Àwọn ajínigbé tún kọlu iléèjọsìn nítòsí Owo ní ìpínlẹ̀ Ondo, jí ènìyàn mẹ́fa gbé; laráàlú bá yarí, fẹ̀hónúhàn

Aworan ile ijọsin ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Oríṣun àwòrán, Eniola Olurankise

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn Ajinigbe tun ti ji eniyan mẹfa gbe lọ, lẹyin ti awọn agbebọn sekọlu si ile ijọsin n'ilu Uso nijọba ibilẹ Ọwọ nipinlẹ Ondo.

Ọkan lara awọn olugbe ilu naa to ba BBC YORUBA sọrọ sọ di mimọ pe ijọ Celestial Church of Christ to wa ni opopona marose ilu Akure si ilu Ọwọ ni iṣẹlẹ naa ti waye.

O salaye pe awọn ajinigbe naa sekọlu yi lasiko ti awọn olujọsin wá ni ile ijọsin ni ọjọ Isẹgun, ọjọ kerinlelogun oṣu keji ọdun yi.

Olugbe ilu naa sọ pe ọkan lara awọn ti wọn jigbe, ti moribọ lọwọ awọn ajinigbe naa, sugbọn wọn ko mọ ohunkohun nipa awọn to ku ti wọn jigbe.

Kí ni àwọn ará ìlú ṣe lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà?

Ọrọ ijinigbe nipinlẹ Ondo ti di tọrọ fọnkale, bi awọn ajinigbe ṣe ń sekọlu leralera, eyi to mu ki awọn eniyan maa gbe pẹlu ibẹru bojo.

Laipẹ yi ni awọn ajinigbe sẹkupa Alagamo tilu Agamo, Ọba Kehinde Falodun, bẹẹni wọn tun gbe tọkọ taya kan n'ilu Abo ni ọsẹ to kọja.

Eyi lo mu ki awọn olugbe ilu Uso nijọba ibilẹ Ọwọ gbe igi di opopona marose ilu Akure si ilu Ọwọ nitori iṣẹlẹ ijinigbe to waye ni ilu naa.

Awọn araalu naa lo gbe paali dani pẹlu oniruru ọrọ ti wọn kọ si, lati fehonu han nípa iṣẹlẹ ijinigbe naa.

Wọn salaye pe ijọba Ipinlẹ Ondo kawọ gbera nipa iṣẹlẹ ijinigbe, idi niyẹn ti awọn agbebọn naa fi n sọsẹ lojojumọ.

Wọn salaye pe awọn ko ni kuro ni oriko naa titi ti ijọba yoo fi sawari awọn ti wọn jigbe naa.

Opopona naa ti di pa bayi, bi awọn arin rin ajo ṣe ha si opopona naa nitori ifehonuhan to n lọ lọwọ.

Kí ní Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Ondo ti fi idi rẹ mulẹ pe eniyan mẹfa ni awọn ajinigbe naa ji gbe lọ nibi ikọlu ti wọn se si ile ijọsin n'ilu Uso.

Jimoh Abayomi salaye pe deedee ago kan ku isẹju mẹwa ni owurọ ọjọ Isẹgun, ọjọ karundinlọgbọn oṣu yi ni awọn ajinigbe naa ṣekọlu si ile ijọsin Celestial Church to wa ni opopona marosẹ Akure silu Ọwọ n'ilu Uso.

O salaye pe ni kete ti wọn gbọ iṣẹlẹ naa, awọn ikọ ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn ọmọ ogun orileede yii, pẹlu awọn figilante fọwọsowọpọ lati sawari awọn ti wọn jigbe naa.

Abayomi sọ pe ifọwọsowọpọ yi so eso rere bi wọn ṣe doola ẹmi ọkan lara awọn ti wọn jigbe naa. Ó salaye pe ọwọ tun tẹ ọkan lara awọn Ajinigbe ọun to si ti jẹwọ ipa to ko ninu iṣẹlẹ naa.

Agbẹnusọ naa seleri pe awọn esọ alaabo yoo ri daju pe wọn doola ẹmi awọn ti wọn jigbe naa, ti wọn yoo si fi panpẹ ọba mu awọn Ajinigbe naa.

O wa rọ awọn ara ilu lati fi ọkan balẹ, kí wọn si ma fọwọsowọpọ pẹlu awọn esọ alaabo ki alaafia le jọba ní aarin ilu