Àádọ́ta ọdún ECOWAS-Kí ló dé tí wọ́n ń bu ẹnu àtẹ́ lù ú ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Busayo James-Olufade
- Role, Senior Journalist
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Bi ajọ Economic Community of West African States (ECOWAS) to n ri si ọrọ oṣelu, alaafia ati ọrọ aje awọn orilẹede Iwọ-Oorun Afica ṣe pe aadọta ọdun bayii, ọpọ idojukọ ni wọn ti ri, wón si ti ṣe awọn aṣeyọri pẹlu, gẹgẹ bi ọmọkunrin to ji mu iṣẹ aje ṣe ni.
"Nigba mi-in, awọn ohun ti a ti gbe ṣe ki i jọ wa loju." Yusuf Tuggar, Minisita Naijiria fun ọrọ ilẹ okeere lo sọ bẹẹ.
Ipinnu awọn olori Iwọ-Oorun Africa lati mu awọn ẹkun kọọkan wa papọ lo bi ECOWAS. Wọn bẹrẹ si i ṣe pọ lati ni iṣọkan ati ki ọrọ aje awọn ẹkun naa le maa gberu si i.
Lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un ọdun 1975, ajọ ECOWAS wa si imuṣẹ, nigba ti awọn olori orilẹede kaakiri Iwọ-Oorun Africa tọwọ bọwe adehun ilu Eko.
Afojusun naa mu iwuri wa, lati mu ọrọ aje ṣe daadaa kaakiri ẹkun, kawọn ọmọ ẹgbẹ le rin wọbi to wu wọn, ki alaafia ati aabo si wa pẹlu
Fun awọn eeyan ti itan iṣẹdalẹ wọn papọ, ṣugbọn ti wọn ti fọnka nitori owo ẹru ti wọn koju, pẹlu awọn ti ilu wọn ko ri idagbasoke, gbogbo wọn ni wọn fun lanfaani lati waa sọ ero ọkan wọn.
Ṣugbọn bi ECOWAS ṣe n mura lati ṣe ajọyọ aadọta ọdun idasilẹ rẹ yii, awọn awuyewuye labala oṣelu kan n waye, o si n foju han pe ọjọ iwaju ajọ yii n mi lẹsẹ.
Wíwá àlááfìà àti ìdàgbàsókè orílẹ̀èdè

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba ti akọsilẹ nipa ECOWAS ṣẹṣẹ bẹrẹ, wọn maa n gba oriyin gan-an lori alaafia ati aabo ilu ti wọn gbe dani.
Wọn tun da abala ologun silẹ ti i ṣe ECOMOG, wọn si ri si ogun abẹle to n waye ni Liberia ati Sierra Leone nigba yẹn, wọn da alaafia pada sibẹ.
Bakan naa ni wọn wa ojutuu si rogbodiyan to ṣẹlẹ ni Côte d'Ivoire, Guinea-Bissau ati Gambia.
Ninu ọrọ rẹ fun BBC, Aarẹ ECOWAS, Alieu Omar Touray, sọ pe ohun ti awọn to da ECOWAS silẹ n fẹ ni iṣọkan ilẹ Africa.
O ni pẹlu iwe idanimọ ECOWAS, eeyan le gbera l'Ekoo ko si balẹ si Dakar lai ni iwe irinna ti a mọ si Visa.
Bakan naa lo ni aṣeyọri ECOWAS ko wọpọ.
"Bẹẹ naa la ṣe n ri aṣeyọri ati idagbasoke , awọn nnkan bii ẹka to n ri si epo rọbi ti a n gbero (African Atlantic Gas Pipeline), eyi ti yoo gba Naijiria kọja si Morocco, pẹlu erongba lati maa ta afẹfẹ idana si Europe."
Aarẹ ECOWAS lo ṣalaye bẹẹ.
Ogun ọdun sẹyin ni aba ti wa nilẹ,ṣugbọn ko ti i wa si imuṣẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn olori ẹkun kọọkan n sọ pe o ṣee ṣe.
Loṣu Kẹrin ọdun yii, awọn olori banki apapọ nilẹ Africa pẹlu awọn minisita eto iṣuna pade niluu Abuja lati lati fẹnu ko sori owo kan naa giving a new launch date of 2027.
Awọn olori naa gbagbọ pe afojusun awọn naa le wa si imuṣẹ, o kan jẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ kan lati awọn orilẹede ECOWAS ko ti i fẹnuko sibi kan ni.
Ìyapa Sahel

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Pẹli awọn aṣeyọri gbogbo ti wọn n tọka yii, ọjọ iwaju ECOWAS ko ye ẹnikan.
Ajọ ti aye n pọnle fun iṣọkan tẹlẹ naa ti n koju iyapa bayii, ọrọ oṣelu ti n da wahala silẹ, ko si ye awọn eeyan rẹ mọ.
Ni ẹkun-un aṣalẹ Sahel, lati nnkan bii ọdun mẹrin sẹyin ni awọn ologun kekere ti n ditẹ gbajọba, ti ayipada si n de ba iṣejọba ibẹ.
Lati 2020, ijọba Mali, Guinea, Burkina Faso ati Niger ti kuro lọwọ oloṣelu, ṣọja ti gbajọba.
Eyi to lagbara ju ni ti Aarẹ Niger tẹlẹ, Mohamed Bazoum, ti wọn yọ nipo loṣu keje ọdun 2023, ti wọn tun ju sẹwọn.
Ninu igbiyanju wọn lati yi nnkan pada, awọn olori ECOWAS fi gbedeke lelẹ. Wọn gbe ote le ọrọ aje awọn orilẹede naa, ṣugbọn ko si eyi ti so eso rere nibẹ
Eyi lo si fa a ti awọn orilẹede naa Niger, Burkina Faso ati Mali fi ni awọn ko ba ECOWAS ṣe mọ.
Bi wọn ṣe ya kuro lara ECOWAS si ti je kawọn awoye oṣelu maa sọ pe aja to n gbo ti ko le buni jẹ ni ECOWAS.
Aarẹ ECOWAS, Alieu Omar Touray, sọ pe ẹbi oun kọ ni bi awọn Sahel ṣe yapa kuro lara ECOWAS.
O ni wọn ki i fipa mu eeyan ṣe ECOWAS, bi ẹnikẹni ba si fẹ kuro, ipinnu wọn ni.
Ìjákulẹ̀
Ki i ṣe iyapa awọn ọmọ ẹgbẹ nikan lo n fa wahala fun ECOWAS, awọn eeyan kaakiri Africa ni wọn ti n kọminu lori ajọ naa ati bi wọn ṣe nipa si.
Awọn kan ni awọn fẹran ajọ yii, ṣugbọn wọn ko tẹle ohun ti wọn sọ nipa ki eeyan le lọ lati ilu kan sibomi-in.
"Ọpọ eeyan ni ko le kọja si orilẹede mi-in, ti wọn si jẹ ọmọ ẹgbẹ ECOWAS niluu wọn. Eyi n ri bẹẹ nitori ofin ti ECOWAS ṣe ko fẹsẹ mulẹ." Nana Adjei ni Ghana lo sọ bẹẹ
Pẹlu bo ṣe jẹ pe orilẹede mejila lo ku ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ ECOWAS bayii, awọn eeyan ti n beere pe ṣe ajọ naa yoo si yè bayii.
Ṣugbọn Aarẹ ECOWAS ni ko si ewu loko. O ni awọn orilẹede Africa nifẹẹ lati wa papọ.
"Awọn iṣoro kan le wa bayii ti a n koju, ṣugbon wọn ko kọja atunṣe. Nipasẹ ajọsọ ati ajọṣe, o yẹ ka le yanju awọn kan ninu iṣoro yii, ka si ri i pe iṣọkan wa pada."
Bẹẹ ni Aarẹ ECOWAS, wi.














