Irọ́ méje tí wọ́n pa fún ọ nípa àwọn obìnrin tí kò ṣe nnkan oṣù mọ́ àti òtítọ́ nípa wọn

Ami idanimọ nnkan osu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, Senior Journalist
    • Reporting from, Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Jakejado agbaye ni awọn obinrin to n wọ ipele ti wọn ko ti ni i ṣe nnkan oṣu mọ, eyi ti wọn n pe ni menopause ni ede Gẹẹsi.

Lọdun 2021, awọn obinrin to ti pe aadọta ọdun, ko ida 26% ninu awọn obinrin – tọmọde-tagba – l'agbaye. Ọjọ ori yii ni ọpọ gbagbọ pe, nnkan oṣu obinrin ma n bẹrẹ si ni dawọ duro.

Ti ọjọ ori obinrin ba ti le ni ogoji, ni awọn apẹẹrẹ pe nnkan oṣu rẹ ko ni i wa mọ yoo ti maa farahan. Peri-menopause ni wọn ma n pe ipele yii, bi ọdun mẹrindinlaadọta si lo ma n bẹrẹ.

Asiko yii ni awọn obinrin yoo ṣakiyesi pe, nnkan oṣu wọn n ṣe ṣege-ṣege, ti ko si ni i wa deede- ẹjẹ to n jade yoo pọ si tabi kere si i, bakan naa ni ọjọ ti wọn fi n ṣe nnkan oṣu le dinku tabi pọ si. Awọn obinrin mii ti ẹ tun ma n ni awọn ailera ti wọn ko ni tẹlẹ.

Ṣugbọn ṣa, bi ọdun mọkanlelaadọta gan-an ni nnkan oṣu naa ṣe e ṣe ko dawọ duro patapata.

O si di igba ti nnkan oṣu ko ba waye fun oṣu mejila gbako ka to o le sọ pe, o ti dawọ duro patapata.

Fun awọn obinrin kan, o le ri bẹẹ ṣaaju ki wọn to pe aadọta ọdun – o le dawọ duro funra rẹ, o si le jẹ nitori itọju ti wọn n gba fun aisan kan ninu agọ ara wọn.

Awọn apẹẹrẹ pe o ti wọ menopause

Ti nnkan oṣu obinrin ba ti dopin, ọpọlọ, awọ ara, igbeaye, iṣan ara ati nnkan oṣu lo ma n mọ ipa adinku omoonu oestrogen ninu ara.

Awọn obinrin le ni diẹ lara awọn apẹẹrẹ yii, o si le jẹ perete tabi ki wọn o ma ti ẹ ri apẹẹrẹ kankan:

  • Nnkan oṣu to pọ si tabi ti ko wa deede
  • Ooru yoo ma a mu wọn lati inu
  • Wọn o maa laagun ju bo sẹ yẹ paapaa ni alẹ tabi oru
  • Ara wọn ko ni i ya gaga
  • Oju ara wọn yoo gbẹ
  • Ailera le bai le itọ wọn

Yatọ si awọn nnkan yii, obinrin to ti wọ menopause yoo tun ma a gbagbe nnkan, bakan naa ni ọkan rẹ ko si ni i papọ. Irora ni orikerike ara ati awọ ara to n gbẹ naa ko gbẹyin

Kii ṣe gbogbo obinrin lo ma n doju kọ eyi, amọ ida 75% lo ṣaba ma n ṣe.

Awọn irọ mẹfa nipa menopause

Lootọ ni opin nnkan oṣu jẹ nnkan ti ko le ṣalai ṣẹlẹ ninu igbeaye obinrin, oriṣiriṣi irọ ati ahesọ ọrọ lo rọ mọ ọ.

Awọn ahesọ ọrọ yii ko mọ ni orilẹede kan, jakejado agbaye ni wọn ti n pa wọn. meje lara awọn irọ ati ahesọ ọrọ nipa menopause re e ati otitọ nipa wọn:

1. Bakan naa ni 'menopause' ṣe ma n ri lara gbogbo obinrin

Ọkan lara awọn irọ ti awọn eeyan ma n pa nipa opin nnkan oṣu obinrin ni pe, bakan naa ni iriri awọn obinrin to ba ti de ipele naa.

Rara o, eyi ko ri bẹẹ rara. Ọna ọtọọtọ ni ayipada ma n gba ba awọn omoonu ara obinrin kọọkan – eyi si ni i ṣe pẹlu ẹya, igbeaye ati awọn nnkan mii to n ṣẹlẹ ninu agọ ara obinrin.

2. Ti o ba le ni aadọta ọdun ni wa a wọ menopause

Lootọ ni nnkan oṣu obinrin ma n dopin lati bi ẹni ọdun mọkanlelaadọta, amọ o le waye laarin ogoji ọdun si ọgọta – eyi nii ṣe pẹlu ẹya ati orilẹede.

3. Dandan ni ki o sanra si to ba ti wọ menopause

Bi eeyan ṣe n dagba, ni bi awọn ẹya ara ṣe n ṣiṣẹ n dinku si i. Eyi ko ni i ṣe pẹlu menopause rara. Awọn dokita ti ẹ sọ pe ere idaraya ati ounjẹ aṣaraloore ma n ṣe iranlọwọ lati din ara sisan ju, ku.

4. Ooru atinuwa nikan ni apẹẹrẹ menopause

Ooru atinuwa, eyi ti wọn n pe ni hot flashes ni ede Gẹẹsi wọpọ, amọ kii ṣe gbogbo obinrin lo ma n ni i.

Ọdun meji akọkọ ti nnkan oṣu ba dawọ duro lo ma n pọ, to si ma n dopin to ba ti le ni ọdun meje. Eyi ri bẹẹ laarin ida 60% obinrin.

5. Menopause ko ni jẹ ko gbadun nnkan oṣu mọ

Nini ololufẹ to ni ifarada yoo mu ki ibalopọ rọrun fun obinrin to ti wọ menopause

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Nini ololufẹ to ni ifarada yoo mu ki ibalopọ rọrun fun obinrin to ti wọ menopause

Oju ara to gbẹ, aini ifẹ si ibalopọ ati irẹwẹsi ọkan le mu ki ibalopọ o ma lọ geere. Ṣugbọn, pẹlu iranlọwọ awọn oṣiṣẹ eleto ilera ati ololufẹ to ni ipamọra, awọn obinrin ṣi le ma a gbadun ibalopọ lẹyin ti nnkan oṣu wọn ba dawọ duro.

6. Ọda nnkan oṣu n fa irẹwẹsi ọkan, ikanra ati ipaya

Menopause kii fa irẹwẹsi ọkan, amọ o ma n fa airoorun sun, ooru atinuwa, eyi to wọpọ laarin awọn obinrin to ti ṣiwọ nnkan oṣu. eyi si le mu ki wọn o di onikanra.

7. Gbigba itọju fun omoonu ni ewu

Bo tilẹ jẹ pe lilo awọn eroja omoonu le fi ọ sinu ewu jẹjẹrẹ ọyan, o tun le mu adinku ba aisan ọkan.

Iwadii fihan pe awọn anfaani to wa ninu lilo eroja omoonu, pọ ju ewu to wa nibẹ lọ fun awọn obinrin to ni ilera pipe, ti ko si ti i pe ọgọta ọun.