Fubara kan sáárá sí Tinubu lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú Rivers

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ti ijọba apapọ ni ko lọ rọkun ni ile fun igba diẹ nipinlẹ Rivers, Gomina Siminalayi Fubara, ti kan si awọn alatilẹyin rẹ, awọn eeyan ipinlẹ naa ati ọmọ Naijiria lapapọ pe ki wọn kan ṣara si Aarẹ Bola Tinubu lori bio ṣe tete da si rogbodiyan to bẹ silẹ, to si kede ilu o faraọ ni igbiyanju lati yanju yawọ to bẹ silẹ.
Fubara tun ni eto lati jẹ ki alaafia jọba laarin ijọba ati ile igbimọ aṣofin nipinlẹ ti n lọ lọwọ bayii.
Fubara wa fi da awọn araalu pe eto ijọba awarawa ati ijọba rere yoo pada si ipinlẹ naa laipẹ.
Eyi lo jade ninu atẹjade ti agbẹnusọ Gomina, Nelson Chukwudi fi lede fawọn akọroyin lẹyin ti Gomina sọrọ nibi ipade awọn agbagba kan lati ti fi ṣe ayajọ ọdun meji to di Gomina ipinlẹ naa.
"Mo n fi dayin loju pe ọrọ yoo tan yanju, ti ẹ o si pada si ofisi yin, ki ṣe ti awọn gomina nikan, pẹlu awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin bakan naa.
"Ati ajọṣepọ nla ti a ni tẹlẹ yoo pada, ti a o si jọ ma siṣẹ papọ pada fun ilọsiwaju ipinlẹ Rivers. Ohun to ṣe koko fun wa bayii ni lati ni ẹmi idarinjin."
Fubara rọ gbogbo awọn alatilẹyin rẹ ati gbogbo eeyan ipinlẹ Rivers pe ki wọn dupẹ lọwọ Aarẹ Bola Tinubu fun igbesẹ akin to gbe lati mu alaafia wa si ipinlẹ Rivers.
O rọ wọn pe ki wọn gba alaafia laaye, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati jẹ ki alaafia jọba .
O ni: "A ti bẹrẹ eto alaafia. Mo fẹ ki ẹ dupẹ lọwọ Aarẹ fun igbesẹ to gbe. Ti ki i ba ṣe ti Aarẹ ni, ohun ti a n wi lonii kọ a ni ma wi."
"N ko mọ bi aarẹ ṣe gbọ iroyin ṣugbọn otitọ ọrọ ni pe Aarẹ fi ọgbọn ori ṣe eyi ni asiko to yẹ. O yẹ ki a dupẹ lọwọ Aarẹ fun igbesẹ to gbe."
Ki lo sẹlẹ ṣaaju?
Ninu oṣu kẹta, Aarẹ Bola Tinubu kede ilu o fararọ niìpinlẹ Rivers latari laasigbo oṣelu to n waye níbẹ.
Nibi ọrọ ti aarẹ ba awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria sọ ni aṣelẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kejidinlogun, oṣu Kẹta lo ti sọrọ naa.
Tinubu ni laasigbo oṣelu to n waye ni ipinlẹ naa lati bii oṣu meloo kan sẹyin n kọ oun lominu.
O ní gbogbo igbìyanju oun lati ri pe ifanfa naa wa sopin lo ja si pabo.















