Ṣé o le gbà láti ṣiṣẹ́ abẹ gígé okùn méjì tó ń gbé àtọ̀ nínú kórópọ̀n rẹ̀ dípò kí aya rẹ̀ ṣe ìfètòsọ́mọbíbí?
Ǹ jẹ́ ìwọ gẹ́gẹ́ bíi ọkùnrin le è gbà láti ṣiṣẹ́ abẹ gígé okùn méjì tó ń gbé àtọ̀ nínú kórópọ̀n rẹ̀ dípò kí aya rẹ̀ ṣe ìfètòsọ́mọbíbí?
Iwadii fihan pe ida mẹrindinlọgbọn ninu ọgọrun ọmọ Naijiria, to fi mọ ọkunrin ati obinrin, lo gba lati sisẹ abẹ yii.
Amọ ida mẹrinlelaadọta yoku lo faake kọri pe awọn ko le se isẹ abẹ naa ti amọ si Vasectomy ni ede Gẹẹsi.
BBC Yoruba wa bọ si igboro lati bawọn araalu sọrọ pe se ọkunrin kan le gba lati sisẹ́ abẹ́ yii, tabi pe se awọn obinrin le gba pe ki ọkọ wọn se.

Ki lo n jẹ Vasectomy?
Vasectomy jẹ isẹ abẹ kekere kan, ti kii dun eniyan rara.
Isẹ abẹ yii ni wọn n se gé okùn méjì tó ń gbé àtọ̀ nínú kórópọ̀n lọ sinu ẹyin ile ọmọ obinrin.
Isẹ abẹ naa si maa n dena oyun nini ti tọkọ-taya ko ba ro tẹlẹ, paapaa lẹyin ti wọn ko ba fẹ bimọ mọ.
Isẹ́ abẹ naa kii si se akoba kankan fun nnkan ọmọkunrin.
Koda, o tun rọrun lati so okun mejeeji pada lọjọ iwaju, eyiun awọn okun meji to n gbe atọ ọkunrin ninu koropọn ti wọn ti ge tẹlẹ lẹyin isẹ abẹ naa.
N jẹ o wa setan lati se isẹ abẹ naa bi?






