Níbo láwọn dúkìá tí àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ ń gbà lọ́wọ́ àwọn olóṣèlú wà?

Oríṣun àwòrán, X/Multiple
Lorilẹede Naijiria, ijọba tig be ọpọ igbesẹ lati gbe ẹsẹ le awọn dukia kan ti wọn gba lọwọ awọn eeyan kan ti wọn ṣe owo ilu mọkumọku.
Laipẹ yii ni ijọba gbe ẹsẹ le dukia ile gbe to pọ ti Gomina tẹlẹ fun banki apapọ, Godwin Emefiele kọ kalẹ.
Lẹyin dukia, ajọ to n gbe ohun ti iwa ibajẹ bii EFCC ati ICPC lorekore ti kede pe awọn ti gba awọn owo kan pada lọwọ awọn eeyan ti wọn fẹsun iwa ibajẹ kan.
Fun idi eyi, ibo gan ni awọn dukia ati owo yii wa?
Lẹyin ikede gbigba dukia lọwọ Gomina CBN tẹlẹ, ọpọ eeyan lo ti n sọrọ nipa nnkan to yẹ ki ijọba ṣe nipa dukia ti wọn gba pada.

Oríṣun àwòrán, X/@icpcnigeria
BBC ba ọga agba fun ajọ ICPC, Musa Adamu Aliyu sọrọ lori bi wọn se n se awọn dukia ti wọn gba pada yii.
Alaga fun ICPC ni eto ti w ani ilẹ nipa awọn igbesẹ ti wọn yoo gbe lori awọn dukia ti wọn gba lọwọ awọn afurasi ọdaran.
Eyi lo wa ninu iwe ofin ti ọdun 2022 to fi han BBC.
"Lẹyin ti a b agba awọn dukia yii ni ilana ofin, ti a si ta wọn, a ko owo naa si apo ijọba ṣugbọn o ni awọn kan to jẹ pe aarẹ nikan lo le sọrọ nipa rẹ."
"O ni apo owo fun ajọ to n gbe ogun ti iwa ibajẹ ni ile ifowopamọ banki orilẹede Naijiria lati ko awọn owo yii si saaju idajọ ile ẹjọ,"
Bawo gan ni ijọba Naijiria ṣe ma n gbesẹ le dukia?
Alaga ICPC ni ọpọ awọn dukia yii lo jẹ pe ile ẹjọ lo aṣẹ kalẹ pe ki wọn gba awọn dukia naa,
O ni awọn ajọ yii ko ni aṣẹ lati kang be ẹsẹ le dukia lai lọ si ile ẹjọ pe gba aṣẹ, ti ile ẹjọ si le ma fun wọn ni aṣẹ ni gba miiran.
Musa Adamu Aliyu ni ọpọ lo wa ni akati ICPC ti wọn si n duro de idajọ ile ẹjọ ki wọn to gbe owo naa kalẹ fun ijọba apapọ.
"A ti gba owo toto Ogun bilọnu ti o n duro de idajọ ile ẹjọ ka to fa le ijọba lọwọ.
"Bakan naa ni ọpọ igbẹjọ n lọ lọwọ niwaju ile ẹjọ giga niluu Kaduna."
Ni Naijiria, gomina, minisita ati awọn oṣiṣẹ ijọba ni wọn ti ba ara wọn ninu ẹsun iwa ibajẹ, ti wọn si ṣe owo ilu mọkumọku.

Oríṣun àwòrán, X/EFCC
Fun apẹẹrẹ, lẹyin dukia ti wọn gba lọwọ Godwin Emefiele niluu Abuja, ọpọ awọn dukia mii ni awọn tun gbe ẹsẹ le nipinlẹ Eko.
Wọnyii ni awọn ti ijọba gba lọwọ Emefiele
- Ile alaja mọkanla - Ikoyi, Lagos
- AM Plaza, 11th Floor, Lekki Peninsula 1,ni Eko
- Imore Industrial Park, Ijọba ibilẹ Amuwo Odofin, nipinlẹ Eko
- Ilẹ warehouse Mitrewood ati Tatler Warehouse ni Ibeju-Lekki,
- Ile meji ni agbegbe Lakes Estate, Lekki,
Bakan naa ni 2024, ijọba Naijiria gbe ẹsẹ le dukia ọga agba nigba kan rin fun eto abo, Air Chief Marshal Alex Badeh, to w ani agbegbe Wuse 2 ati Maitama.
Wọnyi ni awọn dukia naa
- Ile ni No 14 Adzope Crescent, to kọju si Kumasi Crescent,
- No. 19 Kumasi Crescent, Wuse 2
- Ile ni No Umme Street, Wuse 2.
Bakan naa ni ijọba gba ọpọ ilẹ, ọkọ bọgini, ẹsọ ara lọwọ minisita tẹlẹ fun epo rọọbi labẹ iṣejọba Aarẹ Goodluck Jonathan, Diezani Alison-Madueke, ati awọn ile kan ni Banana Island, agbegbe kan to wọn ju niluu Eko.















