Ilé ẹjọ́ yọ̀ǹda Abba Kyari, wọ́n ní kò lẹ́jọ́ ọ́ jẹ́ lórí àwọn dúkìá tí kò kéde

Oríṣun àwòrán, Abba Kyari/Facebook
Ile ẹjọ giga to n jokoo niluu Abuja ti wọgile ẹṣun ti wọn ka si igbakeji kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nigan kan ri, Abba Kyari lẹsẹ, pe o kọ lati kede awọn dukia rẹ.
Bakan naa ni ile ẹjọ yọnda lori ẹsun naa
Adajọ James Omotosho lo gbe idajọ kalẹ lori ẹsun mẹtalelogun ti ajọ to n gbe ogun ti oogun oloro lorilẹede Naijiria, NDLEA fi kan Abba Kyari.
DCP Abba Kyari ati awọn ẹgbọn rẹ meji ni wọn foju ba ile ẹjọ pe ki wọn sọ pe awọn ni wọn ni awọn dukia kan.
Ninu idajọ rẹ, Adajọ Omotosho kuna lati ko ojulowo ẹri wa si ile ẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan Kyari.
Adajọ ni dukia ti wọn sọrọ lo le jẹ won gba lati pe o jẹ ogun tabi ki eeyan bu wọn gẹgẹ bii ẹbun.
Ki lo sẹlẹ ṣaaju?
Ọjọ kẹrinla, oṣu Keji ọdun 2022, ni NDELA kede pe Kyari wa ni ahamọ oun lori ẹsun pe o n ni ibaṣepọ pẹlu awọn to n ta oogun oloro.
Ikede naa lo waye lẹyin oṣu diẹ ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika, FBI sọ pe ki ọga ọlọpaa naa wa sọ tẹnu rẹ lori ibaṣepọ rẹ pẹlu afurasi onijibiti ori ayelujara, Hushpupi.
Awọn ọlọpaa mẹrin mii ni NDLEA fẹsun gbigbe oogun oloro naa kan, yatọ si Kyari.
Bakan naa ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji, Kyari pe ajọ NDLEA lẹjọ lori pe wọn fi ẹtọ oun dun oun gẹgẹ bii ọmọ Naijiria, ati lori bi wọn ṣe fi oun si atimọle.
Ninu iwe ipẹjọ naa lo ti ni ki ile ẹjo kan an nipa fun NDLEA lati fun oun ni owo gba ma binu ti iye rẹ to ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira lori bi wọn ṣe tẹ ẹtọ oun loju mọlẹ.
O tun ni oun n fẹ ki NDELA tọrọ aforiji lọwọ oun ninu awọn iwe iroyin to gbajumọ kaakiri Naijiria.


























