Ohun tí ṣíṣe àtúntò iléeṣẹ́ ọlọ̀pàá túmọ̀ sí fún Nàìjíríà

Àwọn ọlọ́pàá tó dúró ní àárín títì, wọ́n ń wo iwájú wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ètò ààbò jẹ́ ohun tó ń fa ìkọnilóminú ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lásìkò yìí pàápàá bí ìwà ìjínigbé àti ìgbéṣùmọ̀mí ṣe ń peléke sí ní ojoojúmọ́.

Àwọn ìpèníjà ààbò yìí ti ń ṣokùnfà báwọn èèyàn ṣe ń pè fún ìdásílẹ̀ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láti mójútó ààbò ní agbègbè àti ẹkùn kọ̀ọ̀kan.

Pẹ̀lú àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì àti ìjọba ìbílẹ̀ 774, ìjọba àpapọ̀ ló ń ṣe àkóso àwọn ọlọ́pàá tí iye wọn lé díẹ̀ ní 370,000 láti pèsè fún gbogbo èèyàn tó wà ní Nàìjíríà.

Ìpè fún ìdásílẹ̀ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ kò ṣẹ̀yìn bí ìkọlù àwọn agbébọn àti agbéṣùmọ̀mí, jíjí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé, tó fi mọ́ àwọn ìpèníjà ààbò míì ṣe ń wáyé lemọ́lemọ́ káàkiri gbogbo orílẹ̀ èdè yìí.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé òfin Nàìjíríà là á kalẹ̀ pé ọwọ́ ìjọba àpapọ̀ ni gbogbo ohun tó jọ mọ́ ọ̀rọ̀ ààbò wà, àwọn ọmọ Nàìjíríà gbàgbọ́ pé ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ yóò mú kí ètò ààbò tún sẹ́pẹ́rẹ́ ju báyìí lọ.

Èyí ló mú àwọn aṣòfin gbé àbá kan dìde láti ṣe àtúnṣe sí ìwé òfin Nàìjíríà láti fi ààyè gba ìdásílẹ̀ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀.

Àmọ́ àbá yìí kò ì tíì kọjá ipele àwọn ìgbìmọ̀ tó ń rí sí àtúnṣe yìí pẹ̀lú gbogbo báwọn gómìnà ṣe ń rọ ìjọba àpapọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n fi ààyè gba àwọn láti máa ṣàmójútó ètò ààbò fúnra wọn.

Láìpẹ́ yìí tún ni Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tún rọ ilé aṣòfin láti ṣàtúnṣe ìwé òfin láti fi ààyè gba ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ lójùnà àti lè kojú ìpèníjà ààbò tó ń bá orílẹ̀ èdè fínra.

Ààrẹ ní ohun tó ṣe pàtàkì lásìkò yìí ni ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ tó sì gbọdọ̀ wáyé ní kíákíá.

Ó ní àtúnṣe náà gbọdọ̀ wáyé ní kíákíá láti gbo gbogbo igbó ọba kúrò lọ́wọ́ àwọn ọbàyéjẹ́, káwọn ọmọdé náà sì lè kúrò nínú ìbẹ̀rù.

Ṣáájú ni gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olo àtàwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn náà ní ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ dá lórí dídá ààbò bo àwọn èèyàn.

Bákan náà ni àwọn gómìnà lẹ́kùn àríwá Nàìjíríà ti kọminú lórí bí wọn kìí ṣe le tètè jí gìrì sí ojúṣe wọn nígbà tí ìpèníjà ààbò bá wáyé nítorí àwọn kọ́ ni wọ́n ń ṣàkóso àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó wà ní ìpínlẹ̀ kóówá wọn.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló tis á fi ilé wọn sílẹ̀ nítorí ìkọlù, táwọn agbébọn sì ti jó ọ̀pọ̀ ilé, pa ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu oṣù díẹ̀ sẹ́yìn.

Kí ni àbá tó wà níwájú ilé aṣòfin?

Àbá tó wà níwájú ilé aṣòfin jẹ́ ojúnà láti mú ìgbéga bá ètò ààbò Nàìjíríà nípa ríri pé wọ́n pín agbára iléeṣẹ́ ọlọ́pàá.

Ṣíṣe àtúnṣe sí abala 197, 214, àti 215 ìwé òfin Nàìjíríà láti ṣe àkóso àti àmójútó iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà.

Tí àtúnṣe náà bá wáyé, àbá náà ń bèèrè fún ṣíṣe àyípadà ṣíṣe àkóso iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láti ọwọ́ ààrẹ nìkan àti ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, yóò fààyè gba ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀, tí yóò sì fààyè gba àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ láti máa ṣàkóso àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó bá wà ní ìpínlẹ̀ wọn pàápàá àwọn ọlọ́pàá.

Bákan náà ni àbá náà là á kalẹ̀ pé kò sí ààyè àwọn ọlọ́pàá ìjọba àpapọ̀ láti máa dá sí àkóso àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ tí wọ́n bá da sílẹ̀ tán.

Àwọn aṣòfin ìjọba àpapọ̀ àtàwọn ti ìpínlẹ̀ yóò máa rí sí yíyan ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pátápátá.

Ní ti ọ̀rọ̀ owó, àbá náà ní ọlọ́pàá ìjọba àpapọ̀ yóò máa ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ ilé aṣòfin àpapọ̀.

Ṣé Ààrẹ Tinubu le mú kí ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ kẹ́sẹ járí?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Pẹ̀lú bí awuyewuye ṣe ń wáyé lórí ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀, ohun tí àwọn èèyàn ń kọminú lórí jùlọ ni pé ṣáwọn gómìnà kò ní ṣe àmúlò àwọn ọlọ́pàá náà lọ́nà àìtọ́?

Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú òfin ọlọ́pàá, ojúṣe ọlọ́pàá ni láti ṣàwárí, kí wọ́n sì dènà ìwà ọ̀daràn láwùjọ, kí wọ́n sì dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn.

Ẹ̀wẹ̀, níṣe ni àwọn èèyàn ń kọminú lórí bí àwọn gómìnà kò ṣe ní máa lò wọ́n fún àṣìlò agbára.

Àwọn ìpèníjà tó ń kojú iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tẹ́lẹ̀ ni àìsí òṣìṣẹ́ tó, àìní ohun èlò tó pójú owó àti ìwà àjẹbánu.

Lára àwọn ohun tí àwọn onímọ̀ ń gbèrò pé àyípadà máa bá lẹ́yìn ìyànsípò Olatunji Disu gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ni ọ̀nà táwọn ọlọ́pàá ń gbà ṣiṣẹ́.

Onímọ̀ nípa ètò ààbò, Auwal Durimin Iya sọ fún BBC pé tí Disu bá fẹ́ borí àwọn ìpèníjà tó ń kojú iléeṣẹ́ ọlọ́pàá báyìí, ó nílò láti mú àyípadà bá àwọn ìlànà tí wọ́n ń gbà ṣiṣẹ́ lásìkò yìí.

Gbogbo ìgbà ni ìjọba tó wà lóde lábẹ́ ìṣèjọba Tinubu ti ń jẹ́jẹ̀ẹ́ láti pèsè ètò ààbò tó dájú fáwọn èèyàn ṣùgbọ́n ìkọlù gbogbo ìgbà tó ń wáyé ń mú káwọn èèyàn máa se iyè méjì.

Bí ó ṣe ku bíi ọdún kan tí ètò ìdìbò gbogbogboò ọdún 2027 máa wáyé, ṣíṣe ìdásílẹ̀ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ le wáyé tí àwọn aṣòfin bá mu ní òkúnkúndùn.

Àwọn ìlànà láti ṣe àtúnṣe sí ìwé òfin kìí ṣe ohun tó rọrùn, ó máa ń gba àkókò, tó sì máa ń gba ìgbìmọ̀ lọ́kan-ò-jọ̀kan kọjá.

Ṣùgbọ́n ohun tó le mú kí Ààrẹ Tinubu le kẹ́sẹ járí lórí ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ wà lọ́wọ́ ilé aṣòfin àti pé ṣé ó ṣì máa wà lórí ipò nígbà tí gbogbo ìlànà rẹ̀ fi máa parí.