Pàtàkí ìrántí 'May 30' nínú ìtàn ogun abẹ́lé Naijiria

Aworan Chukwuemeka Odumegwu Ojukwu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oni ọgbọnjọ, oṣu karun un, ọdun 2025 lo pe ọdun mejidinlọgọta ti oloogbe Ọgagun Lt Col. Chukwuemeka Odumegwu Ojukwu kede pe orilẹ-ede Biafra awọn Ibo ti ya kuro lara Naijiria.

Ikede Ojukwu yii lo jẹ ki ogun abẹle bẹ silẹ lọdun 1967, ọdun mẹta gbako ṣi ni wọn fi ja ogun naa.

Akọsilẹ fi idi rẹ mulẹ pe eeyan to le lẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta ni ebi ati iṣẹ pa ku ninu ẹya Igbo ninu eyi ti awọn ọmọde ti pọju lọ.

Lati ọdun naa ni ọgbọnjọ, oṣu karun un ti di pataki ninu itan orilẹ-ede Naijiria papaa julọ fawọn ẹya Ibo.

Awọn ẹya Igbo naa ko kọkọ ka ọjọ yii kun tẹlẹ, amọ awọn to n pe ifun iyapa Ibo lara Naijiria ti jẹ ki wọn ka a kun bayii.

Ki ni iṣepataki ''May 30'' ninu itan ogun abẹle Biafra?

Ọgbọnjọ oṣu Karun un ọdọọdun jẹ ọjọ iranti awọn eeyan papaa awọn ẹya Ibo to ku ninu ogun abẹle Biafra to waye laarin ọdun 1967 si 1970 ni Naijiria.

Ọgbẹni Benjamin Obiajulu Aduba to mori bọ lasiko ogun Biafra ni gbogbo ọgbọnjọ oṣu Karun un ọdọọdun loun maa n ranti awọn ẹbi, akẹgbẹ oun nile ẹkọ, awọn ọrẹ ati gbogbo eeyan to padanu ẹmi ninu ogun Biafra.

Ọgbẹni Aduba ni oun ko gbagbe bawọn ẹgbọn baba ati iya oun ṣe ṣọfọ iku awọn ọdọ langba nigba kugba ti wọn ba ti kede rẹ lasiko ti ogun naa n lọ lọwọ.

''Mo ranti Chidu Aduba, Adaeze Aduba, Onyejelu Aduba, Onyeobialu Anyaragbu, Clifford Orji, Henry Onyebeke, ati Augustine Madu ti gbogbo wọn ba ogun Biafra lọ.

Mi o gbagbe David Nwaigbo to jẹ akẹgbẹ mi nile ẹkọ, bakan naa ni mo ranti ọpọlọpọ eeyan ti wọn ba ogun ọhun lọ,'' Aduba lo sọ bẹẹ.

Kii ṣe awọn ẹbi ati ọrẹ Aduba nikan lo ba ogun Biafra lọ, ko din ni miliọnu mẹta eeyan to ṣegbe sinu ogun Biafra.

Gbogbo eeyan lo yẹ ko maa ṣe iranti ogun abẹle Biafra

Ado oloro ṣeku pa ọpọ eeyan lọja, Henry Onyebeke, akẹkọọ ọmọ ọdun mẹrinla ṣagbako iku ni ọja Nkwo Inyi nibi to wa ounjẹ lọ fun ẹbi rẹ.

Ebi lo pa awọn eeyan mii ku, awọn mii ṣe aisan ti wọn si gba ibẹ lọ nigba ti wọn ko ri itọju; oriṣiiriṣii nnkan mii ṣeku pa ọpọ eeyan lasiko ogun Biafra.

Ọgbẹni Aduba ni idi niyii to fi yẹ kawọn eeyan ya ọjọ kan sọtọ lati maa ṣe iranti awọn to ku ninu ogun abẹle Biafra.

O ni kii ṣe awọn ẹya Ibo nikan lo ku ninu ogun Biafra, awọn ọmọ Naijiria mii naa ba ogun abẹle ọhun lọ.

Aduba ni gbogbo wọn lo yẹ kawọn eeyan maa ṣe iranti wọn.

Ọgbẹni Aduba sọ pe gbogbo eeyan lo yẹ ko maa ṣe iranti ogun abẹle Biafra tori ara itan orilẹede Naijiria ni ogun naa jẹ, ''bo tilẹ jẹ pe awọn oloṣelu maa wo ọjọ yii pe awọn ẹya Ibo nikan lo wa fun un.''

O ni o yẹ ki gbogbo ọmọ Naijiria ya ọgbọnjọ oṣu Karun un lọdọọdun sọtọ fun iranti awọn to ba ogun Biafra lọ.

Ta a ni Odumegwu Ojukwu kede pe orilẹ-ede Biafra lara Naijiria?

Aworan Chukwuemeka Odumegwu Ojukwu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Odumegwu Ojukwu gan an ni olori Biafra nitori oun lo kede iyapa Ibo lara Naijiria.

Ilu Nnewi ni Ojukwu ti wa nipinlẹ Anambra ṣugbọn ilu Zungeru nipinlẹ Niger ni wọn bi i si lọdun 1933.

Ọmọ onile ọlọna ni Ojukwu i ṣe, awọn obi rẹ ran an nile iwe debi pe o tun kawe ni fasiti niluu London.

Lẹyin naa lo kede orilẹ-ede Biafra pe ẹya Ibo ṣetan lati yapa kuro ni Naijiria eyi to jẹ ki ogun bẹ silẹ.

Ojukwu lọ ṣatipo lorilẹede Ivory Coast lọdun 1970 lẹyin ti ogun abẹle pari ki ijọba Naijiria to darijin in lọdun 1982.

Ijọba Naijiria gbe Ojukwu lọdun 1983 lẹyin iṣẹlẹ iditẹgbajọba kan, ṣugbọn wọn pada fi i silẹ lọdun 1984.

Ojukwu ko saaba dasi ọrọ oṣelu mọ lati igba naa titi to fi ku lọdun 2011.

Ijọba dawọn ẹṣọ eleto abo sita tori ẹgbẹ IPOB to kede konile-o-gbele ni ayajọ 'May 30'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa Anambra to ko awọn agbofinro sita kaakiri ipinlẹ naa lati daabo bo araalu lẹyin ti ẹgbẹ IPOB kede konile-o-gbele lati ṣe ayajọ ọgbọnjọ oṣu Karun un ọjọ Biafra lonii.

Ṣaaju ni ẹgbẹ IPOB kede konile-o-gbele fun gbogbo eeyan kaakiri ilẹ Ibo lonii lati ṣe iranti awọn to ba ogun abẹle Biafra lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra, SP Tochukwu Ikenga, sọ pe awọn ọlọpaa, awọn oṣiṣẹ ajọ DSS, awọn oṣiṣẹ abo ara ẹni ni abo ilu, awọn soja, awọn ẹṣọ oju popo atawọn ọmogun ori omi ti wa lojufo lati ṣiṣẹ papọ koju awọn to ba fẹ da wahala silẹ.

''Lẹyin ipade idakọnkọ lori ọrọ abo ti o waye nipinlẹ Anambra tori ikede konile-o-gbele ni ọgbọnjọ osu Karun un yii tawọn ọdaran kan kede, Kọmiṣọna ọlọpaa, IKioye Orutugu, ti sọ pe awọn ẹṣọ eleto abo ti ṣetan lati koju ẹnikẹni to ba da ilu ru.

Ifọwọsowọpọ laarin awọn ẹṣọ eleto abo yoo jẹ ki erongba ijọba lati jẹ ki alaafia jọba so eso rere.

Awọn ọlọpaa, awọn oṣiṣẹ ajọ DSS, awọn oṣiṣẹ abo ara ẹni ni abo ilu, awọn soja, atawọn

Ileeṣẹ ọlọpaa Anambra wa rọ awọn araalu lati pe ọlọpaa lori nọmba yii - 07039194332 tabi 08039334002 ti wọn ba kẹfin nnkan to mu ifura dani.