Jàndùkú pa obìnrin kan àti gbogbo ọmọ rẹ̀ mẹ́fà nínú ilé wọn ní Kano

Awọn agbebọn ti ṣekupa obinrin ẹni ọdun marundinlogji kan atawọn ọmọ rẹ mẹfa nipinlẹ Kano.
Ọlọpaa sọ pe agbegbe Dorayi Chiranchi, niluu Kano ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Iroyin ni ṣadede lawọn januduku dede ya wọ ile Fatima Abubakar pẹlu oniruru ohun ija oloro lọwọ wọn ti wọn si ṣekupa oun atawọ ọmọ rẹ mẹfa.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, CSP Abdullahi Kiyawa, fi lede, o ni nnkan bii aago mejila kọja iṣẹju mẹwaa ọsan ana ọjọ Abamẹta lawọn gba ipe pajawiri nipa iṣẹlẹ naa.
O ni kete lẹyin ipe naa lawọn akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa lọ sibẹ ti wọn si ko awọn eeyan naa lọ sile iwosan Murtala Mohammed to wa niluu Kano nibi ti awọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe wọn ti jade laye.
Ọlọpaa ni "A ko wọn lọ sile iwosan, nibẹ ni wọn ti fidi rẹ mulẹ pe gbogbo wọn ti ku."
O fi kun pe kọmiṣọna ọlọpaa ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ iwadii to peye lati mọ kulẹ kulẹ ikọlu naa si mọlẹbi ọhun, ki wọn tun fi ṣikun ofin mu gbogbo awọn to lọwọ ninu rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa tun ba mọlẹbi ọhun kẹdun ikọlu naa, to fi mọ awọn eeyan agbegbe Dorayi Chiranchi pẹlu ileri pe idajọ ododo yoo waye lori ikọlu mọlẹbi naa.
Wayi o, ikọlu naa ti sọ pupọ ninu awọn olugbe agbegbe naa sinu ipaya bayii, wọn si ti ke si ijọba ko maṣe dakẹ lori igbiyanju rẹ lori eto eebo ipinlẹ naa.
Ti ẹ ko ba gbegbe, ni ipinlẹ Kano yii kan naa lawọn janduku ti gun ọkunrin kan, Abdurrauf Sheriff, pa laipẹ yii.
Ajọ abo ara ẹni laabo ilu, NSCDC ni oloogbe naa n ṣiṣẹ fun saaju iku rẹ.














