Fes el Bali, ìlú 'Mẹ́dínà kékéré' tí ẹ̀sìn àti àṣà ìṣẹ̀mbáyé ti pàdé ara wọn
Fes el Bali, ìlú 'Mẹ́dínà kékéré' tí ẹ̀sìn àti àṣà ìṣẹ̀mbáyé ti pàdé ara wọn
Ni aringbungbun orilẹede Morocco, ilu Kan wa ti wọn n pe ni Fes el Bali.
Nnkan bii ẹẹdẹgbẹrun si ẹgbẹrun ọdun sẹyin ni wọn da ilu naa silẹ.
Ilu naa jẹ ilu kan ti ọpọ miran ti fi n we ilu Mẹdina nitori ilana ẹsin nibẹ.
Amọṣa kii ṣe ẹsin nikan lo duro fun bikoṣe okoowo ati wiwa imọ lẹkunrẹrẹ.
Ilu Iṣẹmbaye ni ilu Fes el Bali jẹ, koda awọn aṣa ati iṣe iṣẹmbaye lo ṣi n fidimulẹ nibẹ.

Lọdun 1981, ajọ UNESCO tọka si ilu naa gẹgẹbi eyi to ni aaye kan to ni ohun ini iṣẹmbaye ti gbogbo agbaye n wari fun.
Awọn opopona to w ani ilu Fes el Bali ti le ni ẹgbẹrun ọdun, bẹẹni awọn isọ ọja to wa nibẹ pe awọn arinrinajo afẹ to le ni miliọnu kan abọ wọ ibẹ lọdun 2023 nikan, ti ireti si tun wa pe eyi yoo ju bẹẹ lọ lọdun 2025



