Àwọn agbébọn jí èèyàn mẹ́rin nínú ìdílé kan náà gbé ní Kwara

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn afurasi agbebọn ti ji eeyan mẹrin gbe lọ ni ilu Babanla to wa ni ijọba ibilẹ Ifelodun ni Ipinlẹ Kwara.
Isẹlẹ yii waye ni aarọ kutu ọjọ Ọjọru, ọjọ karunlelogun osu yii nibi ti wọn ti n roko.
Awọn mẹrin ti wọn gbe yii ni a gbọ pe wọn jẹ ọmọ ile kan, wọn si ji lọ soko ni nnkan bii ago marun-un aarọ lati wa ohun ti wọn yoo jẹ.
Èyí kìí ṣe àkọ́kọ́ tí agbébọn yóò sọsẹ́ ní Babanla - Ìwádìí
Iwadii BBC Yoruba fihan pe akọkọ irufẹ iṣẹlẹ yii kọ ni eleyii ni ilu Babanla ati agbegbe rẹ.
Iwa ipaniyan ati ijinigbe gbilẹ de bi pe awọn araalu n fi ilu silẹ nigbakan ko to wa di pe nnkan tun fẹ maa sẹnure.
Ọkan lara rẹ ni ikọlu ti wọn se si ilu naa ni ọjọ ọja ninu osu kẹsan-an ọdun to kọja, ti wọn pa awọn eniyan, wọn si ba ọpọlọpọ ile igbe, ile ìtura awọn alupupu ati awọn nnkan mii jẹ.
Àwọn márùn-ún ní wọ́n kọ́kọ́ gbé kán tó jọ̀wọ́ àgbàlagbà kan - Aráàlú ṣàlàyé
Araalu kan ti a o le darukọ rẹ salaye pe, awọn marun-un ni awọn ajinigbe naa kọkọ gbe sugbọn wọn pada yọnda baba agba ninu wọn.
Gẹgẹ bii o se sọ, "isẹlẹ naa waye ni aarọ kutu ọjọ Ọjọru nigba ti wọn n sisẹ ninu oko wọn ni ilu Babanla.
"Awọn agbebọn yii ya wọ inu oko naa, wọn si n rọjo ibọn ki wọn to gbe wọn lọ.
"Bi wọn ṣe de ni wọn yi wọn ka ti ko si si aye ti ẹnikẹni lee gba sa lọ, awọn mẹrin ti wọn gbe lọ yii jẹ awọn ọmọ idile kan lati inu ile kan"
O wa rọ ijọba lati tunbọ mura si eeto aabo ni agbegbe naa ati iipinlẹ Kwara lapapọ.
Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, wọn o tii gbe orukọ awọn ti wọn gbe naa jade.
Kí ni ìjọba sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí?
BBC News Yoruba kan si alaga ijọba ibilẹ Ifelodun, Femi Yussuf lori ago, o si fidi iṣẹlẹ yii mulẹ
Igba to n sọrọ latẹnu agbẹnusọ rẹ, Lookman Abdulquadir, O ya a lẹnu bi awọn kan se le gbera lọ soko lago marun-un idaji pẹlu bi ode se ri.
O ni wọn o nilo lati sọ fun ẹnikẹni koto mọ asiko to tọ lati jade pẹlu ohun ti ode da bayii.
O ni, awọn ọmọ ogun, awọn fijilante, ati awọn ẹsọ asọgbo wa ni awọn agbegbe naa oun si mọ pe wọn yoo sisẹ wọn bi isẹ.
Titi di akoko yii, ọlọpaa ko tii fi ọrọ kankan lede lori iṣẹlẹ yii


























