Àjọ INEC kéde ọjọ́ tuntun fún ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, ètò ìdìbò Ààrẹ 2027

Aworan Aisa ajo eleto idibo INEC

Oríṣun àwòrán, X/INEC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria (INEC) ti mu ọjọ tuntun fun eto idibo aarẹ, gomina ati ile igbimọ aṣofin.

Eyi waye lẹyin ọsẹ meji ti ajọ naa kede asiko fun eto idibo, ti ọpọ eeyan si bu ẹnu atẹlu ikede pe oṣeeṣe ki asiko eto idibo naa bọ si asiko ti awọn Musulumi ba n gba awẹ Ramadan 2027.

Ni akọkọ, Ogunjọ oṣu Keji ọdun 2027 ni ọjọ ti INEC mu eto idibo aarẹ ati ile igbimọ aṣofin agba , ti wọn si mu ọjọ kẹfaa oṣu Kẹta gẹgẹ ọjọ fun eto idibo fun eto idibo Gomina ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ.

Ninu atẹjade ti ajọ naa fi lede, eyi to jẹ itọwọbọ lati ọdọ alaga ẹka to n risi idanilẹkọ awọn oludibo, Mohammed Kudu Haruna, o ni. "Lẹyin atunṣe iwe ofin nipa ibo ti ọdun 2022 ati ibuwọlu iwe ofin idibo ti ọdun 2026, ajọ ti pinnu latinṣe awọn atunṣe ṣaaju igbaradi fun eto idibo ati asiko ti yoo waye ni ilana pẹlu ofin tuntun.

Bakan naa ni INEC tun ṣe atunṣe si ọjọ ti eto idibo yoo waye nipinlẹ Osun.

Ọjọ kẹjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2026 ni o yẹ ki eto idibo nipinlẹ waye ṣugbọn ajọ INEC ti sun si siwaju si ọjọ Kẹdogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026.

INEC ni awọn eto idibo abẹle fun awọn ẹgbẹ oṣelu yoo gbera sọ ni Ọjọ Kẹtalelogun oṣu keji si Ọgbọnjọ oṣu Karun un nigba ti ipolongo ibo fun awọn ẹgbẹ oṣelu fun ipo aarẹ ati ile igbimọ aṣofin yoo bẹrẹ ni ọjọ kọkandinlogun.

Ipo lpolongo ibo fun ipo gomina ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ yoo bẹrẹ ni ọjọ kẹsan an oṣu Kẹsan an ọdun 2026.

Awọn ọjọ wo ni eto idibo yii yoo waye

Ọjọ tuntun ti ajọ INEC mu yii ni wọn ti fi sita fun awọn araalu.

Eto idibo aarẹ ati ile igbimọ aṣofin agba ati aṣojusofin- yoo waye ni Ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kini ọdun 2027.

Eto idibo gomina ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ yoo waye ni Ọjọ Kẹfa oṣu Keji ọdun 2027.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post