Amẹ́ríkà fòfin de ètò tẹ́tẹ́ oríire físà pẹ̀lú ìwé ìgbélùú

Àwòrán ìwé ìgbélùú ní Amẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ti gbẹ́sẹ̀lé fífún àwọn èèyàn tó bá jẹ́ "visa lottery" ní ìwé ọmọ ìgbélùú "green card" mọ́.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìyìnbọnpani wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Brown University níbi tí èèyàn méjì ti pàdánù ẹ̀mí wọn.

Àwọn aláṣẹ Amẹ́ríkà sọ pé wọ́n ṣàwárí òkú afurasí tó pa àwọn èèyàn náà, ẹni tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Portugal, ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kejìlá, ọdún 2025.

Ní ọdún 2017 ni afurasí náà wọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà pẹ̀lú ètò Diversity Lottery Immigrant Visa Programme (DV1), tí wọ́n sì fun ní ìwé ọmọ ìgbélùú, green card.

Akọ̀wé Homeland Security Kristi Neom sọ pé àwọn ti ṣe ìdádúró ètò náà báyìí fún ìgbà kan ná lábẹ́ ìdarí Ààrẹ Trump lójúnà àti ṣe àrídájú rẹ̀ pé ọmọ Amẹ́ríkà kò kojú irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ mọ́ nítorí ètò kan.

Àwọn aláṣẹ ní Amẹ́ríkà gbàgbọ́ pé afurasí náà, ẹni ọdún méjìdínláàádọ́ta Claudio Neves Valente tún ṣekúpa ara Portugal kan ní ilé ẹ̀kọ́ Massachusetts Institute of Technology, Ọ̀jọ́gbọ́n Nuno Loureiro ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ yìí.

Kí ló dé tí Amẹ́ríkà ṣe ìdádúró ètò náà?

Ààrẹ Donald Trump pàṣẹ pé kí Akọ̀wé Homeland Security Kristi Noem láti fòfin de ètò náà fún ìgbà kan ná lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí àwọn ọlọ́pàá ṣàwárí òkú Neves Valente níbi ilé tí wọ́n ń kó nǹkan pamọ́ sí ní Salem, New Hamsphire.

Àwọn ọlọ́pàá gbàgbọ́ pé afurasí náà ló yìnbọn pa ara rẹ̀.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ẹ̀rí fídíò wà tó ṣàfihàn pé afruasí ọ̀hún lọ yá ọkọ̀ ní ibi tí wọ́n ti máa ń yá ọkọ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ sì jọ ẹni tí wọ́n ń wá lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́tà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwádìí tó gbòòrò lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Wọ́n bá ohun ìjà méjì lọ́wọ́ rẹ̀ níbi tí wọ́n ti bá òkú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò àgbà Rhode Island, Peter Neronha ṣe sọ , ẹ̀rí tí wọ́n rí níbi ọkọ̀ tó wà nínú ọkọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí wọ́n ti ṣàwárí òkú rẹ̀ àti ibi tí wọ́n ti yìnbọn ba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Brown University.

Ààrẹ Brown University, Christina Paxson ní Neves Valente forúkọ sílẹ̀ fún ètò Ivy League ní ọdún 2000 tó sì kẹ́kọ̀ọ́ láti gboyè ọ̀mọ̀wé nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Physics.

Ó sọ pé Valente kò ní àjọṣepọ̀ kankan pẹ̀lú ilé ẹ̀kọ́ Brown báyìí.

Àwọn aláṣẹ ní àwọn gbàgbọ́ pé Veves Valente yìbọn pa Ọ̀jọ̀gbọ́n Nuno F Gomes Loureiro, ẹni ọdún mẹ́atàdínláàádọ́ta ní ilé rẹ̀ tó wà ní Brookline lọ́jọ́ Ajé, níbi tó jẹ́ àádọ́ta máìlì sí Providence.

Kí ni ètò Diversity Immigrant Visa Program?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ọdọọdún ni ìjọba Amẹ́ríkà máa ń pèsè ètò ẹgbẹ̀rún àádọ́ta físà fáwọn orílẹ̀ èdè tí èèyàn wọn kìí sábà kó lọ sí Amẹ́ríkà.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1990 ni wọ́n gbé ètò náà kalẹ̀, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa ń fi ètò náà bèèrè fún físà Amẹ́ríkà.

Láti lè jẹ físà náà, èèyàn gbọdọ̀ ní ìwé ẹ̀rí ilé ẹ̀kọ́ mẹ́wàá tàbí kó ní ìrírí ọdún méjì lẹ́nu iṣẹ́ tó bá fẹ́ lọ kẹ́kọ̀ọ́ lé lórí. Bákan náà ló pọn dandan fún wọn láti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kí wọ́n tó le rí físà náà gbà.

Ilé aṣòfin ló ṣe àgbékalẹ̀ ètò náà, ọ̀nà tí Noem yóò gbà láti ṣe ìdádúró ètò náà lábẹ́ òfin kò ì tíì yéni.

Iléeṣẹ́ US State Department ló máa ń ṣe àmójútó ọ̀pọ̀ àwọn físà tí wọ́n máa ń fún àwọn èèyàn lábẹ́ ètò lottery bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iléeṣẹ́ US Citizenship àti iléeṣẹ́ Immigration Services máa ń ṣe àkóso àwọn míì.

Láti ọjọ́ pípẹ́ ni Trump ti máa ń bu ẹnu àtẹ́ lu ètò náà. Ó gbìyànjú láti fòpin si nígbà sáà rẹ̀ àkọ́kọ́ látàrí bí ọkùnrin kan tó fi físà lottery wọ Amẹ́ríkà ṣe ní ìjàmbá ọkọ̀ tí sì ṣekúpa èèyàn mẹ́jọ ní New York.

Àwọn tó jẹ́ alátìlẹyìn ètò náà sọ pé àwọn máa ń ṣe àyẹ̀wò àwọn tí wọ́n ń fún ní físà náà dáadáa àti pé ètò náà dára fún ọrọ̀ jé Amẹ́ríkà àti pé ó máa jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé yòókù rí Amẹ́ríkà dáadáa.

Trump ṣe ìdádúró ètò náà nígbà sáà àkọ́kọ́ rẹ̀ lọ́dún 2020.

Kí ni ìwé ìgbélùú 'green card'?

Ìwé ìgbélùú 'green card' máa ń fún àwọn èèyàn tí wọ́n bá wọ Amẹ́ríkà láti orílẹ̀ èdè mìíràn ní àǹfàní láti bèèrè fún ìwé ọmọ onílùú.

Láàárín ọdún kan, wọ́n máa ń fún àwọ èèyàn ní ìwé ìgbélùú tó tó mílíọ̀nù kan ní Amẹ́ríkà.

Ìjábọ̀ ilé aṣòfin US kan lọ́dún 2018 sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń wọ Amẹ́ríkà ló jẹ́ pé ọ̀dọ̀ ẹbí àti ará wọn tó ń gbé ní US ni wọ́n máa ń lọ.

Fún ti ìwé ìgbélùú tó ní ṣe pẹ̀lú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, àwọn èèyàn tó ti ń gbé ní orílẹ̀ èdè náà tó fẹ́ pààrọ̀ ètò ìgbélùú wọn ló sábà máa ń gba ìyẹn jù.