Nítorí aṣọ ilé ẹ̀kọ́, bàbá akẹ́kọ̀ọ́ lọ lu olùkọ́ lálùbolẹ̀ ni Kwara

Ariwo sọ niluu Ilorin, olu ipinlẹ Kwara bi obi ọmọ kan ṣe lọ koju ija si olukọ ọmọ rẹ nile ẹkọ Akerebiata Junior Secondary School to wa lagbegbe Akerebiata ni ijọba ibilẹ ila oorun Ilọrin.
Ọkunrin kan to ni ọmọ ni ile ẹkọ naa, ọgbẹni Adepoju Arewa la gbọ pe o lu olukọ ile ẹkọ naa ọgbẹni Ismail Abdullahi.
Iroyin ni niṣoju awọn akẹkọọ ni ọgbẹni Adepoju Arewa ti lu olukọ naa ni alubami ti ọpọ eeyan si n ṣe kayefi lati mọ ohun to ṣẹlẹ to to bẹẹ.
Ki lo ṣẹlẹ gan?
Ni Ọjọru, ọjọ Kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji ọdun yii ni a gbọ pe ọkunrin to ni ọmọ ni ile ẹkọ Akerebiata Junior Secondary School yawọ ile ẹkọ naa to si dun dundun iya fun olukọ kan nibẹ.
Nigba ti a s ikan si ile ẹkọ ọhun lati fidi ohun to waye mulẹ ni olukọ naa, Ismail Abdullahi sọ fun BBC News Yorùbá pe obi ọmọ naa fa aṣọ ya mọ oun lọrun pẹrẹpẹrẹ.
O salaye pe, iṣẹlẹ naa waye lasiko ti oun n ba akẹkọọ to jẹ ọmọ obi naa wi pe o wọ aṣọ ere idaraya wa si Ile ẹkọ dipo ko wọ aṣọ ile ẹkọ naa.
O ni bi oun ṣe fẹ naa ọmọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Adepọju Ibrahim ni ọmọ naa sakuro ni kiilasi to si salọ sile.
O sọ pe oun ti oun ri lẹyin naa ni baba ọmọ naa ọgbẹni Adepọju Arẹwa ṣe binu wọ ile ẹkọ naa to si bẹrẹ si ni lu oun tọrọ si di ariwo.
Ọgbẹni Abdullahi ni baba ọmọ naa ṣe n nao un ni ọmọ oun to w ani ile ẹkọ bu sẹkun gbọnrangandan nitori iṣẹlẹ jẹ ohun ibanujẹ fun-un.
Nibo lọrọ de duro?
Ninu ọrọ rẹ, giwa agba ile ẹkọ naa, Arabinrin Nimọta Isiaq sọ pe bi iṣẹlẹ naa ṣe n waye lawọn pe awọn agbaagba adugbo, ti wọn si fi iṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti.
O ni ko pẹ si asiko naa ni awọn ẹṣọ aabo ara ẹni laabo ilu, Civil Defence de sinu ọgba ile ẹkọ naa ti wọn si fi ofin gbe ọkunrin naa.
Giwa agba ile ẹkọ naa, Nimọta Isiaq sọ pe ọrọ naa ti deti gbọ ijọba ipinlẹ Kwara.
O salaye pe, wọn ti ranṣẹ pe ọkunrin naa ni ile iṣẹ eto ẹkọ ijọba ipinlẹ Kwara to si ti lọ tọrọ aforiji lọwọ olukọ to na ati lọwọ awọn olukọ yooku to w anile ẹkọ ọhun.
Isiaq juwe igbesẹ baba akẹkọo naa gẹgẹ bi eyi to lodi sofin ijọba lati lọ na olukọ lẹnu iṣẹ.
O wa gba awọn obi ni mọran lati maa ni sùúrù, ki wọn si maa fọwọsowọpọ pẹlu awọn olukọ lati le ba wọn tọju awọn ọmọ wọn bo ṣe yẹ.
























