Wo àwọn ọbẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá mẹ́wàá tí o kò mọ̀ àti bí o ṣe le sè wọ́n

Awọn obinrin to n se ẹfọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Faoziyah Saanu-Olomoda
    • Role, Journalist
    • Reporting from, Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ìran Yorùbá gbàgbọ́ pé oúnjẹ lọ̀rẹ́ àwọ̀ àti pé okun inú ni a fi máa ń gbé tìta.

Èyí sì máa ń ṣe atọ́nà irú àwọn oúnjẹ àti ọbẹ̀ tí Yorùbá máa ń tì bọ ẹnu.

Àmọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní ìpìlẹ̀, tí ìran Yorùbá kò sí ní ojú kan náà, tí Ọ̀yọ́ wà lápá kan, táwọn Ẹ̀gbá, Ekiti, Ìlàjẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ wà lápá míì, bẹ́ẹ̀ náà ni oúnjẹ àti ọbẹ̀ tí oníkálukú wọ́n fẹ́ràn kò kọja wọn.

Àgbègbè kọ̀ọ̀kan ní ilẹ̀ Yorùbá ló ní oúnjẹ àti ọbẹ̀ tí wọ́n máa ń jẹ́.

Lára àwọn ọbẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá tó gbajúmọ̀ ni ẹ̀fọ́ ṣọkọ, ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀, ilá alásèpọ̀, ẹ̀gúsí Ìjẹ̀bú, ewédú àti gbẹ̀gìrì.

Yàtọ̀ sí àwọn ọbẹ̀ tí a kà yìí, ọ̀pọ̀ ọbẹ̀ ló wà tó jẹ́ ti ìran Yorùbá tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn kò mọ̀ nípa rẹ̀.

Èyí ló máa ń mú àwọn èèyàn máa ń rò ó pé Yorùbá kò ní àwọn ọbẹ̀ dàbí alárà nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ọbẹ̀ tó ṣe àǹfàní fún ara, tó sì ládùn ni ọmọ Yorùbá míì gan kò gbọ́ rí.

Nínú iṣẹ́ yìí ni a ó ti máa ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọbẹ̀ tó jẹ́ ìran Yorùbá tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò gbọ́ rí.

Ègbo

Ọ̀kan lára àwọn oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀ tàbí tí a lè sọ pé a kìí fi bẹ́ẹ̀ rí mọ́ láàárín ìgboro ni Egbo jẹ́.

Àgbàdo ni wọ́n fi máa ń se ègbo. Wọ́n máa rẹ àgbàdo sínú omi kó le tètè rọ̀, lẹ́yìn náà ni wọ́n máa sè é títí tó máa fi fọ́.

Àwọn míì máa ń fi òróró àti ẹ̀wà jẹ ẹ́, táwọn míì sì máa ń dín ata si.

Ojojo

Iṣu ewùrà ni wọ́n fi máa ń ṣe ọ̀jọ̀jọ̀. A máa rin iṣu ewùrà tí wọ́n sì máa pò ó papọ̀ pẹ̀lú ata rodo àti àlùbọ́sà.

Lẹ́yìn náà ni wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ sí ní da sínú òróró gbóná títí tó mfi máa dín gbẹ.

Kò sí nǹkan tí wọn kìí fi ọ̀jọ̀jọ̀ jẹ yálà ẹ̀kọ tútù, gààrí tàbí kí èèyàn jẹ́ lásán.

Márúgbó

Ewé Marugbo àti ọbẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn í wọ́n sè é tán

Oríṣun àwòrán, Waasere/Instagram

Ọbẹ̀ yìí kàn náà ni àwọn ẹ̀yà Yorùbá kan máa ń pè ní gbánúnù.

Ọbẹ̀ tó máa ń ṣe ara lóore gidi ni nítorí ewé rẹ̀ ní àǹfàání púpọ̀ tó máa ń ṣe fún ara.

Látara àǹfàání tí ó ń ṣe fún ara ni ewé náà ti mú orúkọ Márúgbó. Àpèjá orúkọ rẹ̀ gan ni A-mú-arúgbó-ta-kébé.

Láàárín àwọn ènìyàn ilẹ̀ Okitipupa àti Ilaje ní ìpínlẹ̀ Ondo ni ọbẹ̀ yìí pọ̀ sí.

Ewé Márúgbó yìí ni èèyàn máa lọ kúná, tí èèyàn yóò sì sè é papọ̀ pẹ̀lú ẹran tàbí ẹja láti fi gbé òkèlè sínú ikùn.

Ìlasa

Ọbẹ̀ Ilasa

Oríṣun àwòrán, Waasere/Instagram

Ilá jẹ́ ọbẹ̀ tó gbajúmọ̀ láàárín ẹ̀yà káàkiri Nàìjíríà, kìí ṣe Yorùbá nìkan ló máa ń jẹ ilá.

Àmọ́ láti ara ilá yìí, àwọn ọbẹ̀ míì wà tí kò gbajúmọ̀ tó sì jẹ́ ọbẹ̀ tí Yorùbá fẹ́ràn láti máa jẹ, tó sì máa ń ṣe ara lóore.

Ọ̀kan lára àwọn ọbẹ̀ yìí ni Ìlasa. Ewé ilá ni Ìlasa, tí wọ́n sì máa ń gé sí wẹ́wẹ́ bíi ewédú.

Láàárín àwọn ènpiyàn ìlú Igbo-Ora àti Ibarapa ní ìpínlẹ̀ Oyo ni ọbẹ̀ yìí ti gbajúmọ̀.

Èèyàn le se Ìlasa ní ọbẹ̀ alásèpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ilá, tí òun náà sì máa ń yọ̀ bíi ilá.

Kò sí òkèlè tí èèyàn kò lè fi ọbẹ̀ Ìlasa jẹ yálà àmàlà, ẹ̀bà, semo, fùfú tàbí iyán.

Ọ̀rúnlá

Orunla

Oríṣun àwòrán, Waasere/Instagram

Ọ̀kan lára àwọn ọbẹ̀ tí èèyàn le rí lára ilá náà ni ọ̀rúnlá.

Tí a bá fẹ́ ṣe ọ̀rúnlá, a máa gé ilá sí wẹ́wẹ́, tí a ó sì sa kó fi gbẹ́.

Lẹ́yìn tó bá gbẹ tán ni a máa lọ̀ ọ́ di lúbúlúbú, tí èèyàn yóò sì máa bù ú sè díẹ̀ díẹ̀

Ó lè lo oṣù mẹ́fà sí ọdún kan nílé lai bàjẹ́.

Òhun náà ṣe é sè ní alásèpọ̀ tàbí kí ẹ sè é lásán kí a bù omi ọbẹ̀ lé e lórí láti fi gbé òkèlè sọ́hùn-ún.

Ìṣápá

Isapa

Oríṣun àwòrán, Waasere/Instagram

Ìṣápá toro mọ́yán.

Ìṣápá fi ara jọ ilá àmọ́ kìí ṣe ilá, kódà kìí ṣe ọbẹ̀ tó máa ń yọ̀ rárá.

Láàárín àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ekiti àti Ondo ni ọbẹ̀ yìí pọ̀ sí nítorí iyán ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ fẹ́ràn láti máa fi ọbẹ̀ yìí jẹ.

A lè se Ìṣápá pẹ̀lú ẹ̀gúsí tàbí kí èèyàn sè é lásán.

Kò sí oúnjẹ tí èèyàn kò lè fi Ìṣápá jẹ kódà tó fi mọ́ Ìrẹsì.

Ẹ̀fọ́ Amúnútutù

Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ amúnútutù

Oríṣun àwòrán, Waasere/Instagram

Ẹ̀fọ́ Amúnútutù náà wà lára àwọn ẹ̀fọ́ tí èèyàn le lò láti fi se ẹ̀fọ́ rírò yàtọ̀ sí ṣọkọ tàbí tẹ̀tẹ̀.

Bákan náà ni èèyàn le sè é pẹ̀lú ẹ̀gúsí gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn ojúgbà rẹ̀.

Ẹkù

Ewe ẹku

Oríṣun àwòrán, Waasere/Instagram

Ẹkù jẹ́ ọbẹ̀ tó máa ń yọ̀, tó sì farajọ ewédú kódà ní àwọn èèyàn ìlú Ilorin fẹ́ràn láti máa se ewédú àti ẹkù papọ̀.

Ẹkù jẹ́ ọbẹ̀ tó máa ń yọ̀ gidi tó sì pọ̀ púpọ̀ ní àwọn agbègbè Oyo, Iseyin àti Oke Ogun.

Ọbẹ̀ Ẹkù ṣe é sè ní tútù bíi ewédú tàbí kí èèyàn sè é ní gbígbẹ. Èyí túmọ̀ sí pé èèyàn máa sá Ẹkù títí tí yóò fi gbẹ.

Lẹ́yìn tí ó bá gbẹ tán ni a máa fi ọwọ́ rún-un tó máa fi dàbí lúbúlúbú.

Kò sí oúnjẹ òkèlè tí èèyàn kò lè fi Ẹkù jẹ.

Elegede

Ọbẹ̀ Elegede

Oríṣun àwòrán, Waasere/Instagram

Elegede jẹ́ ewé èso kan tó farajọ ẹ̀gúsí.

Elegede ni á máa ń sè bí àwọn ẹ̀fọ́ yòókù tí a sì máa ń se èso rẹ̀ bíi ti ẹ̀gúsí.

Bokolisa

Eso ati ọbẹ Bokolisa

Oríṣun àwòrán, Waasere/Instagram

Ọbẹ̀ yìí wọ́pọ̀ láàárín àwọn Ìkálẹ̀, Ìlàjẹ àtàwọn Ìjẹ̀bú.

Látara èso Bokolisa ni a ti máa ń yọ ọbẹ̀ yìí.

Èso yìí ni èèyàn máa lọ kúná. Tí èèyàn bá lọ èso yìí tán, ó máa ń fara jọ ogbono kódà sísè rẹ̀ náà fara jọ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe ogbono.

Ọbẹ̀ tó máa ń yọ̀ náà ni Bokolisa tí èèyàn sì lè fi jẹ oríṣiríṣi òkèlè.

Olú

Aworan olu ọran ati olu ogogo

Oríṣun àwòrán, Waasere/Instagram

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo olú kọ́ ni ó ṣe é jẹ́ àmọ́ àwọn olú kan wà tí Yorùbá máa ń jẹ.

Lára rẹ̀ ni olú ògògó àti olú ọrán.

A lè se àwọn olú yìí pẹ̀lú ẹ̀gúsí tí a lè fi jẹ òkèlè.

Wọ̀rọ̀wọ́

Ẹfọ Wọrọwọ

Oríṣun àwòrán, Waasere/Instagram

Ọbẹ̀ wọ̀rọ̀wọ́ wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn ìlú Iwo ní ìpínlẹ̀ Osun, bẹ́ẹ̀ náà ló sì wà ní ìpínlẹ̀ Ekiti.

Lásìkò tí iṣu tuntun bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde ní ẹ̀fọ́ yìí máa ń pọ̀.

Bí a ṣe máa ń se àwọn ẹ̀fọ́ rírò náà ni a máa ń se Wọ̀rọ̀wọ́.

Tí a bá ní kí a máa kà á, a ò le ka ọbẹ̀ Yoruba tán nítorí a ṣì ní àwọn ọbẹ̀ bíi ẹ̀fọ́ òdú, osungbagba, yánrin, ebòlò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.