Àjọ CAF yí ìdíje AFCON padà sí ọdún mẹ́rin-mẹ́rin dípò méjì tó máa ń wáyé tẹ́lẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n ri si ere bọọlu alafẹsẹgba nilẹ Africa, Confederation of African Football (CAF), ti kede pe idije ere bọọlu ilẹ Africa (AFCON) to maa n waye lọdun meji-meji tẹlẹ yoo yipada si ọdun mẹrin-mẹrin lẹyin eyi to ba waye ni 2028.
Aarẹ CAF, Patrice Motsepe, lo kede ọrọ yii lọjọ Abamẹta, ogunjọ oṣu Kejila ọdun 2025, ni Rabat, lorilẹede Morocco ti idije odun yii yoo ti maa waye.
Aarẹ CAF ṣalaye pe ayipada yii ṣe pataki, nitori yoo jẹ ki idije naa jẹ ọkan lara awọn ti onka rẹ yoo ba ohun to n lọ latẹ agbaye mu.
Gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ tẹlẹ, AFCON ti yoo bẹrẹ lonii ode yii ni Morocco, jẹ idije ọlọdun meji-meji.
Bakan naa lo si jẹ ọna kan gboogi fun awọn orilẹede to ba kopa lati pawo wọle.
Ṣugbọn Aarẹ CAF, Patrice Motsepe, sọ pe idije tuntun fun ilẹ Africa ( African Nations League competition) to farapẹ idije UEFA, ni yoo rọpo rẹ ti yoo si tun apo awọn orilẹede akopa ṣe daadaa.
"Lẹ́yìn ìdíje ife ẹ̀yẹ FIFA ní 2029, ìdíje African Nations League yóò wáyé''
Nigba to n tẹsiwaju ninu alaye rẹ, Aarẹ CAF sọ pe :
"Ohun ti a dojukọ lọwọ yii ni AFCON, ṣugbọn to ba di 2027, a maa lọ si Tanzania, Kenya ati Uganda, idije AFCON ti yoo si waye lẹyin iyẹn yoo jẹ 2028.
"Ti a ba ti wa kopa ninu idije agbaye ti i ṣe FIFA Club World Cup ni 2029, lẹyin naa ni a maa ṣe idije akọkọ fun ikọ ilẹ Africa (First African Nations League), eyi ti owo amurele rẹ yoo pọ si i, ti ajẹmọnu rẹ yoo lekun, ti ifigagba rẹ yoo si tun lagbara si i.
" Lara eto yii naa ni ipinnu pe idije AFCON yoo maa waye ni ẹkan ṣoṣo bayii ninu ọdun mẹrin."
Bẹẹ ni Patrice Motsepe ṣalaye ayipada tuntun naa.
Ṣaaju lo ti jẹ pe ọdun meji-meji ni AFCON maa n waye, ilana naa ko yi pada lati ọdun 1957 ti wọn ti bẹrẹ rẹ.
Ṣugbọn lati nnkan bii ọdun mẹẹẹdogun sẹyin ni awọn eleto rẹ ti n wa ọna ti wọn yoo gba, ti idije naa yoo fi maa ba ti atẹ agbaye mu, ki wọn too kede rẹ bayii.














