Amẹrika àti Israel pa ọwọ́ pọ̀ ju ọ̀pọ̀ àdó olóró sí Iran

Oríṣun àwòrán, getty
Ijọba ilẹ Amẹrika ati orilẹede Israel ti pawọ pọ lati ju ado oloro si Iran.
Awọn aworan ti BBC foju ri ṣafihan bi eefin ṣe n ru laarin ilu Tehran, to jẹ olu ilu orilẹede Iran.
Lẹyin ikọlu naa ni Aarẹ Donald Trump sọ pe afojusun Washington ni lati dena ikọlu eyikeyi to le waye lati ọwọ Iran.
Minisiti eto abo Israel, Israel Katz ni tirẹ juwe ikọlu naa bii eyii to waye lati dena ikọlu ọjọ iwaju lati ọwọ Iran.
Ileeṣẹ iroyin AFP jabọ pe ibugbamu meji ọtọtọ lo dun ni Teharan laarọ ọjọ Abamẹta ti eefin si n ru soke laarin ilu naa.
Ninu fidio kan to fi lede, Trump sọ pe "Ileeṣẹ ọmọ ogun Amẹrika ti bẹrẹ ikọlu si Iran.
"A maa ba gbogbo ado oloro misaili wọn jẹ, a si maa sọ ileeṣẹ ti wọn ti n ṣe misailu di ẹdun arinlẹ.
"A maa pa gbogbo rẹ run patapata. A maa pa ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi wọn run."
Trump tun sọ fun awọn ọmọ orilẹede Iran ọhun pe asiko ominira wọn ti to, o ṣi ṣeleri iku fun awọn ọmọ ogun wọn to ba n ṣe agidi, ati ileri iwalaaye fun awọn to ba ju ọwọ silẹ.
Ẹwẹ, ileeṣẹ iroyin Iran kan sọ pe alaafia ni Aarẹ Masoud Pezeshkian wa lẹyin ikọlu ọhun.
Ileeṣe iroyin Fars jabọ pe ado oloro meje ọtọtọ lo balẹ si agbegbe Keshvardoost ati Pasteur.
Oṣojumikoro kan sọ fun AFP pe "Oju mi mejeji ni mo fi ri ado oloro Tomahawk meji ti wọn n fo… lakọkọ, ariwo ni a kọkọ gbọ, ki a to ri ọkọ ofurufu to n ju ado oloro."
Iran, Iraq ati Israel gbe papakọ ofurufu wọn ti pa lasiko ti ikọlu naa n lọ lọwọ, ọọfisi ijọba Amẹrika to wa ni Qatar ati Bahrain si ti rọ awọn ọmọ Amẹrika to wa lagbegbe naa ki wọn fo ori wọn pamọ.
Ṣaaju ikọlu yii ni ijọba Amẹrika ati Iran ti ni ifọrọwerọ ni Geneva amọ itakurọsọ naa fori ṣọpọn.
Trump sọ lẹyin ipade naa pe ijọba Iran ko tii ṣetan lati fun Amẹrika ni nnkan to n fẹ.

























