Wo kókó ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ngũgĩ wa Thiong'o, àgbà òǹkọ̀wé ilẹ̀ Africa tó jáde láyé

Oríṣun àwòrán, @Ngũgĩ wa Thiong'o
Ngũgĩ wa Thiong'o, agba onkọwe ilẹ Africa to ku lẹni ọdun mẹtadinlaadọrun-un( 87) ko ṣee gbagbe, pẹlu bo ṣe kọ lati jẹ ki ẹwọn, atipo ṣiṣe ati aisan di i lọwọ aṣeyọri.
O to ọgọta ọdun (60), ti Ngũgĩ wa Thiong'o fi kọwe lati mu ayipada ba orilẹede rẹ ti i ṣe Kenya. O gbiyanju lati yi imunisin pada si ijọba tiwa-n-tiwa.
Ọpọ igba ni wọn ti fa Ngũgĩ kalẹ lati gba ami ẹyẹ nla nidi iwe itan litireṣọ kikọ, ọpọ igba naa lo si maa n ya awọn ololufẹ rẹ lẹnu pe wọn ko fun un.
Bo tilẹ jẹ pe agba onkọwe naa ko ri ami ẹyẹ pataki naa gba, manigbagbe ni Ngũgĩ lagbo iwe itan litireṣọ nilẹ Africa pẹlu awọn iwe to ti kọ.
Ngũgĩ, ẹni ti wọn sọ ni James Thiong'o Ngũgĩ, ni 1938 ti wọn bi i lorilẹede Kenya,ba ara rẹ labẹ ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi.
O dagba niluu kan ti a mọ si Limuru, ninu mọlẹbi nla kan to yan iṣẹ agbẹ laayo, ti wọn ko si lowo gidi lọwọ.
Ninu inira ni awọn obi rẹ ti dawo ti wọn fi sanwo ileewe rẹ ni Alliance, ileewe Gẹẹsi to kọkọ lọ.
Ileewe naa lo ti de lọjọ kan to si ri i pe awọn ijọba amunisin ti kina bọ gbogbo abule awọn obi rẹ. Wọn ti jo o.
Awọn mọlẹbi Ngũgĩ' wa lara awọn ti wọn fipa mu lati maa gbe ni agọ ti wọn ko awọn eeyan si, lasiko laasigbo kan ti wọn n pe Mau Mau, eyi ti awọn ajijagbara fi n ja fun ominira.
Ninu rogbodiyan to waye laaarin 1952 si 1960 naa ni wọn ti yinbọn fun aburo Ngũgĩ's, Gitogo, nigba to kọ lati tẹle aṣẹ ṣọja Gẹẹsi kan.
Bẹẹ, ki i ṣe pe Gitogo ko fẹẹ da ṣọja naa lohun, eti lo n yọ ọ lẹnu. Aditi ni.
Bí ìwé Ngũgĩ tó gbajúmọ̀ nnì, 'Weep Not, Child, ṣe wáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni1959, Ngũgĩ kuro ni Kenya lati kawe ni Yunifasiti Makerere, ni Uganda.
Lasiko ti awọn onkọwe n ṣe ipade, Ngũgĩ fi iwe to kọ itan rẹ akọkọ si, han agba onkọwe, Chibuna Achebe, lati Naijiria.
Achebe fiwe ọhun ranṣẹ si ontẹwe rẹ ni UK, bẹẹ si ni wọn ṣe gbe iwe naa ti i ṣe 'Weep Not, Child', jade fun itẹwọgba nla ni 1964.
Iwen naa ni akọkọ iru ẹ ti wọn kọ lede oyinbo ni apa Ila-Oorun Africa.
Kia ni Ngũgĩ tun sare gbe iwe meji mi-in jade lẹyẹ o sọka, awọn naa ni 'A Grain of Wheat ati The River Between'.
Ni 1972, iwe iroyin ilẹ UK, kọ nipa Ngũgĩ, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn nigba naa, gẹgẹ bii "ọkan lara awọn agba onkọwe ilẹ Africa."
Ni 1977, igbeaye Ngũgĩ yipada pẹlu iṣẹ rẹ to yan laayo. Ọdun naa lo yọ orukọ isami rẹ to jẹ ti oyinbo, iyẹn James, kuro, o si n jẹ Ngũgĩ wa Thiong'o nikan.
Bakan naa lo yọ ede oyinbo kuro ninu iwe kikọ rẹ, o si pinnu lati maa fi ede abinibi rẹ nikan kọwe, iyẹn, ede Kikuyu.
Ọdun 1977 lo pari iwe to kọ lede oyinbo si, nigba ti iwe rẹ to pe ni 'Petals of Blood', jade.
Ngũgĩ ṣẹ̀wọ̀n, wọ́n tún fipá bá ìyàwó rẹ̀ lò pọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn iwe ti Oloogbe Ngũgĩ kọkọ kọ da le imunisin awọn oyinbo ilẹ Gẹẹsi, ṣugbọn awọn ijọba ilu rẹ ni Kenya lo fi Petals of Blood ba ja.
Onkọwe naa fiwe ṣalaye pe awọn olori ti sọ ara wọn di aladaajẹ, wọn si ti sọ araalu di yẹpẹrẹ lasan.
Lọdun yẹn kan naa lo tun kọwe kan pẹlu awọn ọkowe mi-in, iwe naa ni wọn pe ni 'Ngaahika Ndeenda' (O tumọ si pe ma a gbeyawo nigba ti mo ba fẹ).
Iwe naa n sọ nipa idaamu awọn ọmọ Kenya ni.
Ijọba Jomo Kenyatta ti ibi ti wọn ti ṣafihan iwe naa pa, wọn si gbe Ngũgĩ ju sẹwọn fun ọdun kan lai gbe e lọ si kootu fun igbẹjọ.
Wọn fi i silẹ lẹyin ti Daniel arap Moi, gbajọba, ti Kenyatta fipo aarẹ Kenya silẹ.
Ngũgĩ funra rẹ sọ pe lẹyin ọdun mẹrin, nigba toun wa ni London, olobo ta oun pe wọn fẹẹ pa oun boun ba pada si Kenya.
Eyi lo fi duro ni UK, to tun pada lọ si America lati ṣatipo. Ko si pada si Kenya afi lẹyin ọdun mejilelogun (22 years).
Wọn ki I kaabọ kari Kenya, ṣugbọn ko pẹ ti ajọyọ fi di ibanujẹ.
Awọn janduku yabo ile Ngũgĩ, wọn lu u, wọn ṣe e leṣẹ, wọn si fipa ba iyawo rẹ lo pọ.
Ngũgĩ loun mọ pe ikọlu naa lọwọ oṣelu ninu.
O pada si US, nibi to ti gboye Ọjọgbọn ni awọn yuifasiti bii Yale, New York ati California Irvine.
Ngũgĩ ṣegbeyawo lẹẹmeji, ṣugbọn mejeeji lo kuna.
O bimọ mẹsan-an, ti mẹrin ninu wọn naa jẹ onkọwe.
Àìsàn dé

Oríṣun àwòrán, Others
Nigba to ya, ilera Ngũgĩ bẹrẹ si i mẹhẹ.
Ni 1995, awọn dokita sọ pe jẹjẹrẹ ẹpọn (prostate cancer) ti kọ lu u, wọn si sọ fun un pe oṣu mẹta lo ni lati gbele aye.
Ṣugbọn Ngũgĩ ko ku nigba naa.
Ni 2019, ẹẹmẹta lo ṣe iṣẹ abẹ ọkan, kindinrin rẹ naa si bẹrẹ si i yọwọ.
Ojiji ni oorun Ngũgĩ wọ bi oṣu Karun-un yii ṣe n pari lọ, ni 2015.
'Imọlẹ ọkan lara awọn imọlẹ akọtan litireṣọ nilẹ Africa si ṣe bẹẹ wọ ookun', bi Chimamanda Ngozi Adichie toun naa jẹ agba onkọwe ilẹ Africa,ṣe sọ.














