Wo àwọn àǹfààní tí kárọ́ọ̀tì ń ṣe fún àgọ́ ara rẹ

Àwòrán àwọn kárọ́ọ̀tì tó wà lórí tábìlì

Oríṣun àwòrán, Alexander Spatari via Getty Images

    • Author, Abubakar Maccido
    • Role, Reporter
    • Reporting from, Kano
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀fọ́ tí àwọn èèyàn fẹ́rà láti máa jẹ púpọ̀ ni kárọ́ọ̀tì jẹ́ nítorí adùn rẹ̀.

Àwọn mìíràn fẹ́ràn rẹ̀ nítorí bí ó ṣe máa ń dún korankoran tí èèyàn bá ń jẹ ẹ́ lẹ́nu, tó sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èròjà aṣaralóore.

Kárọ̀ọ̀tì tó jẹ́ ẹ̀yà ẹbí ẹ̀fọ́ Apiaceae, ló ní àwọ̀ omi ọsàn.

Èèyàn le jẹ kárọ́ọ̀tì ní tútù tàbí kí èèyàn sínú oúnjẹ. Ó ṣe é yan tàbí kí èèyàn lọ̀ ọ́ papọ̀ mọ́ àwọn èso míì gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa oúnjẹ ní ìpínlẹ̀ Kano, Abdulsalam Bichi ṣe sọ.

Ó ṣàlàyé pé kárọ́ọ̀tì ní èròjà aṣaralóore Vitamin A, C, K, àti Biotin (B7) èyí tó máa ń mú kí ara jọ̀lọ̀, tó sì máa ń jẹ́ kí irun gùn púpọ̀.

Àwọn àǹfàní ìlera tó wà nínú kárọ́ọ̀tì

Kárọ́ọ̀tì ní èròjà Beta-Carotene: Tí èèyàn bá jẹ kárọ́ọ̀tì, ara máa ń yi padà sí Vitamin A èyí tó máa ń ṣe ìrànwọ́ fún ojú, àwọ̀ ara àti àwọn èròjà inú ara tó máa ń mú ara jí pépé.

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ antioxidants: Antioxidants jẹ́ àwọn kẹ́míkà tó máa ń wà nínú oúnjẹ tó máa ń dá ààbò bo àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara láti má bàjẹ́. Kárọ́ọ̀tì ní carotenoids, lutein àti polyphenols tí kìí jẹ́ kí èèyàn máa ṣe àárẹ̀, tí kìí jẹ́ kí èèyàn tètè gbó.

Ó máa ń ṣe ìrànwọ́ fún kí oúnjẹ tètè dà bó ṣe yẹ. Carrot ní èròjà fiber èyí tó máa ń ṣe ìrànwọ́ fún àwọn oúnjẹ tí kò bá tètè dà lára. Ó máa ń fọ ẹ̀yà ara tó máa ń jẹ́ kí oúnjẹ dà , tí kò sì ní jẹ́ kí inú le tandi.

Ó dára fún ọkàn: Kárọ́ọ̀tì máa ń ṣe ìrànwọ́ fún yíyọ àwọn ọ̀rá tí kò da lára, tó sì máa ń ṣe àmójútó bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń tọra nítorí èròjà fiber, potassium àti carotenoids tó ní. Gbogbo àwọn nǹkan yìí máa ń jẹ́ kí ọkàn jí pépé si.

Kárọ́ọ̀tì dára fún àwọ̀ ara àti irun pẹ̀lú èròjà tó ń mú kí ara jọ̀lọ̀

Ó le mú àdínkú níní àìsàn jẹjẹrẹ: Lára àwọn èròjà tí kárọ́ọ̀tì ní ni falcarinol èyí tó le ṣe ìdádúró àìsàn jẹjẹrẹ lára.

Ó le mójútó ṣúgà ara: Kárọ́ọ̀tì ní èròjà glycemic index tó kéré jọjọ. Èyí ni kìí jẹ́ kó le pèsè ṣúgà púpọ̀ fún ara. Fiber tó wà nínú rẹ̀ náà máa ń ṣèrànwọ́ láti mójútó ṣúgà ara pàápàá fún àwọn tó bá ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà.

Ó dára fún àwọ̀ ara àti irun: Kárọ́ọ̀tì ní èròjà aṣaralóore Vitamin A, C, K, àti Biotin (B7) èyí tó máa ń mú kí ara jọ̀lọ̀, tó sì máa ń jẹ́ kí irun gùn púpọ̀

E good for skin and hair: Carrot get Vitamin A, C, K, and Biotin (B7) wey dey make skin smooth, reduce pimples, help hair grow strong, and make e shine.

Àwọn èròjà aṣaralóore tó wà nínú kárọ́ọ̀tì tí ìwọ̀n rẹ̀ bá jẹ́ gíráàmù ọgọ́rùn-ún

  • Calories: 41 kcal
  • Omi: 89–90%
  • Protein: 0.8–0.9 g
  • Fat: 0.1–0.2 g
  • Carbohydrates: 9.0 g
  • Dietary Fiber: 2.7 g

Àwọn ìdàkejì tí jíjẹ kárọ́ọ̀tì le mú bá èèyàn

  • Carotenemia: Àwọ̀ ara le yípadà sí pípọ́n tí èèyàn bá jẹ kárọ́ọ̀tì jù àmọ́ kò ní pẹ́ tí àwọ̀ náà fi máa padà sípò.
  • Ara le máa yún ẹlòmíì lẹ́yìn tí wọ́n bá jẹ kárọ́ọ̀tì tán tàbí kí ibìkan lára wọn wú.
  • Ṣé ìdíwọ́ fún bí oúnjẹ ṣe ń dà lára nítorí àpọ̀jù fiber le jẹ́ kí inú èèyàn ga tàbí le lọ́nà òdì.
  • Tí èèyàn bá ń mu omi kárọ́ọ̀tì nìkan láì jẹ àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ le mú kí ṣúgà ara lọ sókè

Àwọn onímọ̀ so pé ó dára láti máa jẹ kárọ́ọ̀tì kan sí méjì lójúmọ́.