Wo àwọn ọmọ Naijiria mẹ́fà tí ile-ẹjọ́ ti dájọ́ ikú fún

Aworan Ramon Adedoyin ati awọn to pa Hanifa Abubakar

Oríṣun àwòrán, Ramon Adedoyin/ Facebook/ Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Idajọ iku ki i deede waye, abala kẹtalelọgbọn ofin Naijiria lo faaye gba a, pe ki kootu dajọ iku fun ẹnikẹni to ba jẹbi iku.

Ijiya ti ofin fọwọ si ni idajọ iku jẹ, nigba ti eeyan ba si daran to jẹ mọ ipaniyan, iditẹgbajọba tabi idigunjale ni idajọ iku maa n waye.

Lẹyin ti kootu ba ti dajọ iku fun eeyan tan, ohun to ku ni ki gomina ipinlẹ naa buwọ lu iwe idajọ iku naa.

Ṣugbọn ni Naijiria lonii, ọpọ idajọ iku ni kootu ti paṣẹ rẹ, ṣugbọn ti awọn gomina ipinlẹ ti idajọ ti waye, ko buwọ lu idajọ naa.

Bi gomina ko ba buwọ lu iwe idajọ iku ẹni to jẹbi iku, ko sẹni kan ti yoo pa ẹni naa.

Yoo kan wa lọgba ẹwọn nibẹ ni.

Eyi lohun to n ṣẹlẹ ninu eto idajọ Naijiria.

Ọmọ Naijiria mẹ́fà to ti gba idajọ iku

Aworan Oloogbe Bamise Ayanwola ati ọkọ BRT

Oríṣun àwòrán, Bamise Ayanwola/ Facebook/ BBC

Andrew Nice Ominikoron: Awakọ BRT tileẹjọ ni oun lo pa Bamise Ayanwola lọdun 2022

Idajọ iku to ṣi n gbona lọwọ yii ni ti eyi ti kootu giga to wa ni TBS, l'Ekoo, da lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja.

Ẹyi naa ni idajọ to waye lori iku Oloogbe Bamise Ayanwola, ọmọbinrin ti awakọ BRT; Andrew Nice Ominikoron pa ni 2022.

Bamise, ẹni ọdun mejilelogun lasiko to di oloogbe, ni a gbọ pe Andrew Nice pa to si tun gbiyanju lati fipa ba a lo pọ.

Lẹyin eyi lo ju oku ọmọbinrin naa jade lati inu ọkọ BRT ọhun.

Lẹyin ọdun mẹta, Adajọ Sherifat Sonaike to gbọ ẹjọ naa, sọ pe gbogbo ẹri lo foju han, pe Andrew lo pa Bamise.

O paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun awakọ BRT naa titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.

Wọn gbe Nice lọ lọjọ naa loootọ, ṣugbọn boya iku rẹ yoo ya, boya gomina yoo tiẹ buwọ lu iwe idajọ rẹ, tabi boya oun naa yoo pe ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun ni ẹnikan o ti I le sọ.

Peter Nwachukwu: Ọkọ gbajumọ olorin ẹmi nni, Osinachi Nwachuku, gba idajọ iku lori iku aya rẹ

Peter Nwachukwu ati aya rẹ Osinachi

Oríṣun àwòrán, Peter Nwachukwu/Facebook

Ọkunrin yii ni ọkọ gbajumọ olorin ẹmi nni, Osinachi Nwachuku to di oloogbe lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin ọdun 2022.

Ọsẹ to kọja ni ile ẹjọ giga ilu Abuja to wa ni Wuse Zone 2, dajọ iku fun Ọgbẹni Nwachukwu lori iku iyawo rẹ.

Adajọ Njideka Nwosu-Iheme, ṣalaye pe Peter jẹbi iku to pa iyawo rẹ, o ni ki wọn lọọ yẹgi foun naa titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.

Ẹlẹrii mẹtadinlogun lo tako Nwachukwu ni kootu, awọn ọmọ rẹ paapaa pẹlu.

Wọn ṣalaye pe o maa n lu Oloogbe Osinachi, o ko o laya jẹ, bẹẹ naa lo si n ṣe si awọn ọmọ wọn pẹlu.

Bo tilẹ jẹ pe ayẹwo fi han pe Oloogbe ni aisan jẹjẹrẹ ọna ọfun, awọn ẹri to tọka si ọkọ rẹ bii ẹni to pa a lo pọ ju.

Nwachukwu ti gbadajọ iku bayii, bi yoo ku la wa o mọ.

Ramon Adedoyin: Eekanlu to gba idajọ iku lori iku Timothy Adegoke.

Aworan Ramon Adedoyin ati Oloogbe Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, Ramon Adedoyin/Facebook

Ramon Adedoyin, ẹni to ni otẹẹli nla kan niluu Ile -Ife, gbadajọ iku tirẹ latari iku ọkunrin akẹkọọ kan, Timothy Adegoke.

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun lo kọkọ dajọ iku fun Adedoyin, ki kootu Ko-tẹ-mi-lọrun ipinlẹ Ondo naa too ni o jẹbi iku.

Tẹ o ba gbagbe, akẹkọọ ni Oloogbe Timothy Adegoke, ni Yunifasiti Obafemi Awolowo, Ile-Ife.

Otẹẹli Adedoyin lo de si lọjọ Karun-un si Ikeje oṣu Kọkanla ọdun 2021 to fi pade iku ojiji.

Lẹyin gbogbo ẹri to foju han pe Adedoyin lọwọ ninu iku naa, ati idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun, ati ti Ko-tẹ-mi-lọrun ipinlẹ Ondo, Ramon Adedoyin ti gbadajọ iku lorilẹede Naijiria .

Abdulmalik Muhammmad Tanko: Ajinigbe to gbe Hanifa Abubakar, ọmọ ọdun marun naa, to si pa a

Aworan Oloogbe Hanifa Abubakar ati awọn to pa a

Oríṣun àwòrán, Hanifa Abubakar's family

Ọmọ ọdun marun-un pere ni Hanifa Abubakar nigba ti ẹni to ni ileewe ti ọmọ naa n lọ, Abdulmalik Muhammmad Tanko, ji i gbe to si pada pa a.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe ro o nigba naa, ọjọ kẹrin oṣu Kejila ọdun 2021 ni Hanifa dagbere faye nipinlẹ Kano.

Ọmọ naa n bọ lati ilee keu ni, nigba ti Muhammmad Tanko, Fatima Musa ati Hashim Isyaku, ji i gbe.

Tanko lo pa ọmọde yii bi iroyin ṣe wi, o si sinku rẹ sinu iho kan ti ko jin.

Aṣiri tu lẹyin iwadii ọlọpaa, Adajọ Usman Naabba, ti ipinlẹ Kano si dajọ iku fun Tanko; ẹni ọdun mejidinlogoji nigba naa, pẹlu awọn yooku rẹ.

Sunday Jackson: Agbẹ kan to gba idajọ iku tori pe o gun darandaran kan ni ọbẹ pa

Agbẹ ni Sunday Jackson, o si tun n lọ sileewe pẹlu nigba to wa lẹni ọdun mọkandinlọgbọn, ni 2015.

Inu oko rẹ lo wa lọjọ kan ni 2015, lagbegbe Dong, ipinlẹ Adamawa, nigba naa ni darandaran kan, Buba Ardo Bawuro, da maaluu wọnu oko naa lati jẹko.

Jackson tako eyi, darandaran si fa ọbẹ yọ, o gun un lẹẹmeji.

Jackson naa ko gọ, o dide pẹlu ọgbẹ ara rẹ, o si gun darandaran naa pada.

Oró ọbẹ ti Jackson gun Bawuro mu un pupọ, ọgbẹ naa lo si pada pa darandaran yii.

Ọlọpaa mu Jackson nitori eyi, wọn gbe e lọ sile ẹjọ giga Yola, wọn si fi ẹsun ipaniyan kan an.

Nigba to n jẹjọ rẹ, Jackson ni loootọ ni darandaran le ku lati ara ọgbẹ toun da si I lara, o ni ṣugbọn oun ko jẹbi ipaniyan, bi kootu tilẹ dajọ iku foun.

Adamu Mohammed: Ṣọ́jà tó pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀

Ṣọja kan, Private Adamu Mohammed naa ti gba idajọ iku nipinlẹ Enugu, fun pipa ọrẹbinrin rẹ, Omidan Hauwa Ali.

Kootu apapọ to n jokoo ni olu ileeṣẹ ologun, 82 Division, Enugu, lo paṣẹ pe ki wọn yẹgi fun Private Adamu Mohammed, fun ẹsun ipaniyan.

Atẹjade kan lati ọfiisi Ọgagu Jonah Unuakhalu, to n ri si ikede ni kọmandi naa, ṣalaye pe igbimọ ẹlẹni mọkanla tawọn gbe kalẹ lati wadii iku naa lọjọ kejindinlogun, oṣu Keji ọdun 2025, faaye gba awọn lati gbọ ẹjọ awọn ṣọja to ba tasẹ agẹẹrẹ.

Ninu idajọ rẹ, Brigadier General Sadisu Buhari, sọ pe awọn ri i pe Adamu jẹbi iku to pa Omidan Hauwa, o si jẹbi iku labẹ ofin '106(a) Act, Cap A20', ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 2004.