"Orin Kèǹgbè jẹ́ orin àwa Fúlàní, àwọn Yorùbá kò mọ iyì rẹ̀"
Yoruba ni idalu ni iselu, asa ilu kan si yatọ si ilu miran bi o tilẹ jẹ pe wọn lee ma sọ ede kan naa.
Ta ba n sọrọ nipa orin ti a da mọ pẹlu awn eeyan ilu kan, ilẹ Ibadan lo ni Dundun ati Sẹkẹrẹ nigba ti agbegbe Ẹgba ati Yewa lo ni Bọlọjọ .
Ni ilu Ilorin, orin Kengbe gbajumọ, paapaa laarin awọn obinrin, ti ijo rẹ si wa fun takọ tabo.
Orin ati ijo Kengbe jẹ ara ayẹyẹ to maa n waye lasiko eto igbeyawo, to si jẹ aṣa adayeba nilu Ilorin, tii se olu ilu ipinlẹ Kwara.

Asa yii ti gbilẹ lati onka ẹgbẹrun meji ọdun sẹyin, to si jẹ itẹwọgba gidi laaring gbogbo ẹya ati eeyan to wa nipinlẹ Kwara.
Ede Yoruba ni wọn maa fi n kọ orin Kengbe bi o tilẹ jẹ pe inu ẹya Fulani ni orin naa ti wa.
BBC Yoruba de ilu Ilorin lati ba awọn eeyan to n kọ orin Kengbe sọrọ lati mọ pataki orin ọhun ninu asa ati ise wọn.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, asaaju ẹgbẹ awọn obinrin to n kọ orin Kengbe salaye pe orin lile ni orin Kengbe.
O ni ẹnikan yoo le e, ẹlomiran yoo gbe e.

Asaaju awọn akọrin Kengbe naa ni "A ba lọwọ awọn to bi wa, orin Funlani ni, ti a maa n kọ fun iyawo ọsigin.
Iyatọ orin Kengbe ni pe a maa n ki oriki iywao ninu rẹ, ti a si tun gba niyanju lati mase igberaga, ko ni iwa irẹlẹ, ko si maa bọwọ fawọn eeyan ọkọ rẹ.
Obinrin kekere ati agba lo n kọ orin Kengbe amọ awọn ẹya Yoruba ko lu orin Kengbe mọ tori wn ko mọ iyi rẹ.
Lati kekere ni awa obinrin Fulani ti n kọ orin Kengbe amọ o ti n lọ sokun igbagbe laarin awọn kekeke.
A kii beere pe iye owo kan la fẹ gba ka to kọrin Kengbe, iye ti onikaluku ba fẹ, lo lee fun wa.
Yatọ si awa Fulani, bi ẹni ti ko se Fulani naa ba bẹ wa lode, a maa n lọ sibẹ lati kọrin Kengbe."






