Nǹkan mẹ́jọ tó le mú kí obìnrin má rì í nǹkan oṣù láì lóyún

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, BBC 100 Women
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀dá obìnrin, tí ọmọbìnrin bá ti dé àwọn ọjọ́ orí kan ló máa bẹ̀rẹ̀ nǹkan oṣù, tí nǹkan oṣù obìnrin kò sí tún ní wá mọ́ nígbà tí èèyàn bá ti dàgbà tó ọjọ́ orí kan.
Nǹkan tó máa ń fa kí obìnrin tó wà lọ́wọ́ ọmọ bíbí má rì í nǹkan oṣù rẹ̀ ni oyún àmọ́ ó ṣeéṣe kí obìnrin má rì í nǹkan oṣù rẹ̀ láì ṣe pé ó lóyún.
Èyí ni àwọn olóyìnbó ń pè ní "amenorrhea". Onírúurú ìdí ló le mú kí obìnrin má rì í nǹkan oṣù láì ṣe pé ó lóyún.
Gẹ́gẹ́ bí ìṣe, láàárín ọjọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n ni ọ̀pọ̀ obìnrin máa ń ṣe nǹkan oṣù ṣùgbọ́n táwọn obìnrin míì yàtọ̀.
Àwọn obìnrin míì le máa rí nǹkan oṣù láàárín ọjọ́ mẹ́rìnlélógún sí ọjọ́ márùndínlógójì.
Tí obìnrin kò bá rí nǹkan oṣù rẹ̀ láàárín ọjọ́ péréte tàbí tí ọjọ́ tó yẹ kó ri bá lé díẹ̀, ó ṣeéṣe kó má jẹ̀ ẹ́ ohun tó nira àmọ́ tó bá ń léra ní gbogbo ìgbà, ó nílò àmójútó, ó sì lè jẹ́ àmì àpẹẹrẹ àìsàn kan tàbí òmíràn.
Dókítà Amira Alkourdin Martinez sọ fún BBC pé "èèyàn nílò láti mọ ara rẹ̀ àti bí ara òun ṣe ń ṣiṣẹ́, ó nílò láti mọ̀ nígbà tí nǹkan kò bá lọ bó ṣe yẹ. Obìnrin méjì kò rí bákan náà, bí ara wa ṣe ń ṣiṣẹ́ sì yàtọ̀ síra".
Àjọ tó ń rí sí ètò ìlera ní UK, National Health Scheme, NHS sọ pé kí obìnrin tètè kàn sí àwọn dókítà rẹ̀ nígbà tí kò bá rí nǹkan osù rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta láì ṣe wí pé ó lóyún tàbí tí nǹkan oṣù rẹ̀ kò bá wá mọ́ nígbà tí kò bá ì tíì pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́ta.
Bákan náà ni ilé ìwòsàn Mayo Clinic ní Amẹ́ríkà sọ pé ọmọbìnrin tó bá ti lé ní ọdún mẹ́ẹ̀dógún láì tíì bẹ̀rẹ̀ nǹkan oṣù nílò láti rí àwọn dókítà.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn iléeṣẹ́ ètò ìlera yìí ṣe sọ, àwọn nǹkan mẹ́jọ yìí ló le mú obìnrin má rì í nǹkan oṣù rẹ̀ láì lóyún.
1. Wàhálà ṣíṣe
Dókítà Amira Alkourdin Martinez sọ wáhàlá ṣíṣe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó ń ṣe àkóbá lọ́pọ̀lọpọ̀ fáwọn èèyàn lásìkò yìí.
Wáhàlá ṣíṣe máa ń bí ìpèsè àwọn hòmóònù bíi "adrenaline", mú kí ara wà ní ìtají láti ojú oro sí ohun tó le ṣe ìjàmbá fára.
Tí ara bá ń pèsè àwọn hòmóònù fún ọ̀pọ̀ ìgbà, ó le ní ipa lórí nǹkan oṣù – ó le mú kí nǹkan oṣù pẹ́, yá kíákíá, kí ó má wà á rárá tàbí kí nǹkan mí ìnira púpọ̀ dání.
Nígbà míì, ó le mú kí obìnrin rí nǹkan oṣù ní ẹ̀ẹmèjì láàárín oṣù kan.
Tó bá jẹ́ pé wáhàlá ló ṣe ìdádúró nǹkan oṣù, NHS ní kí èèyàn máa ṣe eré ìdárayá lóòrè kóòrè tàbí máa mí dáadáa láti fi kojú ìṣòro náà.
Tí èyí kò bá ṣiṣẹ́, ètò ìwòsàn kàn tí wọ́n ń pè ní "cognitive-behavioural therapies (CBT)" ni wọ́n máa lò láti tọ́jú ẹni bẹ́ẹ̀.
2. Kí èèyàn rù púpọ̀
Tí èèyàn bá mú àdínkù bá iye oúnjẹ tó máa ń jẹ le dènà ẹ̀yà ara láti pèsè àwọn hòmóònù tó máa ń mú obìnrin ṣe nǹkan oṣù.
Àwọn onímọ̀ nípa oúnjẹ le ṣe ìrànwọ́ fún ẹni tó bá rù púpọ̀, tó fi mọ́ àgbàlagbà tí kò gbé ìwọ̀n tó yẹ, láti bú sára lọ́nà tí kò ní ṣàkóbá fún ìlera wọn.
Tó bá jẹ́ pé àìrí oúnjẹ jẹ bíi "anorexia" ló ń fa tí èèyàn bá ń rù, onítọ̀hún yóò nílò ìrànwọ́ àwọn onímọ̀ ìtọ́jú ọpọlọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
3. Ara àsanjù
Tí èèyàn bá ń sanra ní àsanjù le mú kí ara pèsè àpọ̀jù oestrogen, ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà ara tó ń ṣàmójútó àwọn ẹ̀yà ara ìbímọ obìnrin.
Tí oestrogen bá pọ̀ jù, ó le ní ipa lórí nǹkan oṣù, tó sì lè mu kí nǹkan oṣù dúró nígbà míì.
Fún àwọn obìnrin tó jẹ́ ara àsanjù ló fa àìrí nǹkan oṣù wọn, àwọn dókìtà máa ń darí wọn sọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ nípa oúnjẹ láti mójútó ara sísan wọn.
4. Àpọ̀jù eré ìdárayá
Ohun míì tó le fa kí nǹkan oṣù obìnrin dúró ni tí eré ìdárayá bá pọ̀ jù bó ṣe yẹ lọ.
Àpọ̀jù eré ìdárayé le ṣokùnfà kí àwọn hòmóònù tó rí sí nǹkan oṣù má ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ àti pé tí èèyàn bá pàdánù ọ̀rá púpọ̀ lára le dènà nǹkan oṣù.
Fún àwọn eléré ìdárayà, àwọn dókítà máa ń fún wọn lámọ̀ràn lórí bí wọ́n ṣe le ṣe eré ìdárayá lọ́nà tí kò ní ṣàkóbá fún ẹ̀yà ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
5. Polycystic Ovary Syndrome (PCOS)
Èyí túmọ̀ sí pé àwọn àpò kan kò dàgbà dáadáa lára ilé ẹyin ọmọbìnrin tí ẹyin ti ń dàgbà.
Àwọn obìnrin tó bá ní àìlera yìí kìí lè pèsè tó máa ń di nǹkan oṣù.
Ní UK, NHS ní PCOS ń da ó kéré tán obìnrin kan láàmú nínú obìnrin mẹ́wàá. Bákan náà ló kó ìdá mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33%) nínú ohun tó ń fa ìdí táwọn obìnrin kìí fi rí nǹkan oṣù wọn.

6. Kí obìnrin ti dé ọjọ́ orí tí kò ní ṣe nǹkan oṣù mọ́
Gẹ́gẹ́ bí oyún tàbí tí obìnrin bá ń fún ọmọ lọ́yàn, tí obìnrin bá ti dé ọjọ́ orí tí kò ní rí nǹkan oṣù mọ́, ó máa dúró.
Táwọn obìnrin bá ti ń wọ ọjọ́ orí yìí lọ, ipa oestrogen máa bẹ̀rẹ̀ sí ní dínkù.
Láàárín ọjọ́ márìndínláàádọ́ta (45) sí márùndínlọ́gọ́ta (55) ni nǹkan oṣù obìnrin fi máa ń dúró, tí kò ní wá mọ́ rárá.
Àmọ́, ìwádìí ti fi hàn pé àwọn obìnrin kan ni nǹkan oṣù wọn máa dúró, tí kò ní wá mọ́ rárá nígbà tí ọjọ́ orí wọn kò ì tíì wọ ogójì ọdún. Obìnrin kan níní ọgọ́rùn-ún obìnrin ni èyí máa ń ṣẹlẹ̀ sí.
7. Àwọn oògùn ìfètò sọ́mọ bíbí
Àwọn oògùn, abẹ́rẹ́ ìfètò sọ́mọ bíbí náà máa ń fa kí obìnrin má rì í nǹkan oṣù.
Kódà lẹ́yìn tí èèyàn bá ṣe ìdádúró àwọn oògùn náà ní lílò, ó máa ń tó ìgbà díẹ̀ kí ara tó tún bọ̀ sípò padà.
8. Àwọn àìlera míì àti lílo oògùn fún ìgbà pípẹ́
Ó ṣeéṣe kí obìnrin má rì í nǹkan oṣù nígbà tó bá ń kojú àwọn àìlera kan bíi ìtọ ṣúgà, hyperthyroidism tàbí hypothyroidism.
Bákan náà ni àwọn oògùn kan náà máa ń fa kí obìnrin má rì í nǹkan oṣù fún ìgbà pípẹ́ bíi antipsychotics, chemotherapy, antidepressants, àti ìtọ́jú ẹ̀jẹ̀ rúru gẹ́gẹ́ bí ilé ìwòsàn Mayo Clinic ṣe sọ.















