Ìgbéyàwó wú mi, kódà, mo tọrọ ọkọ ní Mecca, àmọ́ dandan kọ́ ni ọkọ níní, tó bá wá ni - Bukky Wright
Gbajugbaja oṣerebinrin ilẹ wa, Alaaja Sekinat Ajoke Bukky Wright, ba BBC Yoruba sọ ọpọ ọrọ nipa aye rẹ, paapaa bi awọn ololufẹ rẹ ko ṣe ri i ninu fiimu mọ fun ọdun pipẹ.
Bukky Wright ṣalaye nipa igbeyawo, awọn ọmọ rẹ ati bo ṣe dero ilu oyinbo.
Nigba to n dahun ibeere nipa pe ṣe yoo ṣi pada lọkọ, oṣere Yoruba, to tun maa n ṣere oloyinbo naa sọ pe, o wu oun lati ṣegbeyawo, ṣugbọn ti Ọlọun ba kọ ọ ni, ki i ṣe dandan .
Bakan naa lo ni tori ọmọ loun ṣe di ero ilu oyinbo, ati pe awọn ọmọ naa si ti dagba bayii.
O ni awọn ọmọ lo ni koun gbe igbesi aye oun lọna ti oun n tọ tẹlẹ, nitori eyi to lo aye rẹ fun awọn gẹgẹ bi iya ti to.
Eyi lo mu oun sọ fun wọn pe oun yoo pada sidi ere ori itage ni, wọn si gba.
"Ìgbésí ayè ilú òyìnbó yàtọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ iléèwé padà ni"
Ninu alaye Wright tawọn eeyan tun mọ si Omotara Johnson lo ti ni igbesi aye ilu oyinbo yatọ gedegbe, oṣere naa ṣalaye pe niṣe loun pada sileewe lakọtun.
O ni oun lọọ bẹrẹ ẹkọ nipa imọ ayelujara (I.T).
O fi kun un pe ẹkọ toun kọ nipa rẹ pọ, ṣugbọn eyi to jẹ mọ aabo ati ipenija ori ayelujara loun yan laayo. (I.T Audit and Cyber Security).
Bukky Wright ṣalaye pe ilu oyinbo gba ki eeyan gbadura ko le ri aanu gba, ko si ṣetan lati pada sileewe.
''Emi naa nigba yẹn, mo maa n sọ ọ pe nnkan ẹyọkan ṣoṣo ti ori mi le ka ko ju owo lọ. Ko le ka do-re-mi. Amọ nigba ti mo de ilu oyinbo, mo sọ funra mi pe mi o le ṣiṣẹ ẹgbin, mo fẹẹ kawe ni.
''Nnkan ti eeyan nilo niyẹn, ki eeyan ja ara rẹ gba, k'Ọlọun wa fi aanu si i, o maa ṣe aṣeyọri.
"Ẹni tó máa fẹ ọkọ mẹ́wàá kò ní í dúró lórii mẹ́sàn-ààbọ̀"

''Lori ọrọ igbeyawo, ẹni ti Ọlọun ba ni o n lọ si ori mẹfa, mo de marun-un aabọ ko ni i duro.
"T'Ọlọun ba ni o n lọ si ori mẹwaa, bo de ori mẹsan-an aabọ ko ni i duro.
Nnkan to wu mi ni, ṣugbọn t'Ọlọun ba kọ ọ ni. Mi o ni kawọn obinrin ma gbiyanju o, nitori emi, o wu mi.
"Nibi to wu mi de, mo de Kaabah, mo sọ fun Ọlọun, mo dẹ mọ pe Ọba to n gba adua ni''
Bukky lo ni oun naa le ni lọwọ loootọ, nitori ẹlẹran ara loun naa.
O ni ṣugbọn bi ọkunrin ba ṣe ohun ti ko tẹ oun lọrun, oun ko ni i duro sibẹ o.
Nipa awọn oṣere to n ṣira silẹ, oṣere tiata naa sọ pe ki i ṣe onitiata nikan lo n ṣi ara silẹ, o ni ọpọ obinrin ni Naijiria bayii lo n ṣi ara silẹ.
O fi kun un pe oun maa n beere lọwọ awọn ọkunrin, pe ṣe nitori wọn ni awọn obinrin ṣe n ṣi gbogbo ọmu silẹ bi eyi, wọn si maa n sọ foun pe awọn gan-an fẹ ki wọn faṣọ bo o, ko le baa niyi.
Lakootan, Bukky Wright ṣalaye nipa iyatọ to ti ba iṣẹ tiata, bẹrẹ lati ibi ẹrọ ti wọn n lo.
O ni kawọn ololufẹ oun maa reti iṣẹ tuntun to n bọ laipẹ.














