.
Napoli lo pada ya Hojlund losu Kẹsan an ọdun to kọja.
Amọ, lasiko yii ni Osimhen gba ami ẹyẹ African Footballer of the Year lọdun 2023, ko to darapọ mọ Galatasaray.
Bawo lawọn akọnimọọgba atawọn agbabọọlu ṣe n ṣe pẹlu ariwo lati ita?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
McCarthy gbagbọ pe Osimhen ko ba fakọyọ labẹ akọnimọọgba Ten Hag ti Man U ba fi le ra nigba naa.
''McCarthy sọ pe ''Osimhen maa n gba goolu sawọn daadaa, ki i feti si ariwo ọja tawọn eeyan maa n pa.
Osimhen ko le ni iṣoro ni Man United tori o ti ni oriṣiiriṣii iriri laye pẹlu ibi to ti wa ni Naijiria.
Oṣu Kinni ati oṣu Keji ti idije AFCON maa n bọ si gan an ni ko jẹ ki Man U pada ra a mọ.
O jẹ nnkan to bami lọkan jẹ gidi gan an tori mo fẹ ki iru ẹlẹsẹ ayo lati ilẹ Afirika bii Osimhen gbabọọlu fun Man United.
Bi idije AFCON ṣe n kọlu idije Liigi ilẹ Yuroopu
Ni bayii, iṣoro aifẹ kowo gidi le agbabọọlu Afirika lori le di ohun igbagbe laipẹ lẹyin ti ajọ CAF ti fẹ sọ idije AFCON di ọdun mẹrin mẹrin lati ọdun 2028.
Aarẹ ajọ CAF Patrice Motsepe ni ajọ naa gbe igbesẹ yii pẹlu ajọṣepọ FIFA.
Ṣugbọn McCarthy to jẹ akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Kenya to jẹ ọkan lara awọn orilẹede ti yoo gbalejo idije AFCON lọdun 2027 ti sọ pe oun ko ba fẹ ki CAF si maa ṣe idije AFCON lọdun meji meji ti wọn ti n ṣe tẹlẹ.
''Ajọ CAF si le gbe idije AFCON si ipari saa bọọlu ni Yuroopu laarin oṣu Kẹfa si oṣu Keje.
Amọ, ohun to maa tumọ si ni pa awọn agbabọọlu ko ni raye sinmi rara.
Ko ba dara ti wọn ba le fi i silẹ lọdun meji meji, niwọn igba ti ko ba ti tako asiko tawọn ikọ agbabọọlu n gbabọọlu lọwọ,'' McCarthy lo sọ bẹẹ.


























