Fìtínà ni ogun tó ń wáyé láàárín Amẹ́ríkà-Israel àti Iran, ẹ yé dá sí ohun tí kò kàn yín nípa rẹ̀ – Ìgbìmọ̀ àwọn Imáàmù kìlọ̀

Aworan ile kan ti ogun ti wo pẹlu aṣia orilẹede Iran ti wọn ri si ori awoku ile naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images/lagos state government

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Igbimọ awọn Imaamu tik e sawọn musulumi lorilẹede Naijiria lati yago fun awọn ọrọ tabi iwa to le da omi alaafia orilẹede Naijiriar u nitori ogun ti Amẹrika ati Israel n gbe ko Iran lọwọlọwọ. bakan naa ni wọn tun ṣekilọ pe ki wọn dẹkun yiyọju tabi yọnu si wahala naa eyi to n ranju mọọ bayii lagbegbe ilẹ Larubawa.

Nibi eto iṣinu ati iwaasu asiko awẹ ti wọn ṣe nile ijọba ipinlẹ Eko to wa ni Ikẹja lawọn Imaamu naa ti sọ ọ di mimọ pe bi awọn kan ṣe n ṣe iwọde lawọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria, paapaajulọ awọn ọmọ ijọ Shiite ti wọn ṣe iwọde ni ilu Eko lori iku olori orilẹede Iran, Ali Khamenei lasiko ikọlu Amẹrika ati Iran ku diẹ kaato.

Adari agba fun ijọ Ansar-Ud-Deen lorilẹede Naijiria, Sheikh Abdulrahaman Ahmad to gbẹnusọrọ̀ fun igbimọ̀ awọn Imaamu ijọ Musulumi naa pe fun suuru ati ipamọra pẹlu ikilọ peorilẹede NAijiria ko gbọdọ fi aye gba wahala agbaye lati da rugudu silẹ labẹle rẹ.

Sheikh Abdulrahaman Ahmad ṣalaye pe adura fun itẹsiwaju alaafia ni ipinlẹ Eko ati orilẹede Naijiria lapapọ lo yẹ ki koowa o fi asiko awẹ Ramadan ati lenti yii gba dipo gigun le iwọde kan tabi ohun ẹtanu kankan nipa ogun to n ṣẹlẹ ni Iran.

'Fitina lohun to n ṣẹlẹ nilẹ larubawa'

Aworan awọn Imaamu agba joko.

Oríṣun àwòrán, Lagos state government

Awọn imaamu agba naa wa tun woye pe ohun to n ṣẹlẹ lagbaye lọwọ yii ko ṣai kan Naijiria, nitori naa adura fun ijọba lẹka gbogbo, wiwa ọna abayọ si awọn ipenija gbogbo lo yẹ ko mumu lọkan gbogbo mutumuwa.

"Ẹ yẹra fun fitina; nitori pe bi o ba ṣẹlẹ tan ati ẹni to mọwọ-mẹsẹ ati ẹni to joko jẹjẹ ni yoo kan. Fitina ni ogun to n waye nilẹ larubawa. Asiko fun adura ati lati wa alaafia niyi; kii ṣe akoko fun iwọde ati ifẹhonuhan kankan. Kii ṣe akoko ati maa bu eebu. Kii ṣe akoko hilahilo. Akoko ironu la wa."

Igbimọ awọn imaamu naa tẹsiwaju lati sọ pe, ohun to n ṣẹlẹ lagbaye bayii n ba Naijiria finra. O ni bi ọrọ ṣe n lọ yii afaimọ ki epo bẹntirolu o maa le sii, koda o le gbowo lori di ẹgbẹrun meji Naira lori lita kan tabi ju bẹẹ lọ.

Wọn tun kẹdun lori awọn ẹmi to ti lọ ati dukia to ti bajẹ labẹ ikọlu naa, wọn ni bi awọn eeyan ko b ani ọna abayọ fun awọn ohun ibanujẹ wọnyii ki wọn maṣe da kun un.