Wo ohun tó mú Busola Oke 'Eleyele' sunkún tó ń fa awuyewuye lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, Biola Adebayo/Instagram
Níṣe ni gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí, Busola Oke tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Eleyele ti sọ àwọn ìlàkàkà tó ń là kọjá láti bíi ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.
Lórí ìkànnì TikTok ti akọrin ẹ̀mí náà ti bú sẹ́kún tó sì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tó ń kojú rẹ̀ lórí iṣẹ́ tí yàn láàyò.
Nínú fídíò náà, tó gba orí ayélujára ni Eleyele ti ní ṣíṣe oríire nídìí iṣẹ́ orin kíkọ kọjá níní ẹ̀bùn lásán.
"Sí ẹ̀yin olólùfẹ́ mi, ẹ má bínú, mi ò gbèrò láti ṣe èyí ṣùgbọ́n ọkàn mi kò gbé e mọ́. Orin gidi kò tà mọ́."
Ó kọminú lórí bí àwọn akọrin ṣe le ní ìfọ̀kànbalẹ̀ láìsí àwọn ohun amáyédẹrùn tí wọ́n nílò láti fi gbé ìgbé ayé tó rọrùn.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn akẹgbẹ́ òun tí àwọn jọ bẹ̀rẹ̀ ni wọn kò tib á òun ṣe mọ́, tí òun sì ń gbé bí ẹni tí kò ní ẹnìkankan.
'Ohun tó mú mi ṣe fídíò tí mo ti ń sunkún rèé'
Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ míì tí akọrin náà ṣe pẹ̀lú òṣèré Biola Adebayo, Busola Oke ní ohun tó mú òun ṣe fídíò náà kò ṣẹ̀yìn bí òun ṣe ń dáwà tí kò sì sí owó kankan lọ́wọ́ òun.
Busola Oke sọ níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà pé láti ọdún 2020 ni òun kò ti ní ọkọ̀ kankan lọ́wọ́ mọ́ àti pé gbèsè pọ̀ lọ́rùn òun.
Bákan náà ló sọ pé òun kò ní ibí tí òun ń gbé mọ́ nítorí òun kò rí owó ilé san àti pé gbogbo owó tó yẹ kí òun fi jẹun ni òun fi ń gbé ọkọ̀ kiri.
"Nítorí ebi tó ń pa mí ló jẹ́ kí ń sunkún lórí ayélujára. Mi ò bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ tẹ́lẹ̀ nítorí kìí ṣe irú èèyàn tí mo jẹ́ nìyẹn.
"Láti ọdún 2020 ni mo ti ń dákẹ́ lórí ọ̀rọ̀ mi nítorí mi ò fẹ́ kí àwọn èèyàn máa fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni mo mọ̀ ṣùgbọ́n wọn ò ṣe ìrànwọ́ fún mi. Mi ò rí owó ilé mi san mọ́ nígbà tó di àsìkò kan."
'Lóòótọ̀ ni mo wà nínú ìbànújẹ́ ṣùgbọ́n mi ò gbèrò láti pa ara mi'
Busola Oke tún sọ̀rọ̀ pé òun kò sọ pé òun máa gbẹ̀mí ara òun bí àwọn kan ṣe ń gbe kiri lórí ayélujára.
Ó ní àwọn èèyàn ṣi òun gbọ́ lórí nǹkan tí òun sọ ni nítorí òun kò sọ pé òun máa gbẹ̀mí ara òun nígbà tí òun ń ṣe fídíò náà.
Ó ṣàlàyé nígbà tó ń bá Biola Adebayo sọ̀rọ̀ pé àwọn èèyàn gba ohun tí òun sọ sódì bí wọ́n ṣe yí ọ̀rọ̀ náà mọ́ òun lọ́wọ́.
Ó sọ pé gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ náà ti kún òun lẹ́mìí ni òun ṣe bọ́ síta láti sọ àwọn ìlàkàkà òun àti ohun tí òun ń la kọjá.
"Níṣe ló dàbí kò sí ẹnikẹ́ni ní àkàtà mi, tí mo dá wà lásán, òun ló jẹ́ kí ń bọ́ sórí ayélujára."
Lásìkò tí akọrin ẹ̀mí náà ń sọ̀rọ̀, ó ní òun sọ fún àwọn èèyàn láti máa bá òun pín fídíò náà ká láti mọ̀ bóyá àwọn èèyàn ṣì wà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun.
Busola Oke ní láti ìgbà tí òun ti ṣe fídíò náà ni àwọn èèyàn ti ń kàn sí òun, tí inú òun sì ń dùn pé àwọn èèyàn ti ń ríran rí òun.
























