Bí nǹkan oṣù rẹ̀ bá ń gba èékánná, ìdodo, àtẹ́lẹwọ́ àtàwọn ẹ̀yà ara tó yàtọ̀ sí ojú ara jáde, ọ̀nà àbáyọ rèé

Àkọlé fídíò, Bí nǹkan oṣù rẹ̀ bá ń gba èèkánná, ọpọlọ, àtẹ́lẹwọ́ àtàwọn ẹ̀yà ara tó yàtọ̀ sí ojú ara jáde, ọ̀nà àbáyọ rèé
Bí nǹkan oṣù rẹ̀ bá ń gba èékánná, ìdodo, àtẹ́lẹwọ́ àtàwọn ẹ̀yà ara tó yàtọ̀ sí ojú ara jáde, ọ̀nà àbáyọ rèé

Awọn iṣẹda obinrin kan wa to jẹ wi pe ori eekanna, itan, ọwọ, atẹlẹsẹ tabi awọn ẹya ara miran to yatọ si oju ara obinrin ni nnkan oṣu wọn ti maa n waye.

Eyi kii ṣe tuntun o, ṣugbọn ohun to maa n ṣe ọpọ ni kayeefi ni pe ki gan an lo fa a ti awọn nnkan wọnyii fi n ri bẹẹ.

Lati le tan imọlẹ si ọrọ yii, BBC News Yoruba kan si akọṣẹmọṣẹ iṣegun kan, Dokita Taofeek Ogunfunmilayọ lọ, ẹni to ṣalaye fun wa pe ẹran kan wa ni ile ọmọ obinrin eyi to maa n kuro lara ile ọmọ loṣoṣu ti wọn fi n sọ pe awọn obinrin n ṣe nnkan oṣu.

O ni nnkan oṣu yii ba n ṣẹlẹ ni ẹdọ fooro awọn obinrin, o le maa fa ikọ wiwu eyi to le maa pọ ẹjẹ nigba miran. Dokita Ogunfunmilayọ fi kun un pe nigba miran ẹwẹ, awọn miran a maa lọ sinu ọpọlọ, eleyii to ni o lee fa ẹfọri, tabi giiri fun iru obinrin bẹẹ tabi ko maa daku lasiko to ba n ṣe nnkan oṣu rẹ.

Ki wa lọna abayọ?

Onimọ nipa ilera awọn obinrin naa ṣalaye pe ifa to letutu lọrọ naa ati wi pe ọna abayọ rẹ pọ daadaa. o ni nitori pe bi obinrin ba loyun kii ṣe nnkan oṣu, kini ọhun ko ni le dagba sii lasiko naa.

o ni ọkan gboogi ninu ọna abayọ naa ni ki wọn sọ fun obinrin to ba n ni irufẹ ọna nnkan oṣu bẹẹ pe ko lọ loyun.

Ẹ wo fidio yii lati gbọ alaye lori awọn ọna abayọ miran to wa fun.